Esr 5:1-5
Esr 5:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN awọn woli, Haggai woli, ati Sekariah ọmọ Iddo, sọ asọtẹlẹ fun awọn Ju ti o wà ni Juda ati Jerusalemu li orukọ Ọlọrun Israeli. Li akoko na ni Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki dide, nwọn si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile Ọlọrun ni Jerusalemu; awọn woli Ọlọrun si wà pẹlu wọn ti nràn wọn lọwọ. Li akoko kanna ni Tatnai, bãlẹ ni ihahin odò, ati Ṣetar-bosnai pẹlu awọn ẹgbẹ wọn, wá si ọdọ wọn, nwọn si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati tun odi yi ṣe? Nigbana ni awa wi fun wọn bayi, pe, Orukọ awọn ọkunrin ti nkọ́ ile yi ti ijẹ? Ṣugbọn oju Ọlọrun wọn mbẹ li ara awọn àgba Juda, ti nwọn kò fi le mu wọn ṣiwọ titi ọ̀ran na fi de ọdọ Dariusi: nigbana ni nwọn si fi èsi pada, nipa iwe nitori eyi.

Esr 5:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Wolii Hagai ati wolii Sakaraya, ọmọ Ido, bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn Juu tí wọ́n wà ni Juda ati Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó jẹ́ orí fún wọn. Nígbà tí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Jeṣua, ọmọ Josadaki gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí àtikọ́ ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu, àwọn wolii Ọlọrun mejeeji sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní àkókò kan náà, Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò ati Ṣetari Bosenai ati gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá sí ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n bi wọ́n léèrè pé: “Ta ló fun yín láṣẹ láti kọ́ tẹmpili yìí ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ? Ati pé, kí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ń kọ́ ilé yìí?” Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu àwọn olórí Juu, wọn kò sì lè dá wọn dúró títí tí wọn fi kọ̀wé sí Dariusi ọba, tí wọ́n sì rí èsì ìwé náà gbà.
Esr 5:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, láti ìran Iddo, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Juda àti Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọ́run Israẹli tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn. Nígbà náà Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua ọmọ Josadaki gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní àkókò náà Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹgbẹgbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?” Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?” Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbàgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró títí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dariusi kí wọ́n sì gba èsì tí àkọsílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.