Gal 4:1-31

Gal 4:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ mo wipe, niwọn igbati arole na ba wà li ewe, kò yàtọ ninu ohunkohun si ẹrú bi o tilẹ jẹ oluwa ohun gbogbo; Ṣugbọn o wà labẹ olutọju ati iriju titi fi di akokò ti baba ti yàn tẹlẹ. Gẹgẹ bẹ̃ si li awa, nigbati awa wà li ewe, awa wà li ondè labẹ ipilẹṣẹ ẹda: Ṣugbọn nigbati akokò kíkun na de, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ jade wá, ẹniti a bí ninu obinrin, ti a bi labẹ ofin, Lati ra awọn ti mbẹ labẹ ofin pada, ki awa ki o le gbà isọdọmọ. Ati nitoriti ẹnyin nṣe ọmọ, Ọlọrun si ti rán Ẹmí Ọmọ rẹ̀ wá sinu ọkàn nyin, ti nke pe, Abba, Baba. Nitorina iwọ kì iṣe ẹrú mọ́, bikoṣe ọmọ; ati bi iwọ ba iṣe ọmọ, njẹ iwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kristi. Ṣugbọn nigbati ẹnyin kò ti mọ̀ Ọlọrun rí, ẹnyin ti nsìnrú fun awọn ti kì iṣe ọlọrun nipa ẹda. Ṣugbọn nisisiyi, nigbati ẹnyin ti mọ̀ Ọlọrun tan, tabi ki a sá kuku wipe, ẹ di mimọ̀ fun Ọlọrun, ẽha ti ri ti ẹ fi tun yipada si alailera ati alagbe ipilẹṣẹ ẹda, labẹ eyiti ẹnyin tun fẹ pada wa sinru? Ẹnyin nkiyesi ọjọ, ati oṣù, ati akokò, ati ọdún. Ẹru nyin mba mi, ki o má ba ṣe pe lasan ni mo ti ṣe lãlã lori nyin. Ará, mo bẹ̀ nyin, ẹ dà bi emi; nitori emi dà bi ẹnyin: ẹnyin kò ṣe mi ni ibi kan. Ṣugbọn ẹnyin mọ̀ pe ailera ara li o jẹ ki nwasu ihinrere fun nyin li akọṣe. Eyiti o si jẹ idanwo fun nyin li ara mi li ẹ kò kẹgàn, bẹni ẹ kò si kọ̀; ṣugbọn ẹnyin gbà mi bi angẹli Ọlọrun, ani bi Kristi Jesu. Njẹ ayọ nyin igbana ha da? nitori mo gbà ẹ̀ri nyin jẹ pe, iba ṣe iṣe, ẹ ba yọ oju nyin jade, ẹ ba si fi wọn fun mi. Njẹ mo ha di ọta nyin nitori mo sọ otitọ fun nyin bi? Nwọn nfi itara wá nyin, ṣugbọn ki iṣe fun rere; nwọn nfẹ já nyin kuro, ki ẹnyin ki o le mã wá wọn. Ṣugbọn o dara lati mã fi itara wá ni fun rere nigbagbogbo, kì si iṣe nigbati mo wà pẹlu nyin nikan. Ẹnyin ọmọ mi kekeke, ẹnyin ti mo tún nrọbi titi a o fi ṣe ẹda Kristi ninu nyin. Iba wù mi lati wà lọdọ nyin nisisiyi, ki emi ki o si yi ohùn mi pada nitoripe mo dãmu nitori nyin. Ẹ wi fun mi, ẹnyin ti nfẹ wà labẹ ofin, ẹ kò ha gbọ́ ofin? Nitori a ti kọ ọ pe, Abrahamu ni ọmọ ọkunrin meji, ọkan lati ọdọ ẹrú-binrin, ati ọkan lati ọdọ omnira-obinrin. Ṣugbọn a bí eyiti iṣe ti ẹrúbinrin nipa ti ara; ṣugbọn eyi ti omnira-obinrin li a bí nipa ileri. Nkan wọnyi jẹ apẹrẹ: nitoripe awọn obinrin wọnyi ni majẹmu mejeji; ọkan lati ori oke Sinai wá, ti a bí li oko-ẹrú, ti iṣe Hagari. Nitori Hagari yi ni òke Sinai Arabia, ti o si duro fun Jerusalemu ti o wà nisisiyi, ti o si wà li oko-ẹrú pẹlu awọn ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn Jerusalemu ti oke jẹ omnira, eyiti iṣe iya wa. Nitori a ti kọ ọ pe, Mã yọ̀, iwọ àgan ti kò bímọ: bú si ayọ̀ ki o si kigbe soke, iwọ ti kò rọbi rí; nitori awọn ọmọ ẹni alahoro pọ̀ jù ti abilekọ lọ. Njẹ ará, ọmọ ileri li awa gẹgẹ bi Isaaki. Ṣugbọn bi eyiti a bí nipa ti ara ti ṣe inunibini nigbana si eyiti a bí nipa ti Ẹmi, bẹ̃ si ni nisisiyi. Ṣugbọn iwe-mimọ́ ha ti wi? Lé ẹrú-binrin na jade ati ọmọ rẹ̀: nitori ọmọ ẹrú-binrin kì yio ba ọmọ omnira-obinrin jogun pọ̀. Nitorina, ará, awa kì iṣe ọmọ ẹrú-binrin, bikoṣe ti omnira-obinrin.

Gal 4:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Ohun tí mò ń sọ ni pé nígbà tí àrólé bá wà ní ọmọde kò sàn ju ẹrú lọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó ni gbogbo nǹkan tí Baba rẹ̀ fi sílẹ̀. Nítorí pé òun alára wà lábẹ́ àwọn olùtọ́jú, ohun ìní rẹ̀ sì wà ní ìkáwọ́ àwọn alámòójútó títí di àkókò tí baba rẹ̀ ti dá. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu wa. Nígbà tí a jẹ́ ọmọde, a jẹ́ ẹrú àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀mí tí a kò fojú rí. Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu, kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ. Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́. Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun. Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn? Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún! Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán! Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín ni, ẹ dàbí mo ti dà nítorí èmi náà ti dàbí yín. Ẹ kò ṣẹ̀ mí rárá. Ẹ mọ̀ pé àìlera ni ó mú kí n waasu ìyìn rere fun yín ní àkọ́kọ́. Ẹ kò kọ ohun tí ó jẹ́ ìdánwò fun yín ninu ara mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fi mí ṣẹ̀sín, ṣugbọn ẹ gbà mí bí ẹni pé angẹli Ọlọrun ni mí, àní bí ẹni pé èmi ni Kristi Jesu. Kò sí bí inú yín kò ti dùn tó nígbà náà. Kí ni ó wá dé nisinsinyii! Nítorí mo jẹ́rìí yín pé bí ó bá ṣeéṣe nígbà náà ẹ̀ bá yọ ojú yín fún mi! Mo wá ti di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fun yín! Kì í ṣe ire yín ni àwọn tí wọn ń ṣaájò yín ń wá. Ohun tí wọn ń wá ni kí wọ́n lè fi yín sinu àhámọ́, kí ẹ lè máa wá wọn. Ó dára kí á máa wá ara ẹni ninu ohun rere nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo bá wà pẹlu yín nìkan. Ẹ̀yin ọmọ mi, ara ń ni mí nítorí yín, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́, títí ẹ óo fi di àwòrán Kristi. Ó wù mí bíi pé kí n wà lọ́dọ̀ yín nisinsinyii, kí n yí ohùn mi pada, nítorí ọ̀rọ̀ yín rú mi lójú. Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin: ṣé ẹ gbọ́ ohun tí òfin wí? Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Abrahamu ní ọmọ meji, ọ̀kan ọmọ ẹrubinrin, ọ̀kan ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira. Ó bí ọmọ ti ẹrubinrin nípa ìfẹ́ ara, ṣugbọn ó bí ọmọ ti obinrin tí ó ní òmìnira nípa ìlérí Ọlọrun. Àkàwé ni nǹkan wọnyi. Obinrin mejeeji yìí jẹ́ majẹmu meji, ọ̀kan láti òkè Sinai, tí ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹrú; èyí ni Hagari. Hagari ni òkè Sinai ní Arabia tíí ṣe àpẹẹrẹ Jerusalẹmu ti òní. Ó wà ninu ipò ẹrú pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn Jerusalẹmu ti òkè wà ninu òmìnira. Òun ni ìyá wa. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Máa yọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ rí. Sọ̀rọ̀ kí o kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí. Nítorí àwọn ọmọ àgàn pọ̀ ju ti obinrin tí ó ní ọkọ lọ.” Ṣugbọn ẹ̀yin, ará, ọmọ ìlérí bíi Isaaki ni yín. Ṣugbọn bí ó ti rí látijọ́, tí ọmọ tí a bí nípa ìfẹ́ ara ń ṣe inúnibíni ọmọ tí a bí nípa Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di ìsinsìnyìí. Ṣugbọn kí ni Ìwé Mímọ́ wí? Ó ní, “Lé ẹrubinrin ati ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrubinrin kò ní bá ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira pín ogún baba wọn.” Nítorí náà, ará, a kì í ṣe ọmọ ẹrubinrin, ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira ni wá.

Gal 4:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ǹjẹ́ ohun tí mo ń wí ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àrólé náà bá wà ní èwe, kò yàtọ̀ nínú ohunkóhun sí ẹrú bí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n ó wà lábẹ́ olùtọ́jú àti ìríjú títí àkókò tí baba ti yàn tẹ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, nígbà tí àwa wà ní èwe, àwa wà nínú ìdè lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin. Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ, Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.” Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti ṣe ẹrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ìṣẹ̀dá. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a sá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, èéha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti agbára ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá ṣe ẹrú? Ẹ̀yin ń kíyèsi ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún. Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín. Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dàbí èmi: nítorí èmi dàbí ẹ̀yin: ẹ̀yin kò ṣe mí ní ibi kan. Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́. Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí angẹli Ọlọ́run, àní bí Kristi Jesu. Ǹjẹ́ ayọ̀ yín ìgbà náà ha dà? Nítorí mo gba ẹ̀rí yín pé, bi o bá ṣe é ṣe, ẹ̀ ò bá yọ ojú yín jáde, ẹ̀ bá sì fi wọ́n fún mi. Ǹjẹ́ mo ha di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fún yín bí? Wọ́n ń fi ìtara wá yin, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún rere; wọ́n ń fẹ́ já yin kúrò, kí ẹ̀yin lè máa wá wọn. Ṣùgbọ́n ó dára láti máa fi ìtara wá ni fún ohun rere nígbà gbogbo, kì í sì í ṣe nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nìkan. Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèkéé, ẹ̀yin tí mo tún ń rọbí títí a ó fi ṣe ẹ̀dá Kristi nínú yín. Ìbá wù mí láti wà lọ́dọ̀ yín nísinsin yìí, kí èmi sì yí ohùn mi padà nítorí pé mo dààmú nítorí yín. Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin ohun ti òfin sọ. Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Abrahamu ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin. Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara: ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira obìnrin ni a bí nípa ìlérí. Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní májẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sinai wá, tí a bí lóko ẹrú, tí í ṣe Hagari. Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa. Nítorí a ti kọ ọ́ pé, “Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn tí kò bímọ, bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀ yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.” Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki. Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsin yìí. Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira obìnrin jogún pọ̀.” Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrúbìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.