Esr 6:11-18
Esr 6:11-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pẹlupẹlu mo ti paṣẹ pe, ẹnikẹni ti o ba yi ọ̀rọ yi pada, ki a fa igi lulẹ li ara ile rẹ̀, ki a si gbe e duro, ki a fi on na kọ si ori rẹ̀, ki a si sọ ile rẹ̀ di ãtàn nitori eyi. Ki Ọlọrun ẹniti o mu ki orukọ rẹ̀ ma gbe ibẹ, ki o pa gbogbo ọba, ati orilẹ-ède run, ti yio da ọwọ wọn le lati ṣe ayipada, ati lati pa ile Ọlọrun yi run, ti o wà ni Jerusalemu. Emi Dariusi li o ti paṣẹ, ki a mu u ṣẹ li aijafara. Nigbana ni Tatnai bãlẹ ni ihahin-odò, Ṣetarbosnai, ati awọn ẹgbẹ wọn, gẹgẹ bi eyiti Dariusi ọba ti ranṣẹ, bẹ̃ni nwọn ṣe li aijafara. Awọn àgba Juda si kọle, nwọn si ṣe rere nipa iyanju Haggai woli ati Sekariah ọmọ Iddo. Nwọn si kọle, nwọn si pari rẹ̀ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Israeli, ati gẹgẹ bi aṣẹ Kirusi, ati Dariusi ati Artasasta ọba Persia. A si pari ile yi li ọjọ kẹta oṣu Adari, ti iṣe ọdun kẹfa ijọba Dariusi ọba. Awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi pẹlu awọn ọmọ ìgbekun ìyoku ṣe ìyasimimọ́ ile Ọlọrun yi pẹlu ayọ̀. Ni iyasimimọ́ ile Ọlọrun yi, ni nwọn si rubọ ọgọrun akọ-malu, igba àgbo, irinwo ọdọ-agutan; ati fun ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli, obukọ mejila gẹgẹ bi iye awọn ẹ̀ya Israeli: Nwọn si fi awọn alufa si gẹgẹ bi ipa wọn ati awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ipa wọn, fun isin Ọlọrun ni Jerusalemu, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose.
Esr 6:11-18 Yoruba Bible (YCE)
Siwaju sí i, mo tún pàṣẹ pé, bí ẹnikẹ́ni bá rú òfin mi yìí, kí wọ́n yọ ọ̀kan ninu igi òrùlé rẹ̀; kí wọ́n gbẹ́ ẹ ṣóńṣó, kí wọ́n tì í bọ̀ ọ́ láti ìdí títí dé orí rẹ̀. Kí wọ́n sì sọ ilé rẹ̀ di ààtàn. Kí Ọlọrun, tí ó yan Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ibi ìsìn rẹ̀, pa ẹni náà run, kì báà ṣe ọba tabi orílẹ̀-èdè kan ni ó bá tàpá sí òfin yìí, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti wó ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu. Èmi Dariusi ọba ni mo pa àṣẹ yìí, ẹ sì gbọdọ̀ mú un ṣẹ fínnífínní.” Tatenai, gomina, Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí Dariusi ọba pa fún wọn lẹ́sẹẹsẹ. Àwọn àgbààgbà Juu ń kọ́ ilé náà, wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí pẹlu ìdálọ́kànle tí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Hagai ati Sakaraya, ọmọ Ido ń fún wọn. Wọ́n parí kíkọ́ tẹmpili náà bí Ọlọrun Israẹli ti pa á láṣẹ fún wọn ati gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Kirusi, ati ti Dariusi ati ti Atasasesi, àwọn ọba Pasia. Wọ́n parí kíkọ́ Tẹmpili náà ní ọjọ́ kẹta oṣù Adari, ní ọdún kẹfa ìjọba Dariusi. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi ati àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé bá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ tẹmpili náà. Ọgọrun-un ọ̀dọ́ akọ mààlúù, igba (200) àgbò, ati irinwo (400) ọ̀dọ́ aguntan ni wọ́n fi rú ẹbọ ìyàsímímọ́ náà. Wọ́n sì fi ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Wọ́n sì fi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ipò wọn ninu iṣẹ́ ìsìn inú Tẹmpili, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé Mose.
Esr 6:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a sì fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn. Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀-èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹmpili yìí tí ó wà ní Jerusalẹmu run. Èmi Dariusi n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímúṣẹ láìyí ohunkóhun padà. Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dariusi pa, Tatenai, Baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate, àti Ṣetar-bosnai pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pa á mọ́ láìyí ọ̀kan padà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, ìran Iddo. Wọ́n parí kíkọ́ ilé OLúWA gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Israẹli àti àwọn àṣẹ Kirusi, Dariusi àti Artasasta àwọn ọba Persia pọ̀. A parí ilé OLúWA ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari (oṣù kejì) ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́ọ̀rún mẹ́rin akọ ọ̀dọ́-àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli. Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose.