Gẹn 1:10-13
Gẹn 1:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun si pè iyangbẹ ilẹ ni Ilẹ; o si pè iwọjọpọ̀ omi ni Okun: Ọlọrun si ri pe o dara. Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃. Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹta.
Gẹn 1:10-13 Yoruba Bible (YCE)
Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹta.
Gẹn 1:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta.