Gal 2:1-21

Gal 2:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

LẸHIN ọdún mẹrinla, nigbana ni mo tún gòke lọ si Jerusalemu pẹlu Barnaba, mo si mu Titu lọ pẹlu mi. Mo si gòke lọ nipa ifihan, mo si gbe ihinrere na kalẹ niwaju wọn ti mo nwasu larin awọn Keferi, ṣugbọn nikọ̀kọ fun awọn ti o jẹ ẹni-nla, ki emi kì o má ba sáre, tabi ki o má ba jẹ pe mo ti sáre lasan. Ṣugbọn a kò fi agbara mu Titu ti o wà pẹlu mi, ẹniti iṣe ara Hellene, lati kọla: Ati nitori awọn eke arakunrin ti a yọ́ mu wọ̀ inu wa wá, awọn ẹniti o yọ́ wa iṣe amí lati ri omnira wa, ti awa ni ninu Kristi Jesu, ki nwọn ki o le mu wa wá sinu ìde: Awọn ẹniti awa kò si fi àye fun lati dari wa fun wakati kan; ki otitọ ìhinrere ki o le mã wà titi pẹlu nyin. Ṣugbọn niti awọn ti o dabi ẹni nla, ohunkohun ti o wù ki nwọn jasi, kò jẹ nkankan fun mi: Ọlọrun kò ṣe ojuṣãju ẹnikẹni: ani awọn ti o dabi ẹni-nla, kò kọ́ mi ni nkankan. Ṣugbọn kàkà bẹ̃, nigbati nwọn ri pe a ti fi ihinrere ti awọn alaikọla le mi lọwọ, bi a ti fi ihinrere ti awọn onila le Peteru lọwọ; (Nitori ẹniti o ṣiṣẹ ninu Peteru si iṣẹ Aposteli ti ikọla, on kanna li o ṣiṣẹ ninu mi fun awọn Keferi pẹlu), Ati nigbati Jakọbu, ati Kefa, ati Johanu, awọn ẹniti o dabi ọwọ̀n, woye ore-ọfẹ ti a fifun mi, nwọn si fi ọwọ́ ọtún ìdapọ fun emi ati Barnaba, pe ki awa ki o mã lọ sọdọ awọn Keferi, ati awọn sọdọ awọn onila. Kìki nwọn fẹ ki a mã ranti awọn talakà, ohun kanna gan ti mo nfi titaratitara ṣe pẹlu. Ṣugbọn nigbati Peteru wá si Antioku, mo ta kò o li oju ara rẹ̀, nitoriti o jẹ ẹniti a ba bawi. Nitoripe ki awọn kan ti o ti ọdọ Jakọbu wá to de, o ti mba awọn Keferi jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn de, o fà sẹhin, o si yà ara rẹ̀ si apakan, o mbẹ̀ru awọn ti iṣe onila. Awọn Ju ti o kù si jùmọ ṣe agabagebe bẹ̃ gẹgẹ pẹlu rẹ̀; tobẹ̃ ti nwọn si fi agabagebe wọn fà Barnaba tikararẹ lọ. Ṣugbọn nigbati mo ri pe nwọn kò rìn dẽdẽ gẹgẹ bi otitọ ihinrere, mo wi fun Peteru niwaju gbogbo wọn pe, Bi iwọ, ti iṣe Ju, ba nrìn gẹgẹ bi ìwa awọn Keferi, laiṣe bi awọn Ju, ẽṣe ti iwọ fi nfi agbara mu awọn Keferi lati mã rìn bi awọn Ju? Awa ti iṣe Ju nipa ẹda, ti kì si iṣe ẹlẹṣẹ ti awọn Keferi, Ti a mọ̀ pe a ko da ẹnikẹni lare nipa iṣẹ ofin, bikoṣe nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, ani awa na gbà Jesu Kristi gbọ́, ki a ba le da wa lare nipa igbagbọ́ ti Kristi, kì si iṣe nipa iṣẹ ofin: nitoripe nipa iṣẹ ofin kò si enia kan ti a o dalare. Ṣugbọn nigbati awa ba nwá ọ̀na lati ri idalare nipa Kristi, bi a ba si ri awa tikarawa li ẹlẹṣẹ, njẹ́ Kristi ha nṣe iranṣẹ ẹ̀ṣẹ bi? Ki a má ri. Nitoripe bi mo ba si tun gbe ohun wọnni ti mo ti wó palẹ ró, mo fi ara mi han bi arufin. Nitoripe nipa ofin mo ti di oku si ofin, ki emi ki o le wà lãye si Ọlọrun. A ti kàn mi mọ agbelebu pẹlu Kristi: ṣugbọn mo wà lãye, sibẹ ki iṣe emi mọ́, ṣugbọn Kristi wà lãye ninu mi: wiwà ti mo si wà lãye ninu ara, mo wa lãye ninu igbagbọ Ọmọ Ọlọrun, ẹniti o fẹ mi, ti o si fi on tikararẹ̀ fun mi. Emi kò sọ ore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitoripe bi ododo ba ti ipa ofin wá, njẹ Kristi kú lasan.

Gal 2:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn ọdún mẹrinla ni mo tó tún gòkè lọ sí Jerusalẹmu pẹlu Banaba. Mo mú Titu lọ́wọ́ pẹlu. Ọlọrun ni ó fihàn mí lójúran ni mo fi lọ. Mo wá ṣe àlàyé níwájú àwọn aṣaaju nípa ìyìn rere tí mò ń waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Níkọ̀kọ̀ ni a sọ̀rọ̀ kí gbogbo iré-ìje tí mò ń sá ati èyí tí mo ti sá má baà jẹ́ lásán. Kì í ṣe ọ̀ranyàn ni pé kí á kọ Titu tí ó wà pẹlu mi nílà nítorí pé ọmọ ẹ̀yà Giriki ni. Àwọn tí ó gbé ọ̀rọ̀ nípa ìkọlà Titu jáde ni àwọn arakunrin èké tí wọ́n yọ́ wá wo òmìnira wa tí a ní ninu Kristi Jesu, kí wọ́n lè sọ wá di ẹrú òfin. Ṣugbọn a kò fi ìgbà kankan gbà wọ́n láyè rárá, kí ó má dàbí ẹni pé ọ̀rọ̀ tiwọn ni ó borí, kí òtítọ́ ìyìn rere lè wà pẹlu yín. Ṣugbọn àwọn tí wọn ń pè ní aṣaaju ninu wọn kò kọ́ mi ní ohun titun kan. Ohun tí ó mú kí n sọ̀rọ̀ báyìí ni pé kò sí ohun tí ó kàn mí ninu ọ̀rọ̀ a-jẹ́-aṣaaju tabi a-kò-jẹ́-aṣaaju. Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. Ṣugbọn wọ́n wòye pé a ti fi iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà fún mi ṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti fún Peteru ní iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn tí ó kọlà. Nítorí ẹni tí ó fún Peteru ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí wọ́n kọlà ni ó fún mi ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí Jakọbu, Peteru ati Johanu, tí àwọn eniyan ń wò bí òpó ninu ìjọ, rí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun ti fi fún mi, wọ́n bọ èmi ati Banaba lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ìdàpọ̀, wọ́n ní kí àwa lọ sáàrin àwọn tí kì í ṣe Juu bí àwọn náà ti ń lọ sáàrin àwọn tí ó kọlà. Nǹkankan ni wọ́n sọ fún wa, pé kí á ranti àwọn talaka láàrin àwọn tí ó kọlà. Òun gan-an ni mo sì ti dàníyàn láti máa ṣe. Ṣugbọn nígbà tí Peteru wà ní Antioku, mo takò ó lojukooju nítorí ó ṣe ohun ìbáwí. Nítorí kí àwọn kan tó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu dé, Peteru ti ń bá àwọn onigbagbọ tí kì í ṣe Juu jẹun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí fà sẹ́yìn, ó ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, nítorí ó ń bẹ̀rù àwọn tí wọ́n fẹ́ kí gbogbo onigbagbọ kọlà. Àwọn Juu yòókù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgàbàgebè pẹlu Peteru. Wọ́n tilẹ̀ mú Banaba pàápàá wọ ẹgbẹ́ àgàbàgebè wọn! Nígbà tí mo rí i pé ohun tí wọn ń ṣe kò bá òtítọ́ ìyìn rere mu, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ tí ó jẹ́ Juu bá ti ń ṣe bí àwọn yòókù, tí o kò ṣe bí àṣà àwọn Juu, kí ló dé tí o fi fẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ara wọn bíi Juu?” Àwa tí a bí ní Juu, tí a kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, mọ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa iṣẹ́ òfin, àfi nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi. Àwa pàápàá gba Kristi Jesu gbọ́, kí Ọlọrun lè dá wa láre nípa igbagbọ ninu rẹ̀, kì í ṣe nípa iṣẹ́ òfin. Nígbà tí à ń wá ọ̀nà ìdáláre ninu Kristi, bí a bá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwa náà, ṣé Kristi wá di iranṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o! Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí mo ti wó lulẹ̀ ni mo tún ń kọ́, èmi náà di ẹlẹ́ṣẹ̀. Nítorí nípa òfin, mo ti kú sinu òfin kí n lè wà láàyè lọ́dọ̀ Ọlọrun. A ti kàn mí mọ́ agbelebu pẹlu Kristi. Mo wà láàyè, ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo wà láàyè; Kristi ni ó ń gbé inú mi. Ìgbé-ayé tí mò ń gbé ninu ara nisinsinyii, nípa igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun tí ó fẹ́ràn mi ni. Ó fẹ́ràn mi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi. Kì í ṣe pé mo pa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tì. Nítorí bí eniyan bá lè di olódodo nípa ṣíṣe iṣẹ́ òfin, a jẹ́ pé Kristi kàn kú lásán ni.

Gal 2:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jerusalẹmu pẹ̀lú Barnaba, mo sì mú Titu lọ pẹ̀lú mi. Mo gòkè lọ nípa ohun ti a fihàn mi, mo fi ìhìnrere náà tí mo ń wàásù láàrín àwọn aláìkọlà yé àwọn tí ó jẹ́ ẹni ńlá nínú wọn, èyí i nì ní ìkọ̀kọ̀, kí èmi kí ó má ba á sáré, tàbí kí ó máa ba à jẹ́ pé mo ti sáré lásán. Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè. Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìhìnrere náà. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìhìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìhìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́. Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà. Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù. Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe. Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí. Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà. Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà. Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn keferi láti máa rìn bí àwọn Júù? “Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe ‘aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,’ Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì! Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fi ara mi hàn bí arúfin. “Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láààyè sí Ọlọ́run. A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi. Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan: nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”