Gal 5:1-15

Gal 5:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITORINA ẹ duro ṣinṣin ninu omnira na eyi ti Kristi fi sọ wa di omnira, ki ẹ má si ṣe tún fi ọrùn bọ àjaga ẹrú mọ́. Kiyesi i, emi Paulu li o wi fun nyin pe, bi a ba kọ nyin nila, Kristi ki yio li ère fun nyin li ohunkohun. Mo si tún sọ fun olukuluku enia ti a kọ ni ila pe, o di ajigbese lati pa gbogbo ofin mọ́. A ti yà nyin kuro lọdọ Kristi, ẹnyin ti nfẹ ki a da nyin lare nipa ofin; ẹ ti ṣubu kuro ninu ore-ọfẹ. Nitori nipa Ẹmí awa nfi igbagbọ duro de ireti ododo. Nitori ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ́ ti nṣiṣẹ nipa ifẹ. Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha dí nyin lọwọ ki ẹnyin ki o máṣe gba otitọ? Iyipada yi kò ti ọdọ ẹniti o pè nyin wá. Iwukara kiun ni imu gbogbo iyẹfun wu. Mo ni igbẹkẹle si nyin ninu Oluwa pe, ẹnyin kì yio ni ero ohun miran; ṣugbọn ẹniti nyọ nyin lẹnu yio rù idajọ tirẹ̀, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ. Ṣugbọn, ara, bi emi ba nwasu ikọla sibẹ, ehatiṣe ti a nṣe inunibini si mi sibẹ? njẹ ikọsẹ agbelebu ti kuro. Emi iba fẹ ki awọn ti nyọ nyin lẹnu tilẹ ké ara wọn kuro. Nitori a ti pè nyin si omnira, ará; kiki pe ki ẹ máṣe lò omnira nyin fun àye sipa ti ara, ṣugbọn ẹ mã fi ifẹ sìn ọmọnikeji nyin. Nitoripe a kó gbogbo ofin já ninu ọ̀rọ kan, ani ninu eyi pe; Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. Ṣugbọn bi ẹnyin ba mbù ara nyin ṣán, ti ẹ si njẹ ara nyin run, ẹ kiyesara ki ẹ máṣe pa ara nyin run.

Gal 5:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Irú òmìnira yìí ni a ní. Kristi ti sọ wá di òmìnira. Ẹ dúró ninu rẹ̀, kí ẹ má sì tún gbé àjàgà ẹrú kọ́rùn mọ́. Èmi Paulu ni mo wí fun yín pé bí ẹ bá kọlà, Kristi kò ṣe yín ní anfaani kankan. Mo tún wí pé gbogbo ẹni tí a bá kọ nílà di ajigbèsè; ó níláti pa gbogbo òfin mọ́. Ẹ ti ya ara yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fẹ́ ìdáláre nípa òfin. Ẹ ti yapa kúrò ní ọ̀nà oore-ọ̀fẹ́. Ṣugbọn ní tiwa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni à ń retí ìdáláre nípa igbagbọ. Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́. Ẹ ti ń sáré ìje dáradára bọ̀. Ta ni kò jẹ́ kí ẹ gba òtítọ́ mọ́? Ìyípadà ọkàn yín kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó pè yín. Ìwúkàrà díẹ̀ níí mú kí gbogbo ìyẹ̀fun wú sókè. Mo ní ìdánilójú ninu Oluwa pé ẹ kò ní ní ọkàn mìíràn. Ṣugbọn ẹni tí ó ń yọ yín lẹ́nu yóo gba ìdájọ́ Ọlọrun, ẹni yòówù kí ó jẹ́. Ará, tí ó bá jẹ́ pé iwaasu pé kí eniyan kọlà ni mò ń wà, kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ǹjẹ́ a ti mú ohun ìkọsẹ̀ agbelebu Kristi kúrò? Ìbá wù mí kí àwọn tí ó ń yọ yín lẹ́nu kúkú gé ara wọn sọnù patapata! Òmìnira ni a pè yín sí, ẹ̀yin ará, ṣugbọn kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín fún ìtẹ́lọ́rùn ara yín, ìfẹ́ ni kí ẹ máa fi ran ara yín lọ́wọ́. Nítorí gbolohun kan kó gbogbo òfin já, èyí ni pé “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.” Ṣugbọn bí ẹ bá ń bá ara yín jà, tí ẹ̀ ń bu ara yín ṣán, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa ara yín run.

Gal 5:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kristi fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́. Kíyèsi i, èmi Paulu ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà abẹ́, Kristi kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun. Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbèsè láti pa gbogbo òfin mọ́. A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́. Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo. Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́. Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́? Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá. Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú. Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. Ṣùgbọ́n, ará, bí èmi bá ń wàásù ìkọlà síbẹ̀, kín ni ìdí tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀? Ǹjẹ́ ìkọ̀sẹ̀ àgbélébùú ti kúrò. Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà ara wọn kan kúrò. Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejì yín. Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run.

Gal 5:1-15

Gal 5:1-15 YBCVGal 5:1-15 YBCVGal 5:1-15 YBCV