Gal 4:12-14
Gal 4:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín ni, ẹ dàbí mo ti dà nítorí èmi náà ti dàbí yín. Ẹ kò ṣẹ̀ mí rárá. Ẹ mọ̀ pé àìlera ni ó mú kí n waasu ìyìn rere fun yín ní àkọ́kọ́. Ẹ kò kọ ohun tí ó jẹ́ ìdánwò fun yín ninu ara mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fi mí ṣẹ̀sín, ṣugbọn ẹ gbà mí bí ẹni pé angẹli Ọlọrun ni mí, àní bí ẹni pé èmi ni Kristi Jesu.
Gal 4:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ará, mo bẹ̀ nyin, ẹ dà bi emi; nitori emi dà bi ẹnyin: ẹnyin kò ṣe mi ni ibi kan. Ṣugbọn ẹnyin mọ̀ pe ailera ara li o jẹ ki nwasu ihinrere fun nyin li akọṣe. Eyiti o si jẹ idanwo fun nyin li ara mi li ẹ kò kẹgàn, bẹni ẹ kò si kọ̀; ṣugbọn ẹnyin gbà mi bi angẹli Ọlọrun, ani bi Kristi Jesu.
Gal 4:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dàbí èmi: nítorí èmi dàbí ẹ̀yin: ẹ̀yin kò ṣe mí ní ibi kan. Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́. Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí angẹli Ọlọ́run, àní bí Kristi Jesu.