Gal 5:2-6
Gal 5:2-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiyesi i, emi Paulu li o wi fun nyin pe, bi a ba kọ nyin nila, Kristi ki yio li ère fun nyin li ohunkohun. Mo si tún sọ fun olukuluku enia ti a kọ ni ila pe, o di ajigbese lati pa gbogbo ofin mọ́. A ti yà nyin kuro lọdọ Kristi, ẹnyin ti nfẹ ki a da nyin lare nipa ofin; ẹ ti ṣubu kuro ninu ore-ọfẹ. Nitori nipa Ẹmí awa nfi igbagbọ duro de ireti ododo. Nitori ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ́ ti nṣiṣẹ nipa ifẹ.
Gal 5:2-6 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu ni mo wí fun yín pé bí ẹ bá kọlà, Kristi kò ṣe yín ní anfaani kankan. Mo tún wí pé gbogbo ẹni tí a bá kọ nílà di ajigbèsè; ó níláti pa gbogbo òfin mọ́. Ẹ ti ya ara yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fẹ́ ìdáláre nípa òfin. Ẹ ti yapa kúrò ní ọ̀nà oore-ọ̀fẹ́. Ṣugbọn ní tiwa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni à ń retí ìdáláre nípa igbagbọ. Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.
Gal 5:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kíyèsi i, èmi Paulu ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà abẹ́, Kristi kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun. Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbèsè láti pa gbogbo òfin mọ́. A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́. Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo. Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.