Gal 3:15-22

Gal 3:15-22 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí á lo àkàwé kan ninu ìrírí eniyan. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, nígbà tí a bá ti ṣe majẹmu tán, kò sí ẹni tí ó lè yí i pada tabi tí ó lè fi gbolohun kan kún un. Nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu ati irú-ọmọ rẹ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ ni Ọlọrun ń sọ, ṣugbọn ọmọ kanṣoṣo ni ó tọ́ka sí. Ó sọ pé, “Ati fún irú-ọmọ rẹ.” Ọmọ náà ni Kristi. Kókó ohun tí mò ń sọ ni pé òfin tí ó dé lẹ́yìn ọgbọnlenirinwo (430) ọdún kò lè pa majẹmu tí Ọlọrun ti ṣe rẹ́. Ìlérí tí Ọlọrun ti ṣe kò lè torí rẹ̀ di òfo. Nítorí bí eniyan bá lè di ajogún nípa òfin, a jẹ́ pé kì í tún ṣe ìlérí mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni nípa ìlérí ni Ọlọrun fún Abrahamu ní ogún. Ipò wo wá ni òfin wà? Kí eniyan lè mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ṣe fi òfin kún ìlérí, títí irú-ọmọ tí ó ṣe ìlérí rẹ̀ fún yóo fi dé. Láti ọwọ́ àwọn angẹli ni alárinà ti gba òfin. Ètò tí alárinà bá lọ́wọ́ sí ti kúrò ní ti ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọrun. Ǹjẹ́ òfin wá lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọrun ni bí? Rárá o! Bí ó bá jẹ́ pé òfin tí a fi fúnni lè sọ eniyan di alààyè, eniyan ìbá lè di olódodo nípa òfin. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ ti sọ pé ohun gbogbo wà ninu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ kí á lè fi ìlérí nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi fún gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́.

Gal 3:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ará, èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ènìyàn ti a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́. Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣe wí pé, Fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀, bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, àti fún irú-ọmọ rẹ̀, èyí tí í ṣe Kristi. Èyí tí mò ń wí ni pé: májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣàájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, kí ó sì mú ìlérí náà di aláìlágbára. Nítorí bí ogún náà bá dúró lórí ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí í òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́: ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Abrahamu nípa ìlérí. Ǹjẹ́ kí ha ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipasẹ̀ àwọn angẹli ṣe ìlànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá. Ǹjẹ́ onílàjà kì í ṣe alárinà ti ẹnìkan, ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run. Nítorí náà òfin ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọ ni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà. Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ti fi yé wa pé gbogbo ènìyàn ni ń bẹ lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fún àwọn tí ó gbàgbọ́.