Gẹn 1:14-15
Gẹn 1:14-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun si wipe, Ki awọn imọlẹ ki o wà li ofurufu ọrun, lati pàla ọsán on oru; ki nwọn ki o si ma wà fun àmi, ati fun akoko, ati fun ọjọ́, ati fun ọdún: Ki nwọn ki o si jẹ́ imọlẹ li ofurufu ọrun, lati mọlẹ sori ilẹ: o si ri bẹ̃.
Pín
Kà Gẹn 1Gẹn 1:14-15 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn, kí wọ́n sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti máa tàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Pín
Kà Gẹn 1Gẹn 1:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún ààmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún, Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Pín
Kà Gẹn 1