Gal 3:23-26
Gal 3:23-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ki igbagbọ́ to de, a ti pa wa mọ́ labẹ ofin, a si sé wa mọ́ de igbagbọ́ ti a mbọwa fihàn. Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ́. Ṣugbọn lẹhin igbati igbagbọ́ ti de, awa kò si labẹ olukọni mọ́. Nitoripe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo nyin, nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.
Gal 3:23-26 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn kí àkókò igbagbọ yìí tó tó, a wà ninu àtìmọ́lé lábẹ́ òfin, a sé wa mọ́ títí di àkókò igbagbọ yìí. Èyí ni pé òfin jẹ́ olùtọ́ wa títí Kristi fi dé, kí á lè dá wa láre nípa igbagbọ. Nígbà tí àkókò igbagbọ ti dé, a kò tún nílò olùtọ́ mọ́. Nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ọlọrun nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu.
Gal 3:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fihàn. Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùtọ́jú mọ́. Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.