Esr 4:1-23
Esr 4:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI awọn ọta Juda ati Benjamini gbọ́ pe awọn ọmọ-igbekun nkọ́ tempili fun Oluwa Ọlọrun Israeli; Nigbana ni nwọn tọ̀ Serubbabeli wá, ati awọn olori awọn baba, nwọn si wi fun wọn pe, ẹ jẹ ki awa ki o ba nyin kọle, nitoriti awa nṣe afẹri Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin; awa si nru ẹbọ si ọdọ rẹ̀, lati ọjọ Esarhaddoni, ọba Assuri, ẹniti o mu wa gòke wá ihinyi. Ṣugbọn Serubbabeli, ati Jeṣua ati iyokù ninu awọn olori awọn baba Israeli wi fun wọn pe, Kì iṣe fun awa pẹlu ẹnyin, lati jumọ kọ ile fun Ọlọrun wa; ṣugbọn awa tikarawa ni yio jùmọ kọle fun Oluwa Ọlọrun Israeli gẹgẹ bi Kirusi ọba, ọba Persia, ti paṣẹ fun wa, Nigbana ni awọn enia ilẹ na mu ọwọ awọn enia Juda rọ, nwọn si yọ wọn li ẹnu ninu kikọle na. Nwọn si bẹ̀ awọn ìgbimọ li ọ̀wẹ si wọn, lati sọ ipinnu wọn di asan, ni gbogbo ọjọ Kirusi, ọba Persia, ani titi di ijọba Dariusi, ọba Persia. Ati ni ijọba Ahasuerusi, ni ibẹ̀rẹ ijọba rẹ̀, ni nwọn kọwe ẹ̀sun lati fi awọn ara Juda ati Jerusalemu sùn. Ati li ọjọ Artasasta ni Biṣlami, Mitredati, Tabeeli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ iyokù kọwe si Artasasta, ọba Persia: a si kọ iwe na li ède Siria, a si ṣe itumọ rẹ̀ li ède Siria. Rehumu, adele ọba, ati Ṣimṣai, akọwe, kọ iwe ẹ̀sun Jerusalemu si Artasasta ọba, bi iru eyi: Nigbana ni Rehumu, adele-ọba, ati Ṣimṣai akọwe, ati awọn ẹgbẹ wọn iyokù: awọn ara Dina, ti Afarsatki, ti Tarpeli, ti Afarsi, ti Arkefi, ti Babiloni, ti Susanki, ti Dehafi ati ti Elamu, Ati awọn orilẹ-ède iyokù ti Asnapperi, ọlọla ati ẹni-nla nì, kó rekọja wá, ti o si fi wọn do si ilu Samaria, ati awọn iyokù ti o wà ni ihahin odò, ati ẹlomiran. Eyi ni atunkọ iwe na ti nwọn fi ranṣẹ si i, ani si Artasasta ọba: Iranṣẹ rẹ, awọn enia ihahin odò ati ẹlomiran. Ki ọba ki o mọ̀ pe, awọn Ju ti o ti ọdọ rẹ wá si ọdọ wa, nwọn de Jerusalemu, nwọn nkọ́ ọlọtẹ ilu ati ilu buburu, nwọn si ti fi odi rẹ̀ lelẹ, nwọn si ti so ipilẹ rẹ̀ mọra pọ̀. Ki ọba ki o mọ̀ nisisiyi pe, bi a ba kọ ilu yi, ti a si tun odi rẹ̀ gbe soke tan, nigbana ni nwọn kì o san owo ori, owo-bode, ati owo odè, ati bẹ̃ni nikẹhin yio si pa awọn ọba li ara. Njẹ nisisiyi lati ãfin ọba wá li a sa ti mbọ́ wa, kò si yẹ fun wa lati ri àbuku ọba, nitorina li awa ṣe ranṣẹ lati wi fun ọba daju; Ki a le wá inu iwe-iranti awọn baba rẹ: bẹ̃ni iwọ o ri ninu iwe-iranti, iwọ o si mọ̀ pe, ọlọtẹ ni ilu yi, ti o si pa awọn ọba ati igberiko li ara, ati pe, nwọn ti ṣọtẹ ninu ikanna lati atijọ wá, nitori eyi li a fi fọ ilu na. Awa mu u da ọba li oju pe, bi a ba tun ilu yi kọ, ti a si pari odi rẹ̀ nipa ọ̀na yi, iwọ kì o ni ipin mọ ni ihahin odò. Nigbana ni ọba fi èsi ranṣẹ si Rehumu, adele-ọba, ati si Ṣimṣai, akọwe, pẹlu awọn ẹgbẹ wọn iyokù ti ngbe Samaria, ati si awọn iyokù li oke odò: Alafia! ati kiki miran. A kà iwe ti ẹnyin fi ranṣẹ si wa dajudaju niwaju mi. Mo si paṣẹ, a si ti wá, a si ri pe, lati atijọ wá, ilu yi a ti ma ṣọ̀tẹ si awọn ọba, ati pe irukerudo ati ọ̀tẹ li a ti nṣe ninu rẹ̀. Pẹlupẹlu awọn ọba alagbara li o ti wà lori Jerusalemu, awọn ti o jọba lori gbogbo ilu oke-odò; owo ori, owo odè, ati owo bodè li a ti nsan fun wọn. Ki ẹnyin ki o paṣẹ nisisiyi lati mu awọn ọkunrin wọnyi ṣiwọ, ki a má si kọ ilu na mọ, titi aṣẹ yio fi jade lati ọdọ mi wá. Ẹ kiyesi ara nyin, ki ẹnyin ki o má jafara lati ṣe eyi: ẽṣe ti ìbajẹ yio fi ma dàgba si ipalara awọn ọba? Njẹ nigbati a ka atunkọ iwe Artasasta ọba niwaju Rehumu, ati Ṣimṣai akọwe, ati awọn ẹgbẹ wọn, nwọn gòke lọ kankán si Jerusalemu, si ọdọ awọn Ju, nwọn si fi ipá pẹlu agbara mu wọn ṣiwọ.
Esr 4:1-23 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà ti àwọn ọ̀tá Juda ati ti Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli, wọ́n wá sọ́dọ̀ Serubabeli, ati sọ́dọ̀ àwọn baálé baálé, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á jọ kọ́ ọ nítorí ọ̀kan náà ni wá, Ọlọrun yín ni àwa náà ń sìn, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà ayé Esaradoni, ọba Asiria, tí ó mú wa wá síhìn-ín.” Ṣugbọn Serubabeli, Jeṣua, ati àwọn baálé baálé tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli dá wọn lóhùn pé, “A kò fẹ́ kí ẹ bá wa lọ́wọ́ sí kíkọ́ ilé OLUWA Ọlọrun wa. Àwa nìkan ni a óo kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí Kirusi, ọba Pasia, ti pa á láṣẹ fún wa.” Nígbà náà ni àwọn tí wọ́n ti ń gbé ilẹ̀ náà mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn ará ilẹ̀ Juda, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n, kí wọ́n má baà lè kọ́ tẹmpili náà. Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn èké tí wọ́n ń san owó fún láti da ìpinnu àwọn ará Juda rú ní gbogbo àkókò ìjọba Kirusi, ọba Pasia, títí di àkókò Dariusi, ọba Pasia. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi, àwọn kan kọ ìwé wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn tí ń gbé Juda ati Jerusalẹmu. Ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ni àwọn wọnyi dìde: Biṣilamu, Mitiredati, Tabeeli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù. Wọ́n kọ̀wé sí ọba Pasia ní èdè Aremia, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀. Rehumu, olórí ogun, ati Ṣimiṣai, akọ̀wé, ni wọ́n kọ ìwé ẹ̀sùn sí ọba Atasasesi, nípa Jerusalẹmu ní orúkọ àwọn mejeeji ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ṣẹ́kù pẹlu àwọn adájọ́, àwọn gomina ati àwọn ará Pasia, àwọn eniyan Ereki, àwọn ará Babiloni ati àwọn eniyan Susa, àwọn ará Elamu, pẹlu àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí Osinapari, alágbára ati ọlọ́lá, kó wá láti máa gbé àwọn ìlú Samaria ati àwọn agbègbè tí wọ́n wà ní òdìkejì odò. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí: “Sí ọba Atasasesi, àwa iranṣẹ rẹ tí a wà ní agbègbè òdìkejì odò kí ọba. A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn Juu tí wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wa ti lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí tún ìlú burúkú náà, tí ó kún fún ọ̀tẹ̀ kọ́. Wọ́n ti mọ odi rẹ̀, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ parí ìpìlẹ̀ rẹ̀. Kabiyesi, tí wọ́n bá fi lè kọ́ ìlú náà parí, tí wọ́n sì parí odi rẹ̀, wọn kò ní san owó ìṣákọ́lẹ̀ mọ́. Eléyìí yóo sì dín owó tí ń wọ àpò ọba kù. A kò lè rí ohun tí kò dára kí á má sọ nítorí pé abẹ́ rẹ ni a ti ń jẹ; nítorí náà ni a fi gbọdọ̀ sọ fún ọba. Ìmọ̀ràn wa ni pé, kí ọba pàṣẹ láti lọ wá àkọsílẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín ti kọ. Ẹ óo rí i pé ìlú ọlọ̀tẹ̀ ni ìlú yìí. Láti ìgbà laelae ni wọ́n ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba agbègbè wọn. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi pa ìlú náà run. A fẹ́ tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọba létí pé bí àwọn eniyan wọnyi bá kọ́ ìlú yìí tí wọ́n sì mọ odi rẹ̀, kò ní ku ilẹ̀ kankan mọ́ fún ọba ní agbègbè òdìkejì odò.” Ọba désì ìwé náà pada sí Rehumu, olórí ogun ati Ṣimiṣai, akọ̀wé, ati sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí wọn ń gbé Samaria ati agbègbè òdìkejì odò yòókù. Ó ní, “Mo ki yín. Wọ́n ka ìwé tí ẹ kọ sí wa, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi. Mo pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìwádìí, a sì rí i pé láti ayébáyé ni ìlú yìí tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba wọn. Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerusalẹmu, wọ́n ti jọba lórí gbogbo agbègbè òdìkejì odò, wọ́n sì gba owó ìṣákọ́lẹ̀, owó bodè lọ́wọ́ àwọn eniyan. Nítorí náà, ẹ pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró títí wọn yóo fi gbọ́ àṣẹ mìíràn láti ọ̀dọ̀ mi. Ẹ má ṣe fi iṣẹ́ náà jáfara, nítorí tí ẹ bá fi falẹ̀, ó lè pa ọba lára.” Lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n ka ìwé ọba tán sí etígbọ̀ọ́ Rehumu ati Ṣimiṣai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, Rehumu ati Ṣimiṣai yára lọ sí Jerusalẹmu pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọn sì fi ipá dá iṣẹ́ náà dúró.
Esr 4:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àwọn ọ̀tá Juda àti Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ìgbèkùn tí ó padà dé ń kọ́ tẹmpili fún OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Serubbabeli àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé, wọ́n sì wí pé, “Jẹ́ kí a bá a yín kọ́ nítorí pé, bí i tiyín, a ń wá Ọlọ́run yín, a sì ti ń rú ẹbọ sí i láti ìgbà Esarhadoni ọba Asiria, tí ó mú wa wá sí ibi yìí.” Ṣùgbọ́n Serubbabeli, Jeṣua àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Israẹli dáhùn pé, “Ẹ kò ní ohunkóhun pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa. Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, bí Kirusi, ọba Persia, ti pàṣẹ fún wa.” Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú ọwọ́ àwọn ènìyàn Juda rọ, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n ní ti kíkọ́ ilé náà. Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lòdì sí wọn àti láti sọ ète wọn di asán ní gbogbo àsìkò ìjọba Kirusi ọba Persia àti títí dé ìgbà ìjọba Dariusi ọba Persia. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahaswerusi wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu. Àti ní àkókò ìjọba Artasasta ọba Persia, Biṣilami, Mitredati, Tabeli àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Artasasta. A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Aramaiki èdè Aramaiki sì ní a fi kọ ọ́. Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé jùmọ̀ kọ́ ìwé láti dojúkọ Jerusalẹmu sí Artasasta ọba báyìí: Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tókù—àwọn ará Dina, ti Afarsatki, ti Tarpeli, ti Afarsi, Ereki àti Babeli, àwọn ará Elamu ti Susa, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí ẹni ọlá àti ẹni ọ̀wọ̀ Asnappari kó jáde, tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí ìlú Samaria àti níbòmíràn ní agbègbè e Eufurate. (Èyí ni ẹ̀dà ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i.) Sí ọba Artasasta, Láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin agbègbè Eufurate: Ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn ará Júù tí ó gòkè wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti lọ sí Jerusalẹmu wọ́n sì ń tún ìlú búburú àti ìlú ọlọ̀tẹ̀ ẹ nì kọ́. Wọ́n ń tún àwọn ògiri náà kọ́, wọ́n sì ń tún àwọn ìpìlẹ̀ náà ṣe. Síwájú sí i, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù. Nísinsin yìí níwọ̀n ìgbà tí a ní ojúṣe sí ààfin ọba, kò sì bójúmu fún wa láti rí ìtàbùkù ọba, àwa ń rán iṣẹ́ yìí láti sọ fún ọba, kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn aṣíwájú rẹ̀. Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò rí i wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oníwàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́. Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run. A fi dá ọba lójú wí pé tí a bá tún ìlú kọ́ àti ti àwọn ògiri rẹ̀ si di mímọ padà, kì yóò sì ohun ti yóò kù ọ́ kù ní agbègbè Eufurate. Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà: Sí Rehumu balógun, Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí ń gbé ní Samaria àti ní òpópónà Eufurate: Ìkíni. A ti ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi. Mo pa àṣẹ, a sì ṣe ìwádìí, nínú ìtàn ọjọ́ pípẹ́ àti ti ìsinsin yìí ti ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba pẹ̀lú, ó sì jẹ́ ibi ìṣọ̀tẹ̀ àti ìrúkèrúdò. Jerusalẹmu ti ní àwọn ọba alágbára tí ń jẹ ọba lórí gbogbo àwọn agbègbè Eufurate, àti àwọn owó orí, owó òde àti owó ibodè sì ni wọ́n ń san fún wọn. Nísinsin yìí pa àṣẹ fún àwọn ọkùnrin yìí láti dá iṣẹ́ dúró, kí a má ṣe tún ìlú náà kọ títí èmi yóò fi pàṣẹ. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe àìkọbi-ara sí ọ̀rọ̀ yìí. Èéṣe tí ìbàjẹ́ yóò fi pọ̀ sí i, sí ìpalára àwọn ọba? Ní kété tí a ka ẹ̀dà ìwé ọba Artasasta sí Rehumu àti Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, wọ́n yára lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní Jerusalẹmu pẹ̀lú, wọ́n fi agbára mú wọn láti dáwọ́ dúró.