Gal 4:13-15
Gal 4:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ẹnyin mọ̀ pe ailera ara li o jẹ ki nwasu ihinrere fun nyin li akọṣe. Eyiti o si jẹ idanwo fun nyin li ara mi li ẹ kò kẹgàn, bẹni ẹ kò si kọ̀; ṣugbọn ẹnyin gbà mi bi angẹli Ọlọrun, ani bi Kristi Jesu. Njẹ ayọ nyin igbana ha da? nitori mo gbà ẹ̀ri nyin jẹ pe, iba ṣe iṣe, ẹ ba yọ oju nyin jade, ẹ ba si fi wọn fun mi.
Gal 4:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ mọ̀ pé àìlera ni ó mú kí n waasu ìyìn rere fun yín ní àkọ́kọ́. Ẹ kò kọ ohun tí ó jẹ́ ìdánwò fun yín ninu ara mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fi mí ṣẹ̀sín, ṣugbọn ẹ gbà mí bí ẹni pé angẹli Ọlọrun ni mí, àní bí ẹni pé èmi ni Kristi Jesu. Kò sí bí inú yín kò ti dùn tó nígbà náà. Kí ni ó wá dé nisinsinyii! Nítorí mo jẹ́rìí yín pé bí ó bá ṣeéṣe nígbà náà ẹ̀ bá yọ ojú yín fún mi!
Gal 4:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́. Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí angẹli Ọlọ́run, àní bí Kristi Jesu. Ǹjẹ́ ayọ̀ yín ìgbà náà ha dà? Nítorí mo gba ẹ̀rí yín pé, bi o bá ṣe é ṣe, ẹ̀ ò bá yọ ojú yín jáde, ẹ̀ bá sì fi wọ́n fún mi.