Gal 4:8-11
Gal 4:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati ẹnyin kò ti mọ̀ Ọlọrun rí, ẹnyin ti nsìnrú fun awọn ti kì iṣe ọlọrun nipa ẹda. Ṣugbọn nisisiyi, nigbati ẹnyin ti mọ̀ Ọlọrun tan, tabi ki a sá kuku wipe, ẹ di mimọ̀ fun Ọlọrun, ẽha ti ri ti ẹ fi tun yipada si alailera ati alagbe ipilẹṣẹ ẹda, labẹ eyiti ẹnyin tun fẹ pada wa sinru? Ẹnyin nkiyesi ọjọ, ati oṣù, ati akokò, ati ọdún. Ẹru nyin mba mi, ki o má ba ṣe pe lasan ni mo ti ṣe lãlã lori nyin.
Gal 4:8-11 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun. Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn? Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún! Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán!
Gal 4:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti ṣe ẹrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ìṣẹ̀dá. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a sá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, èéha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti agbára ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá ṣe ẹrú? Ẹ̀yin ń kíyèsi ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún. Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín.