Esr 2:1-70

Esr 2:1-70 Bibeli Mimọ (YBCV)

WỌNYI li awọn ọmọ igberiko Juda ti o goke wa, lati inu igbèkun awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnessari, ọba Babiloni, ti ko lọ si Babiloni, ti nwọn si pada wá si Jerusalemu ati Juda, olukuluku si ilu rẹ̀: Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin ninu awọn enia Israeli: Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbọkanla o din mejidilọgbọn. Awọn ọmọ Ṣefatiah, irinwo o din mejidilọgbọn. Awọn ọmọ Ara, ẹgbẹrin o din mẹ̃dọgbọn. Awọn ọmọ Pahati-Moabu ninu awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejila. Awọn ọmọ Elamu, adọtalelẹgbẹfa o le mẹrin. Awọn ọmọ Sattu, ọtadilẹgbẹ̀run, o le marun. Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin. Awọn ọmọ Bani, ojilelẹgbẹta, o le meji. Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mẹtalelogun. Awọn ọmọ Asgadi, ẹgbẹfa, o le mejilelogun. Awọn ọmọ Adonikami ọtalelẹgbẹta o le mẹfa. Awọn ọmọ Bigfai, ẹgbã o le mẹrindilọgọta. Awọn ọmọ Adini, adọtalenirinwo o le mẹrin. Awọn ọmọ Ateri ti Hesekiah, mejidilọgọrun. Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹta. Awọn ọmọ Jora, mejilelãdọfa. Awọn ọmọ Haṣumu igba o le mẹtalelogun. Awọn ọmọ Gibbari, marundilọgọrun. Awọn ọmọ Betlehemu, mẹtalelọgọfa. Awọn enia Netofa, mẹrindilọgọta. Awọn enia Anatotu, mejidilãdọje. Awọn ọmọ Asmafeti, mejilelogoji. Awọn ọmọ Kirjat-arimu, Kefira ati Beeroti ọtadilẹgbẹrin o le mẹta. Awọn ọmọ Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun. Awọn ọmọ Mikmasi, mejilelọgọfa. Awọn enia Beteli ati Ai, igba o le mẹtalelogun. Awọn ọmọ Nebo, mejilelãdọta. Awọn ọmọ Magbiṣi mẹrindilọgọjọ. Awọn ọmọ Elamu ekeji, ãdọtalelẹgbẹfa o le mẹrin. Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo. Awọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le marun, Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun. Awọn ọmọ Sanaa, egbejidilogun o le ọgbọn. Awọn alufa; awọn ọmọ Jedaiah, ti idile Jeṣua, ogúndilẹgbẹrun o din meje. Awọn ọmọ Immeri, ãdọtalelẹgbẹrun o le meji. Awọn ọmọ Paṣuri, ojilelẹgbẹfa o le meje. Awọn ọmọ Harimu, ẹgbẹrun o le mẹtadilogun. Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua ati Kadmieli ti awọn ọmọ Hodafiah, mẹrinlelãdọrin. Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdoje. Awọn ọmọ awọn adena: awọn ọmọ Ṣalumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, gbogbo wọn jẹ, mọkandilogoje. Awọn Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Hasufa, awọn ọmọ Tabbaoti. Awọn ọmọ Kerosi, awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Padoni. Awọn ọmọ Lebana, awọn ọmọ Hagaba, awọn ọmọ Akkubu, Awọn ọmọ Hagabu, awọn ọmọ Ṣalmai, awọn ọmọ Hanani; Awọn ọmọ Giddeli, awọn ọmọ Gahari, awọn ọmọ Reaiah, Awọn ọmọ Resini, awọn ọmọ Nekoda, awọn ọmọ Gassamu, Awọn ọmọ Ussa, awọn ọmọ Pasea, awọn ọmọ Besai, Awọn ọmọ Asna, awọn ọmọ Mehunimi, awọn ọmọ Nefusimi, Awọn ọmọ Bakbuki, awọn ọmọ Hakufa, awọn ọmọ Har-huri, Awọn ọmọ Basluti, awọn ọmọ Mehida, awọn ọmọ Harṣa, Awọn ọmọ Barkosi, awọn ọmọ Sisera, awọn ọmọ Tama, Awọn ọmọ Nesia, awọn ọmọ Hatifa, Awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni: awọn ọmọ Sotai, awọn ọmọ Sofereti, awọn ọmọ Peruda, Awọn ọmọ Jaala, awọn ọmọ Darkoni, awọn ọmọ Giddeli, Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Ami. Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni, jẹ irinwo o din mẹjọ. Awọn wọnyi li o si goke wá lati Telmela, Telkarsa, Kerubu, Addani, ati Immeri: ṣugbọn nwọn kò le fi idile baba wọn hàn, ati iru ọmọ wọn, bi ti inu Israeli ni nwọn iṣe: Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ãdọtalelẹgbẹta o le meji. Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Hakosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o fẹ ọkan ninu awọn ọmọ Barsillai obinrin, ara Gileadi li aya, a si pè e nipa orukọ wọn; Awọn wọnyi li o wá iwe itan wọn ninu awọn ti a ṣiro nipa itan idile, ṣugbọn a kò ri wọn, nitori na li a ṣe yọ wọn kuro ninu oye alufa. Balẹ si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o má jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi dide pẹlu Urimu ati pẹlu Tummimu. Apapọ gbogbo ijọ na, jẹ ẹgbã mọkanlelogun o le ojidinirinwo. Li aika iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹbinrin wọn, ti o jẹ ẹgbẹrindilẹgbãrin o din mẹtalelọgọta: igba akọrin ọkunrin ati akọrin obinrin li o si wà ninu wọn. Ẹṣin wọn jẹ, ọtadilẹgbẹrin o din mẹrin; ibaka wọn, ojilugba o le marun. Ibakasiẹ wọn, irinwo o le marundilogoji; kẹtẹkẹtẹ wọn, ẹgbẹrinlelọgbọn o din ọgọrin. Ati ninu awọn olori awọn baba, nigbati nwọn de ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu, nwọn si ta ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun, lati gbe e duro ni ipò rẹ̀. Nwọn fi sinu iṣura iṣẹ na gẹgẹ bi agbara wọn, ọkẹ mẹta ìwọn dramu wura, o le ẹgbẹrun, ẹgbẹdọgbọn mina fadaka, ati ọgọrun ẹ̀wu alufa. Bẹ̃li awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati omiran ninu awọn enia, ati awọn akọrin, ati awọn adèna, ati awọn Netinimu ngbe ilu wọn, gbogbo Israeli si ngbe ilu wọn.

Esr 2:1-70 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Juda wọnyi ni wọ́n pada dé láti oko ẹrú ní Babiloni, níbi tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó wọn lẹ́rú lọ. Wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, olukuluku pada sí ìlú rẹ̀. Àwọn olórí wọn ni: Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Seraaya, Reelaya, Modekai, Biliṣani, Misipa, Bigifai, Rehumu ati Baana. Iye àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n pada láti oko ẹrú ní ìdílé ìdílé nìyí: Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa lé mejilelaadọsan-an (2,172) Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọọdunrun ó lé mejilelaadọrin (372) Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin lé marundinlọgọrin (775) Àwọn ọmọ Pahati Moabu láti inú ìran Jeṣua ati Joabu jẹ́ ẹgbẹrinla lé mejila (2,812) Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254) Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé marundinlaadọta (945) Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (760) Àwọn ọmọ Bani jẹ́ ẹgbẹta ó lé mejilelogoji (642) Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbaata ó lé mẹtalelogun (623) Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mejilelogun (1,222) Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ẹgbẹta ó lé mẹrindinlaadọrin (666) Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹrindinlọgọta (2,056) Àwọn ọmọ Adini jẹ́ irinwo ó lé mẹrinlelaadọta (454) Àwọn ọmọ Ateri láti inú ìran Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹtalelogun (323) Àwọn ọmọ Jora jẹ́ aadọfa ó lé meji (112) Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223) Àwọn ọmọ Gibari jẹ́ marundinlọgọrun-un Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹtalelọgọfa (123) Àwọn eniyan Netofa jẹ́ mẹrindinlọgọta Àwọn eniyan Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128) Àwọn ọmọ Asimafeti jẹ́ mejilelogoji Àwọn ọmọ Kiriati Jearimu; Kefira ati Beeroti jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹtalelogoji (743) Àwọn ọmọ Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta ó lé mọkanlelogun (621) Àwọn ọmọ Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122) Àwọn eniyan Bẹtẹli ati Ai jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223) Àwọn ọmọ Nebo jẹ́ mejilelaadọta Àwọn ọmọ Magibiṣi jẹ́ mẹrindinlọgọjọ (156) Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254) Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320) Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹẹdọgbọn (725) Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345) Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ egbejidinlogun ó lé ọgbọ̀n (3,630) Iye àwọn alufaa tí wọ́n pada dé láti, oko ẹrú wọn nìwọ̀nyí: Àwọn ọmọ Jedaaya láti inú ìdílé Jeṣua jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973) Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052) Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247) Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017) Iye àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú nìwọ̀nyí: Àwọn ọmọ Jeṣua ati Kadimieli láti inú ìran Hodafaya jẹ́ mẹrinlelaadọrin Àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ní tẹmpili jẹ́ mejidinlaadoje (128) Iye àwọn ọmọ àwọn aṣọ́nà: àwọn ọmọ Ṣalumu ati àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni ati àwọn ọmọ Akubu; àwọn ọmọ Hatita ati àwọn ọmọ Ṣobai jẹ́ mọkandínlogoje (139) Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa ati àwọn ọmọ Tabaoti; àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Siaha ati àwọn ọmọ Padoni; àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba ati àwọn ọmọ Akubu; àwọn ọmọ Hagabu, àwọn ọmọ Ṣamlai ati àwọn ọmọ Hanani; àwọn ọmọ Gideli, àwọn ọmọ Gahari ati àwọn ọmọ Reaaya; àwọn ọmọ Resini, àwọn ọmọ Nekoda ati àwọn ọmọ Gasamu; àwọn ọmọ Usa, àwọn ọmọ Pasea, ati àwọn ọmọ Besai; àwọn ọmọ Asina, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefisimu; àwọn ọmọ Bakibuki, àwọn ọmọ Akufa, àwọn ọmọ Hahuri, àwọn ọmọ Basiluti, àwọn ọmọ Mehida, ati àwọn ọmọ Haṣa, àwọn ọmọ Bakosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema, àwọn ọmọ Nesaya ati àwọn ọmọ Hatifa. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìyí: àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Hasofereti, ati àwọn ọmọ Peruda; àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli; àwọn ọmọ Ṣefataya ati àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu ati àwọn ọmọ Ami. Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392). Àwọn kan wá láti Teli Mela, Teli Hariṣa, Kerubu, Adani ati Imeri tí wọn kò mọ ìdílé baba wọn tabi ìran wọn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli àwọn nìwọ̀nyí: Àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Gbogbo wọn jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652). Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ alufaa ninu wọn nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Habaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí ó fẹ́ aya ninu ìdílé Basilai ará Gileadi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ àna rẹ̀ pe àwọn ọmọ rẹ̀). Wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn wọn kò rí i. Nítorí náà a kà wọ́n kún aláìmọ́, a sì yọ wọ́n kúrò ninu iṣẹ́ alufaa. Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn oúnjẹ mímọ́ jùlọ, títí tí wọn yóo fi rí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu láti wádìí lọ́wọ́ OLUWA. Àpapọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaa, ó lé ọtalelọọdunrun (42,360). Láìka àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó lé ojilelọọdunrun ó dín mẹta (7,337). Wọ́n sì tún ní igba (200) akọrin lọkunrin, ati lobinrin. Àwọn ohun ọ̀sìn tí wọ́n kó bọ̀ nìwọ̀nyí: ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736) akọ mààlúù wọn jẹ́ igba ó lé marundinlaadọta (245) Ràkúnmí wọn jẹ́ irinwo ó lé marundinlogoji (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbaata ó lé okoolelẹẹdẹgbẹrin (6,720). Nígbà tí wọ́n dé ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ ninu àwọn olórí ìdílé náà fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ láti tún ilé Ọlọrun kọ́ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ti tó. Wọ́n fi ọọdunrun ó lé mejila (312) kilogiramu wúrà ẹgbẹsan (1,800) kilogiramu fadaka ati ọgọrun-un (100) ẹ̀wù alufaa, ṣe ẹ̀bùn fún ilé OLUWA. Àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn kan ninu àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀. Àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ń gbé àwọn ìlú tí ó wà nítòsí wọn, àwọn ọmọ Israẹli yòókù sì ń gbé àwọn ìlú wọn.

Esr 2:1-70 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lákòókò náà, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Juda tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrín àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Babeli (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí bá Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu àti Baanah wá): Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Israẹli: Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó-lé-méjìléláàádọ́sàn-án (2,172) Ṣefatia jẹ́ òjì-dín-nírínwó ó-lé-méjìlá (372) Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó-dínmẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (775) Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ àwọn ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rìn-lé-méjìlá (2,812) Elamu jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rin (1,254) Sattu jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rún ó-lé-márùn-ún (945) Sakkai jẹ́ òjì-dínlẹ́gbẹ̀rin (760) Bani jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (642) Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mẹ́tàlélógún (623) Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-méjìlélógún (1,222) Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-mẹ́fà (666) Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó-lé-mẹ́rìn-dínlọ́gọ́ta (2,056) Adini jẹ́ aádọ́ta-lé-ní-irínwó ó-lé-mẹ́rin (454) Ateri (nípasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjì-dínlọ́gọ́rin (78) Besai jẹ́ ọrùn-dínnírínwó ó-lé-mẹ́ta (323) Jora jẹ́ méjìléláàdọ́fà (112) Haṣumu jẹ́ igba ó-lé-mẹ́tàlélógún (223) Gibbari jẹ́ márùn-dínlọ́gọ́rùn (95) Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123) Netofa jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́tà (56) Anatoti jẹ́ méjì-dínláàdóje (128) Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì (42) Kiriati-Jearimu, Kefira àti Beeroti jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-mẹ́ta (743) Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mọ́kànlélógún (621) Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122) Beteli àti Ai jẹ́ igba ó-lé-mẹ́tàlélógún (223) Nebo jẹ́ méjìléláàdọ́ta (52) Magbiṣi jẹ́ mẹ́rìn-dínlọ́gọ́jọ (156) Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rìnléláàdọ́ta (1,254) Harimu jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó (320) Lodi, Hadidi àti Ono jẹ́ ọ̀rìn-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-márùn-ún (725) Jeriko jẹ́ ọ̀tà-dínnírínwó ó-lé-márùn-ún (345) Senaa jẹ́ egbèjì-dínlógún ó-lé-ọgbọ̀n (3,630) Àwọn àlùfáà: Àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínméje (973) Immeri jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀rún ó-lé-méjì (1,052) Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́tà-dínláàdọ́ta (1,247) Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó-lé-mẹ́tà-dínlógún (1,017) Àwọn ọmọ Lefi: Àwọn ọmọ Jeṣua àti Kadmieli (ti ìdílé Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́rin (74) Àwọn akọrin: Àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjì-dínláádóje (128) Àwọn aṣọ́bodè: Àwọn ará Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàn-dínlógóje (139) Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili: Àwọn ọmọ Ṣiha, Hasufa, Tabboati, Kerosi, Ṣiaha, Padoni, Lebana, Hagaba, Akkubu, Hagabu, Ṣalmai, Hanani, Giddeli, Gahari, Reaiah, Resini, Nekoda, Gassamu, Ussa, Pasea, Besai, Asna, Mehuni, Nefisimu, Bakbu, Hakufa, Harhuri. Basluti, Mehida, Harṣa, Barkosi, Sisera, Tema, Nesia àti Hatifa. Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni: Àwọn ọmọ Sotai, Sofereti, Peruda, Jaala, Darkoni, Giddeli, Ṣefatia, àwọn ọmọ Hattili, Pokereti ti Haṣebaimu àti àwọn ọmọ Ami. Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irínwó-ó-dínmẹ́jọ (392) Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli: Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (652) Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà: Àwọn ọmọ: Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi a sì ń fi orúkọ náà pè é). Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́. Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu. Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-òjìdínnírínwó (42,360). Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀rìn-dínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́tàlélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin. Wọ́n ní ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínmẹ́rin ẹṣin (736); ìbáaka òjìlélúgba ó-lé-márùn-ún (245) Ràkunmí jẹ́ irínwó ó-lé-márùn-dínlógójì; (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó-dínọgọ́rin (6,720). Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé OLúWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà. Àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé OLúWA ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Israẹli ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.