Esr 1:1-10

Esr 1:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI ọdun ekini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ OLUWA lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, OLUWA rú ẹmi Kirusi, ọba Persia soke, ti o mu ki a kede yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, a si kọwe rẹ̀ pẹlu wipe, Bayi ni Kirusi ọba Persia wi pe, OLUWA, Ọlọrun ọrun, ti fi gbogbo ijọba aiye fun mi; o si ti pa a li aṣẹ lati kọ ile fun on ni Jerusalemu ti o wà ni Juda. Tani ninu nyin ninu gbogbo enia rẹ̀? ki Ọlọrun rẹ̀ ki o wà pẹlu rẹ̀, ki o si goke lọ si Jerusalemu, ti o wà ni Juda, ki o si kọ ile OLUWA Ọlọrun Israeli, on li Ọlọrun, ti o wà ni Jerusalemu. Ati ẹnikẹni ti o kù lati ibikibi ti o ti ngbe, ki awọn enia ibugbe rẹ̀ ki o fi fadaka ràn a lọwọ, pẹlu wura, ati pẹlu ẹrù, ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, pẹlu ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu. Nigbana ni awọn olori awọn baba Juda ati Benjamini dide, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu gbogbo awọn ẹniti Ọlọrun rú ẹmi wọn soke, lati goke lọ, lati kọ́ ile OLUWA ti o wà ni Jerusalemu. Gbogbo awọn ti o wà li agbegbe wọn si fi ohun-èlo fadaka ràn wọn lọwọ, pẹlu wura, pẹlu ẹrù ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, ati pẹlu ohun iyebiye, li aika gbogbo ọrẹ atinuwa. Kirusi ọba si ko ohun èlo ile OLUWA jade, ti Nebukadnessari ti ko jade lọ lati Jerusalemu, ti o si fi sinu ile ọlọrun rẹ̀; Kirusi ọba Persia si ko wọnyi jade nipa ọwọ Mitredati, oluṣọ iṣura, o si ka iye wọn fun Ṣeṣbassari (Serubbabeli) bãlẹ Juda. Iye wọn si li eyi: ọgbọn awo-pọ̀kọ wura, ẹgbẹrun awo-pọ̀kọ fadaka, ọbẹ mọkandilọgbọn, Ọgbọn ago wura, ago fadaka iru ekeji, irinwo o le mẹwa, ohun èlo miran si jẹ ẹgbẹrun.

Esr 1:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Pasia, kí àsọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, OLUWA fi sí Kirusi ọba lọ́kàn láti kéde yíká gbogbo ìjọba rẹ̀ ati láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé: “Èmi Kirusi, ọba Pasia kéde pé: OLUWA Ọlọrun ọ̀run ti fi gbogbo ìjọba ayé fún mi, ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda. Kí Ọlọrun wà pẹlu àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan rẹ̀. Ẹ lọ sí Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda, kí ẹ tún ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli kọ́, nítorí òun ni Ọlọrun tí wọn ń sìn ní Jerusalẹmu. Ní gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan rẹ̀ ń gbé, kí àwọn aládùúgbò wọn fi fadaka, wúrà, dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn ta wọ́n lọ́rẹ, yàtọ̀ sí ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọrun.” Àwọn olórí ninu ìdílé ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Bẹnjamini, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi sì dìde, pẹlu àwọn tí Ọlọrun ti fi sí lọ́kàn láti tún ilé OLUWA tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá. Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu. Kirusi ọba fún Mitiredati, akápò ìjọba rẹ̀ ní àṣẹ láti kó wọn síta, ó sì kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ṣeṣibasari, olórí ẹ̀yà Juda. Iye àwọn nǹkan náà nìyí: Ẹgbẹrun kan (1,000) àwo wúrà, ẹgbẹrun kan (1,000) àwo fadaka, àwo turari mọkandinlọgbọn; ọgbọ̀n àwokòtò wúrà, ẹgbaa ó lé irinwo ati mẹ́wàá (2,410) àwo fadaka kéékèèké, ẹgbẹrun (1,000) oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn.

Esr 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ OLúWA tí Jeremiah sọ ṣẹ, OLúWA ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé: “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé: “ ‘OLúWA, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili OLúWA fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili OLúWA Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu. Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ” Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Juda àti Benjamini àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé OLúWA ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá. Ní àfikún, ọba Kirusi mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé OLúWA jáde wá, tí Nebukadnessari ti kó lọ láti Jerusalẹmu tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀. Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda. Èyí ni iye wọn: Ọgbọ̀n àwo wúrà 30 Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà 1,000 Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n 29 Ọgbọ̀n àdému wúrà 30 Irínwó ó-lé-mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn 410 Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn 1,000