Esr 3:1-3
Esr 3:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI oṣu keje si pé, ti awọn ọmọ Israeli si wà ninu ilu wọnni, awọn enia na ko ara wọn jọ pọ̀ bi ẹnikan si Jerusalemu. Jeṣua ọmọ Jehosadaki si dide pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ awọn alufa, ati Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati awọn arakunrin rẹ̀, nwọn si tẹ́ pẹpẹ Ọlọrun Israeli, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun lori rẹ̀, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, enia Ọlọrun. Nwọn si gbe pẹpẹ na ka ipilẹ rẹ̀; nitori ẹ̀ru bà wọn nitori awọn enia ilẹ wọnni. Nwọn si rú ẹbọ ọrẹ sisun si Oluwa, ọrẹ ẹbọ sisun li owurọ ati li aṣalẹ.
Esr 3:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ní oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli ti pada sí ìlú wọn, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu. Jeṣua, ọmọ Josadaki pẹlu àwọn alufaa ẹgbẹ́ rẹ̀ ati Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀ tún pẹpẹ Ọlọrun Israẹli kọ́, kí wọ́n baà lè máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, eniyan Ọlọrun. Wọ́n tẹ́ pẹpẹ náà sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn eniyan ibẹ̀; wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí rẹ̀ ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́.
Esr 3:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jerusalẹmu. Nígbà náà ni Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Israẹli láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mose ènìyàn Ọlọ́run Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n síbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ sí OLúWA, ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́.