Esr 3:10-13
Esr 3:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati awọn ọmọle si fi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ, nwọn mu awọn alufa duro ninu aṣọ wọn, nwọn mu ipè lọwọ, ati awọn ọmọ Lefi, awọn ọmọ Asafu mu kimbali lọwọ, lati ma yìn Oluwa gẹgẹ bi ìlana Dafidi ọba Israeli. Nwọn si jùmọ kọrin lẹsẹsẹ lati yìn ati lati dupẹ fun Oluwa, nitoripe o ṣeun, ati pe anu rẹ̀ si duro lailai lori Israeli. Gbogbo enia si ho iho nla, nigbati nwọn nyìn Oluwa, nitoriti a fi ipilẹ ile Oluwa lelẹ. Ṣugbọn pupọ ninu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori awọn baba ti iṣe alàgba, ti nwọn ti ri ile atetekọṣe, nwọn fi ohùn rara sọkun, nigbati a fi ipilẹ ile yi lelẹ li oju wọn, ṣugbọn awọn pupọ si ho iho nla fun ayọ̀: Tobẹ̃ ti awọn enia kò le mọ̀ iyatọ ariwo ayọ̀ kuro ninu ariwo ẹkun awọn enia; nitori awọn enia ho iho nla, a si gbọ́ ariwo na li okere rére.
Esr 3:10-13 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí àwọn mọlémọlé bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀, àwọn alufaa gbé ẹ̀wù wọn wọ̀, wọ́n dúró pẹlu fèrè lọ́wọ́ wọn. Ìdílé Asafu, ẹ̀yà Lefi, ń lu kimbali wọn, wọ́n fí ń yin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi, ọba Israẹli, ti ṣe. Pẹlu orin ìyìn ati ìdúpẹ́ wọ́n ń kọrin sí OLUWA pẹlu ègbè rẹ̀ pé, “OLUWA ṣeun, ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí lae.” Gbogbo àwọn eniyan hó ìhó ìyìn sí OLUWA, nítorí pé wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀. Ṣugbọn ọpọlọpọ àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi, ati àwọn olórí ìdílé, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n gbọ́njú mọ ilé OLUWA ti tẹ́lẹ̀ sọkún, wọ́n kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí bí a ti ń fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà lélẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn hó fún ayọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ariwo ẹkún ati ti ayọ̀ nítorí pé, gbogbo wọn ń kígbe sókè, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan sì gbọ́ igbe wọn ní ọ̀nà jíjìn réré.
Esr 3:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀lé gbé ìpìlẹ̀ ilé OLúWA kalẹ̀, àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ àlùfáà wọn pẹ̀lú fèrè, àti àwọn ará Lefi (àwọn ọmọ Asafu) pẹ̀lú símbálì, dúró ní ipò wọn láti yin OLúWA, bí Dafidi ọba Israẹli ti fi lélẹ̀. Pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ́ ni wọ́n kọrin sí OLúWA: “Ó dára; ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí láé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì fi ohùn ariwo ńlá yin OLúWA, nítorí tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLúWA lélẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbà àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti àwọn olórí ìdílé, tí ó ti rí tẹmpili OLúWA ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sọkún kíkorò nígbà tí wọ́n rí ìpìlẹ̀ tẹmpili OLúWA yìí tí wọ́n fi lélẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ kígbe fún ayọ̀. Kò sí ẹni tí ó le mọ ìyàtọ̀ láàrín igbe ayọ̀ àti ẹkún, nítorí tí ariwo àwọn ènìyàn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Wọ́n sì gbọ́ igbe náà ní ọ̀nà jíjìn réré.