Gẹn 1:24-25
Gẹn 1:24-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o mu ẹdá alãye ni irú rẹ̀ jade wá, ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹranko ilẹ ni irú rẹ̀: o si ri bẹ̃. Ọlọrun si dá ẹranko ilẹ ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.
Gẹn 1:24-25 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.
Gẹn 1:24-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.