Esr 6:13-22
Esr 6:13-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Tatnai bãlẹ ni ihahin-odò, Ṣetarbosnai, ati awọn ẹgbẹ wọn, gẹgẹ bi eyiti Dariusi ọba ti ranṣẹ, bẹ̃ni nwọn ṣe li aijafara. Awọn àgba Juda si kọle, nwọn si ṣe rere nipa iyanju Haggai woli ati Sekariah ọmọ Iddo. Nwọn si kọle, nwọn si pari rẹ̀ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Israeli, ati gẹgẹ bi aṣẹ Kirusi, ati Dariusi ati Artasasta ọba Persia. A si pari ile yi li ọjọ kẹta oṣu Adari, ti iṣe ọdun kẹfa ijọba Dariusi ọba. Awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi pẹlu awọn ọmọ ìgbekun ìyoku ṣe ìyasimimọ́ ile Ọlọrun yi pẹlu ayọ̀. Ni iyasimimọ́ ile Ọlọrun yi, ni nwọn si rubọ ọgọrun akọ-malu, igba àgbo, irinwo ọdọ-agutan; ati fun ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli, obukọ mejila gẹgẹ bi iye awọn ẹ̀ya Israeli: Nwọn si fi awọn alufa si gẹgẹ bi ipa wọn ati awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ipa wọn, fun isin Ọlọrun ni Jerusalemu, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose. Awọn ọmọ igbekun si ṣe ajọ irekọja li ọjọ kẹrinla oṣu ekini. Nitoriti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ti wẹ̀ ara wọn mọ́ bi ẹnikan, gbogbo wọn li o si mọ́, nwọn si pa ẹran irekọja fun gbogbo awọn ọmọ igbekun, ati fun awọn arakunrin wọn, awọn alufa, ati fun awọn tikara wọn. Awọn ọmọ Israeli ti o ti inu igbekun pada bọ̀, ati gbogbo iru awọn ti o ti ya ara wọn si ọdọ wọn kuro ninu ẽri awọn keferi ilẹ na, lati ma ṣe afẹri Oluwa Ọlọrun Israeli, si jẹ àse irekọja. Nwọn si fi ayọ̀ ṣe ajọ aiwukara li ọjọ meje: nitoriti Oluwa ti mu wọn yọ̀, nitoriti o yi ọkàn ọba Assiria pada si ọdọ wọn, lati mu ọwọ wọn le ninu iṣẹ ile Ọlọrun, Ọlọrun Israeli.
Esr 6:13-22 Yoruba Bible (YCE)
Tatenai, gomina, Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí Dariusi ọba pa fún wọn lẹ́sẹẹsẹ. Àwọn àgbààgbà Juu ń kọ́ ilé náà, wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí pẹlu ìdálọ́kànle tí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Hagai ati Sakaraya, ọmọ Ido ń fún wọn. Wọ́n parí kíkọ́ tẹmpili náà bí Ọlọrun Israẹli ti pa á láṣẹ fún wọn ati gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Kirusi, ati ti Dariusi ati ti Atasasesi, àwọn ọba Pasia. Wọ́n parí kíkọ́ Tẹmpili náà ní ọjọ́ kẹta oṣù Adari, ní ọdún kẹfa ìjọba Dariusi. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi ati àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé bá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ tẹmpili náà. Ọgọrun-un ọ̀dọ́ akọ mààlúù, igba (200) àgbò, ati irinwo (400) ọ̀dọ́ aguntan ni wọ́n fi rú ẹbọ ìyàsímímọ́ náà. Wọ́n sì fi ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Wọ́n sì fi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ipò wọn ninu iṣẹ́ ìsìn inú Tẹmpili, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé Mose. Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ọdún tí ó tẹ̀lé e, àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ṣe ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ya ara wọn sí mímọ́ lápapọ̀, fún ayẹyẹ náà. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá fún àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú, wọ́n pa fún àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn, ati fún àwọn tìkara wọn. Gbogbo àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ati àwọn tí wọ́n kọ ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ láti sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí wọn ń bá wọn gbé ní ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì wá síbi ayẹyẹ náà pẹlu wọn, ni wọ́n jọ jẹ àsè náà. Ọjọ́ meje ni wọ́n fi fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ Àjọ Àìwúkàrà, nítorí pé Ọlọrun ti fún wọn ní ayọ̀ nítorí inú ọba Asiria tí ó yọ́ sí wọn, tí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ilé Ọlọrun Israẹli kọ́.
Esr 6:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dariusi pa, Tatenai, Baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate, àti Ṣetar-bosnai pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pa á mọ́ láìyí ọ̀kan padà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, ìran Iddo. Wọ́n parí kíkọ́ ilé OLúWA gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Israẹli àti àwọn àṣẹ Kirusi, Dariusi àti Artasasta àwọn ọba Persia pọ̀. A parí ilé OLúWA ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari (oṣù kejì) ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́ọ̀rún mẹ́rin akọ ọ̀dọ́-àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli. Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose. Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn (oṣù kẹrin), àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá. Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Lefi pa ọ̀dọ́-àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá OLúWA Ọlọ́run Israẹli. Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ àkàrà àìwú pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí OLúWA ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Asiria padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.