Esr 7:1-28

Esr 7:1-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ lẹhin nkan wọnyi, ni ijọba Artasasta ọba Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah, Ọmọ Ṣallumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu, Ọmọ Amariah, ọmọ Asariah, ọmọ Meraiotu, Ọmọ Serahiah, ọmọ Ussi, ọmọ Bukki, Ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olori alufa: Esra yi li o gòke lati Babiloni wá; o si jẹ ayáwọ́-akọwe ninu ofin Mose, ti Oluwa Ọlọrun Israeli fi fun ni: ọba si fun u li ohun gbogbo ti o bère, gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ti wà lara rẹ̀. Ati ninu awọn ọmọ Israeli, ati ninu awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn akọrin, ati awọn adèna, pẹlu awọn Netinimu si goke wá si Jerusalemu li ọdun keje Artasasta ọba. On si wá si Jerusalemu li oṣu karun, eyi ni ọdun keje ọba. Nitoripe lati ọjọ kini oṣu ekini li o bẹrẹ si igòke lati Babiloni wá, ati li ọjọ ikini oṣu karun li o de Jerusalemu, gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun rẹ̀ ti o wà lara rẹ̀. Nitori Esra ti mura tan li ọkàn rẹ̀ lati ma wá ofin Oluwa, ati lati ṣe e, ati lati ma kọ́ni li ofin ati idajọ ni Israeli. Eyi si ni atunkọ iwe na ti Artasasta ọba fi fun Esra alufa, akọwe, ani akọwe ọ̀rọ ofin Oluwa, ati ti aṣẹ rẹ̀ fun Israeli. Artasasta, ọba awọn ọba, si Esra alufa, akọwe pipé ti ofin Ọlọrun ọrun, alafia: Mo paṣẹ pe, ki gbogbo enia ninu awọn enia Israeli, ati ninu awọn alufa rẹ̀ ati awọn ọmọ Lefi, ninu ijọba mi, ẹniti o ba fẹ nipa ifẹ inu ara wọn lati gòkẹ lọ si Jerusalemu, ki nwọn ma ba ọ lọ. Niwọn bi a ti rán ọ lọ lati iwaju ọba lọ ati ti awọn ìgbimọ rẹ̀ mejeje, lati wadi ọ̀ran ti Juda ati Jerusalemu gẹgẹ bi ofin Ọlọrun rẹ ti mbẹ li ọwọ rẹ; Ati lati ko fàdaka ati wura, ti ọba ati awọn ìgbimọ fi tinutinu fi fun Ọlọrun Israeli, ibugbe ẹniti o wà ni Jerusalemu. Ati gbogbo fàdaka ati wura ti iwọ le ri ni gbogbo igberiko Babiloni, pẹlu ọrẹ atinuwa awọn enia, ati ti awọn alufa, ti iṣe ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun wọn ti o wà ni Jerusalemu. Ki iwọ ki o le fi owo yi rà li aijafara, akọmalu, àgbo, ọdọ-agutan, ati ọrẹ ohun jijẹ wọn ati ọrẹ ohun mimu wọn, ki o si fi wọn rubọ li ori pẹpẹ ile Ọlọrun nyin ti o wà ni Jerusalemu. Ati ohunkohun ti o ba wu ọ, ati awọn arakunrin rẹ lati fi fàdaka ati wura iyokù ṣe, eyini ni ki ẹnyin ki o ṣe gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun nyin. Ohun-èlo wọnni ti a fi fun ọ pẹlu fun ìsin ile Ọlọrun rẹ, ni ki iwọ ki o fi lelẹ niwaju Ọlọrun ni Jerusalemu. Ati ohunkohun ti a ba fẹ pẹlu fun ile Ọlọrun rẹ, ti iwọ o ri àye lati nawo rẹ̀, nawo rẹ̀ lati inu ile iṣura ọba wá. Ati emi, ani Artasasta ọba paṣẹ fun gbogbo awọn olutọju iṣura, ti o wà li oke odò pe, ohunkohun ti Esra alufa, ti iṣe akọwe ofin Ọlọrun ọrun yio bère lọwọ nyin, ki a ṣe e li aijafara, Titi de ọgọrun talenti fàdaka, ati de ọgọrun oṣuwọn alikama, ati de ọgọrun bati ọti-waini, ati de ọgọrun bati ororo, ati iyọ laini iye. Ohunkohun ti Ọlọrun ọrun palaṣẹ, ki a fi otitọ ṣe e fun ile Ọlọrun ọrun: ki ibinu ki o má de si ijọba ọba, ati awọn ọmọ rẹ̀. Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin kò ni oyè lati di owo-ori, owo-odè, ati owo-bodè ru gbogbo awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, awọn akọrin, awọn adèna, awọn Netinimu, ati awọn iranṣẹ ninu ile Ọlọrun yi, Ati iwọ, Esra, gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun rẹ ti o wà li ọwọ rẹ, yan awọn oloyè ati onidajọ, ti nwọn o ma da ẹjọ fun gbogbo awọn enia ti o wà li oke-odò, gbogbo iru awọn ti o mọ̀ ofin Ọlọrun rẹ, ki ẹnyin ki o si ma kọ́ awọn ti kò mọ̀ wọn. Ẹnikẹni ti kì o si ṣe ofin Ọlọrun rẹ, ati ofin ọba, ki a mu idajọ ṣe si i lara li aijafara, bi o ṣe si ikú ni, tabi lilé si oko, tabi kiko li ẹrù, tabi si sisọ sinu tubu. Olubukun li Oluwa Ọlọrun awọn baba wa, ti o fi nkan bi iru eyi si ọkàn ọba, lati ṣe ogo si ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu: Ti o si nàwọ anu si mi niwaju ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀, ati niwaju gbogbo awọn alagbara ijoye ọba: mo si ri iranlọwọ gbà gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun mi ti o wà lara mi, mo si ko awọn olori awọn enia jọ lati inu Israeli jade, lati ba mi goke lọ.

Esr 7:1-28 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ọkunrin kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹsira, ọmọ Seraaya, ọmọ Asaraya, ọmọ Hilikaya, ọmọ Ṣalumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu, ọmọ Amaraya, ọmọ Asaraya, ọmọ Meraiotu, ọmọ Serahaya, ọmọ Usi, ọmọ Buki, ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, olórí alufaa. Láti Babiloni ni Ẹsira tí à ń wí yìí ti dé. Akọ̀wé ni, ó sì já fáfá ninu òfin Mose, tí OLUWA Ọlọrun Israẹli fún wọn. Ọba fún un ní gbogbo nǹkan tí ó bèèrè, nítorí pé ó rí ojurere OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ní ọdún keje ìjọba Atasasesi, díẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ìgbèkùn dé: àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn iranṣẹ ninu Tẹmpili, wá sí Jerusalẹmu. Ní oṣù karun-un ọdún keje ìjọba Atasasesi ni Ẹsira dé sí Jerusalẹmu. Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Babiloni ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un nítorí pé ó rí ojurere Ọlọrun. Nítorí Ẹsira fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sí kíkọ́ òfin OLUWA, ati pípa á mọ́ ati kíkọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé tí ọba Atasasesi fún Ẹsira nìyí, “Láti ọ̀dọ̀ Atasasesi ọba, sí Ẹsira, alufaa, tí ó tún jẹ́ akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run. “Mo pàṣẹ jákèjádò ìjọba mi pé bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi bá fẹ́ bá ọ pada lọ sí Jerusalẹmu, kí ó máa bá ọ lọ; nítorí pé èmi ati àwọn olùdámọ̀ràn mi meje ni a rán ọ lọ láti ṣe ìwádìí fínnífínní lórí Juda ati Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun rẹ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ, ati pé kí o kó ọrẹ wúrà ati fadaka lọ́wọ́, tí ọba ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún Ọlọrun Israẹli, tí ibùgbé rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu. O níláti kó gbogbo wúrà ati fadaka tí o bá rí ní gbogbo agbègbè Babiloni, ati ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn alufaa bá fínnúfẹ́dọ̀ dá jọ fún Tẹmpili Ọlọrun wọn ní Jerusalẹmu. “Ṣíṣọ́ ni kí o ṣọ́ owó yìí ná: fi ra akọ mààlúù, àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan ati èròjà ẹbọ ohun jíjẹ ati ohun mímu, kí o fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Tẹmpili Ọlọrun rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu. Fadaka ati wúrà tí ó bá ṣẹ́kù, ìwọ ati àwọn eniyan rẹ, ẹ lò ó bí ó ti yẹ lójú yín ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun yín. Gbogbo ohun èlò tí wọ́n kó fún ọ fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun ni kí o kó lọ sí Jerusalẹmu, níwájú Ọlọrun. Bí o bá fẹ́ ohunkohun sí i fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun rẹ, gbà á ninu ilé ìṣúra ọba. “Èmi Atasasesi ọba pàṣẹ fún àwọn olùtọ́jú ilé ìṣúra ní agbègbè òdìkejì odò láti pèsè gbogbo nǹkan tí Ẹsira, alufaa akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run, bá fẹ́ fún un. Ó láṣẹ láti gbà tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati ọtí waini, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati òróró, ati ìwọ̀n iyọ̀ tí ó bá fẹ́. Kí ẹ rí i pé ẹ tọ́jú gbogbo nǹkan tí Ọlọrun ọ̀run bá pa láṣẹ fún lílò ninu Tẹmpili rẹ̀, kí ibinu rẹ̀ má baà wá sórí ibùjókòó ọba ati àwọn ọmọ rẹ̀. A tún fi ń ye yín pé kò bá òfin mu láti gba owó ìṣákọ́lẹ̀, tabi owó bodè, tabi owó orí lọ́wọ́ àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi, tabi àwọn akọrin, tabi àwọn aṣọ́nà, tabi àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tabi àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ninu ilé Ọlọrun. “Kí ìwọ Ẹsira, lo ọgbọ́n tí Ọlọrun rẹ fún ọ, kí o yan àwọn alákòóso ati àwọn adájọ́ tí wọ́n mọ òfin Ọlọrun rẹ, kí wọ́n lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. Kí o sì kọ́ àwọn tí kò mọ òfin Ọlọrun rẹ kí àwọn náà lè mọ̀ ọ́n. Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹríba fún òfin Ọlọrun rẹ ati àṣẹ ọba, pípa ni a óo pa á, tabi kí á wà á lọ kúrò ní ìlú, tabi kí á gba dúkìá rẹ̀, tabi kí á gbé e sọ sẹ́wọ̀n.” Ẹsira bá dáhùn pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wa, tí ó fi sí ọba lọ́kàn láti ṣe ọ̀ṣọ́ sí tẹmpili Ọlọrun ní Jerusalẹmu, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí níwájú ọba, pẹlu àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pataki pataki. Nítorí pé OLUWA Ọlọrun wà pẹlu mi, mo ṣe ọkàn gírí, mo kó àwọn aṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli jọ, mo ní kí wọ́n bá mi kálọ.”

Esr 7:1-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní àkókò ìjọba ọba Artasasta ní Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah, Ọmọ Ṣallumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu, ọmọ Amariah, ọmọ Asariah, ọmọ Meraioti, ọmọ Serahiah, ọmọ Ussi, ọmọ Bukki, ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olórí àlùfáà— Esra yìí sì gòkè wá láti Babeli. Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfin Mose, èyí tí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, ti fi fún wọn. Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ OLúWA Ọlọ́run wà lára rẹ̀. Ní ọdún keje ọba Artasasta díẹ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili náà gòkè wá sí Jerusalẹmu. Ní oṣù karùn-ún ọdún keje ọba yìí ni Esra dé sí Jerusalẹmu. Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ láti Babeli ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ara rẹ̀. Esra ti fi ara rẹ̀ jì fún kíkọ́ àti pípa òfin OLúWA mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mose ní Israẹli. Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà ti ọba Artasasta fún àlùfáà Esra olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà OLúWA fún Israẹli: Artasasta, ọba àwọn ọba, Sí àlùfáà Esra, olùkọ́ òfin Ọlọ́run ọ̀run: Àlàáfíà. Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jerusalẹmu lè tẹ̀lé ọ lọ. Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèje rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Juda àti Jerusalẹmu. Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu, pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Babeli àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹmpili Ọlọ́run wọn ní Jerusalẹmu. Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rú ẹbọ lórí pẹpẹ tẹmpili Ọlọ́run rẹ ní Jerusalẹmu. Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tókù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín. Kó gbogbo ohun èlò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ fún Ọlọ́run Jerusalẹmu fún ìsìn nínú tẹmpili Ọlọ́run rẹ. Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹmpili Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba. Èmi, ọba Artasasta, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Eufurate láìrójú láti pèsè ohunkóhun tí àlùfáà Esra, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín tó ọgọ́ọ̀rún kan tálẹ́ǹtì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òṣùwọ̀n àlìkámà, àti dé ọgọ́rùn-ún bati ọtí wáìnì, àti dé ọgọ́rùn-ún bati òróró olifi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀. Ohunkóhun tí Ọlọ́run ọ̀run bá fẹ́, jẹ́ kí ó di ṣíṣe ní pípé fún tẹmpili Ọlọ́run ọ̀run. Èéṣe tí ìbínú yóò ṣe wá sí agbègbè ọba àti sí orí àwọn ọmọ rẹ̀? Ìwọ sì ní láti mọ̀ pé ìwọ kò ní àṣẹ láti sọ sísan owó orí, owó òde tàbí owó bodè di dandan fún àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà, àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili tàbí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ilé Ọlọ́run yìí. Ìwọ Esra, ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Ọlọ́run rẹ̀, èyí tí ó ní, yan àwọn adájọ́ àgbà àti àwọn onídàájọ́ láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn agbègbè Eufurate, gbogbo àwọn tí ó mọ òfin Ọlọ́run rẹ. Ìwọ yóò sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò mọ̀ àwọn òfin náà. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìgbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run rẹ àti sí òfin ọba ní ó gbọdọ̀ kú tàbí kí a lé e jáde tàbí kí a gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù rẹ̀ tàbí kí a sọ ọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. Olùbùkún ni OLúWA, Ọlọ́run àwọn baba wa, ẹni tí ó fi sí ọkàn ọba láti mú ọlá wá sí ilé OLúWA ní Jerusalẹmu ní ọ̀nà yìí. Ẹni tí ó jẹ́ kí ojúrere rẹ̀ tàn kàn mí níwájú ọba àti àwọn olùbádámọ̀ràn àti ní iwájú àwọn alágbára ìjòyè ọba. Nítorí ọwọ́ OLúWA Ọlọ́run wà lára mi, mo mú ọkàn le, mo sì kó àwọn olórí jọ láàrín àwọn ènìyàn Israẹli láti gòkè lọ pẹ̀lú mi.