Gal 5:16-26

Gal 5:16-26 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé kí ẹ jẹ́ kí Ẹ̀mí máa darí ìgbé-ayé yín, tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ṣẹ. Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí; bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí Ẹ̀mí ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti ara. Ẹ̀mí ati ara lòdì sí ara wọn. Àyọrísí rẹ̀ ni pé ẹ kì í lè ṣe àwọn ohun tí ó wù yín láti ṣe. Bí Ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin. Àwọn iṣẹ́ ara farahàn gbangba. Àwọn ni àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà; ìbọ̀rìṣà, oṣó, odì-yíyàn, ìjà, owú-jíjẹ, ìrúnú, ọ̀kánjúwà, ìyapa, rìkíṣí; inú burúkú, ìmutípara, àríyá àwọn ọ̀mùtí ati irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, ni mo tún ń sọ fun yín, pé àwọn tí ó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní jogún ìjọba Ọlọrun. Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́, ìwà pẹ̀lẹ́, ìsẹ́ra-ẹni. Kò sí òfin kan tí ó lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí. Àwọn tíí ṣe ti Kristi Jesu ti kan àwọn nǹkan ti ara mọ́ agbelebu pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ati ìgbádùn ara. Bí a bá wà láàyè nípa Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí á máa gbé ìgbé-ayé ti Ẹ̀mí. Ẹ má jẹ́ kí á máa ṣe ògo asán, kí á má máa rú ìjà sókè láàrin ara wa, kí á má sì máa jowú ara wa.

Gal 5:16-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin. Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtaraẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí àwa bá wà láààyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa ṣe ògo asán, kí a má mú ọmọnìkejì wa bínú, kí a má ṣe ìlara ọmọnìkejì wa.

Gal 5:16-26

Gal 5:16-26 YBCVGal 5:16-26 YBCV