Gẹn 11:1-8
Gẹn 11:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBOGBO aiye si jẹ ède kan, ati ọ̀rọ kan. O si ṣe, bi nwọn ti nrìn lati ìha ìla-õrùn lọ, ti nwọn ri pẹtẹlẹ kan ni ilẹ Ṣinari; nwọn si tẹdo sibẹ̀. Nwọn si wi, ikini si ekeji pe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a mọ briki, ki a si sun wọn jina. Briki ni nwọn ni li okuta, ọ̀da-ilẹ ni nwọn si nfi ṣe ọ̀rọ. Nwọn si wipe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a tẹ̀ ilu kan dó, ki a si mọ ile-iṣọ kan, ori eyiti yio si kàn ọrun; ki a si li orukọ, ki a má ba tuka kiri sori ilẹ gbogbo. OLUWA si sọkalẹ wá iwò ilu ati ile-iṣọ́ na, ti awọn ọmọ enia nkọ́. OLUWA si wipe, Kiye si i, ọkan li awọn enia, ède kan ni gbogbo wọn ni; eyi ni nwọn bẹ̀rẹ si iṣe: njẹ nisisiyi kò sí ohun ti a o le igbà lọwọ wọn ti nwọn ti rò lati ṣe. Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a sọkalẹ lọ, ki a dà wọn li ède rú nibẹ̀, ki nwọn ki o máṣe gbedè ara wọn mọ́. Bẹ̃li OLUWA tú wọn ká lati ibẹ̀ lọ si ori ilẹ gbogbo: nwọn si ṣíwọ ilu ti nwọn ntẹdó.
Gẹn 11:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà kan èdè kan ṣoṣo ni ó wà láyé, ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan ni gbogbo wọ́n sì ń lò. Bí àwọn eniyan ṣe ń ṣí káàkiri ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní agbègbè Babiloni, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ. Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á ṣe bíríkì, kí á sì sun wọ́n jiná dáradára.” Bíríkì ni wọ́n lò dípò òkúta, wọ́n sì lo ọ̀dà ilẹ̀ dípò ọ̀rọ̀. Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọ́ ìlú ńlá kan, kí á sì kọ́ ilé ìṣọ́ gíga kan tí orí rẹ̀ yóo kan ojú ọ̀run gbọ̀ngbọ̀n, kí á baà lè di olókìkí, kí á má baà fọ́n káàkiri orí ilẹ̀ ayé.” OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú tí àwọn ọmọ eniyan ń tẹ̀dó ati ilé ìṣọ́ gíga tí wọn ń kọ́. OLUWA wí pé, “Ọ̀kan ni gbogbo àwọn eniyan wọnyi, èdè kan ṣoṣo ni wọ́n sì ń sọ, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí wọn yóo ṣe ni, kò sì ní sí ohun kan tí wọn bá dáwọ́lé láti ṣe tí yóo dẹtì fún wọn. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á sọ̀kalẹ̀ lọ bá wọn, kí á dà wọ́n ní èdè rú, kí wọn má baà gbọ́ èdè ara wọn mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fọ́n wọn káàkiri sí gbogbo orílẹ̀ ayé, wọ́n pa ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó tì.
Gẹn 11:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo. Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari (Babeli), wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà-ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi). Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ (òkìkí) kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ṣùgbọ́n, OLúWA sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́. OLúWA wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbèrò tí wọn kò ní le ṣe yọrí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má ba à yé ara wọn mọ́.” Ọlọ́run sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó.