Gal 5:7-10
Gal 5:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha dí nyin lọwọ ki ẹnyin ki o máṣe gba otitọ? Iyipada yi kò ti ọdọ ẹniti o pè nyin wá. Iwukara kiun ni imu gbogbo iyẹfun wu. Mo ni igbẹkẹle si nyin ninu Oluwa pe, ẹnyin kì yio ni ero ohun miran; ṣugbọn ẹniti nyọ nyin lẹnu yio rù idajọ tirẹ̀, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ.

Gal 5:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ ti ń sáré ìje dáradára bọ̀. Ta ni kò jẹ́ kí ẹ gba òtítọ́ mọ́? Ìyípadà ọkàn yín kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó pè yín. Ìwúkàrà díẹ̀ níí mú kí gbogbo ìyẹ̀fun wú sókè. Mo ní ìdánilójú ninu Oluwa pé ẹ kò ní ní ọkàn mìíràn. Ṣugbọn ẹni tí ó ń yọ yín lẹ́nu yóo gba ìdájọ́ Ọlọrun, ẹni yòówù kí ó jẹ́.
Gal 5:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́? Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá. Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú. Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́.