Gal 6:7-18

Gal 6:7-18 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ má tan ara yín jẹ: eniyan kò lè mú Ọlọrun lọ́bọ. Ohunkohun tí eniyan bá gbìn ni yóo ká. Nítorí àwọn tí ó bá ń gbin nǹkan ti Ẹ̀mí yóo ká àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí, tíí ṣe ìyè ainipẹkun. Kí á má ṣe jẹ́ kí ó sú wa láti ṣe rere, nítorí nígbà tí ó bá yá, a óo kórè rẹ̀, bí a kò bá jẹ́ kí ó rẹ̀ wá. Nítorí náà, bí a bá ti ń rí ààyè kí á máa ṣe oore fún gbogbo eniyan, pàápàá fún àwọn ìdílé onigbagbọ. Ọwọ́ ara mi ni mo fi kọ ìwé yìí si yín, ẹ wò ó bí ó ti rí gàdàgbà-gadagba! Gbogbo àwọn tí wọn ń fẹ́ kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn mọ̀ wọ́n ní ẹni rere ni wọ́n fẹ́ fi ipá mu yín kọlà, kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn má baà ṣe inúnibíni sí wọn nítorí agbelebu Kristi. Nítorí àwọn tí wọ́n kọlà pàápàá kì í pa gbogbo òfin mọ́. Ṣugbọn wọ́n fẹ́ kí ẹ kọlà kí wọ́n máa fi yín fọ́nnu pé àwọn mu yín kọlà. Ṣugbọn ní tèmi, kí á má rí i pé mò ń fọ́nnu kiri àfi nítorí agbelebu Oluwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ayé yìí ti di ohun tí a kàn mọ́ agbelebu lójú mi, tí èmi náà sì di ẹni tí a kàn mọ́ agbelebu lójú rẹ̀. Nítorí ati a kọlà ni, ati a kò kọlà ni, kò sí èyí tí ó já mọ́ nǹkankan. Ohun tí ó ṣe pataki ni ẹ̀dá titun. Kí alaafia ati àánú Ọlọrun kí ó wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá ń gbé ìgbé-ayé wọn nípa ìlànà yìí, ati pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun. Láti ìgbà yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́, nítorí ojú pàṣán wà ní ara mi tí ó fihàn pé ti Jesu ni mí. Ará, kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Oluwa wa kí ó wà pẹlu yín. Amin.

Gal 6:7-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká. Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀. Ǹjẹ́ bí a ti ń rí àǹfààní gba, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tí í ṣe ará ilé ìgbàgbọ́. Ẹ wo bí mo ti fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé gàdàgbà-gàdàgbà sí yín. Iye àwọn tí ń fẹ́ ṣe àṣehàn ni ara wọn ń rọ yín láti kọlà; kìkì nítorí pé kí a má ba à ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kristi. Nítorí àwọn tí a kọ ní ilà pàápàá kò pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ mú yin kọlà, kí wọn lè máa ṣògo nínú ara yín. Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jesu Kristi Olúwa wa, nípasẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé. Nítorí pé nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun. Kí àlàáfíà àti àánú wà lórí gbogbo àwọn tí ń rìn ní ìlànà yìí, àti lórí Israẹli Ọlọ́run. Láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́; nítorí èmi ń ru àpá Jesu Olúwa kiri ní ara mi. Ará, oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.

Gal 6:7-18

Gal 6:7-18 YBCVGal 6:7-18 YBCVGal 6:7-18 YBCVGal 6:7-18 YBCV