Esek 5:5-9
Esek 5:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni Jerusalemu: Emi ti gbe e kalẹ li ãrin awọn orilẹ-ède, ati awọn ilẹ ti o wà yi i ka kiri. O si ti pa idajọ mi dà si buburu ju awọn orilẹ-ède lọ, ati ilana mi ju ilẹ ti o yi i kakiri: nitori nwọn ti kọ̀ idajọ ati ilana mi, nwọn kò rìn ninu wọn. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Nitori ti ẹnyin ṣe ju awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri lọ, ti ẹnyin kò rìn ninu ilana mi, ti ẹ kò pa idajọ mi mọ, ti ẹ kò si ṣe gẹgẹ bi idajọ awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: kiye si i, Emi, ani Emi, doju kọ ọ, emi o si ṣe idajọ li ãrin rẹ li oju awọn orilẹ-ède. Emi o si ṣe ninu rẹ ohun ti emi kò ṣe ri, iru eyi ti emi kì yio si ṣe mọ, nitori gbogbo ohun irira rẹ.
Esek 5:5-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA Ọlọrun ní: “Jerusalẹmu nìyí. Mo ti fi í sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, mo sì ti fi àwọn agbègbè yí i ká. Ó ti tàpá sí òfin mi ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ, ó sì ti kọ ìlànà mi sílẹ̀ ju àwọn agbègbè tí ó yí i ká lọ. Wọ́n kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé rúdurùdu yín ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká lọ, ati pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká. Nítorí náà, èmi, OLUWA Ọlọrun fúnra mi, ni mo dójú le yín, n óo sì ṣe ìdájọ́ fun yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí gbogbo ìwà ìríra yín, n óo ṣe ohun tí n kò ṣe rí si yín, tí n kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́ lae.
Esek 5:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Èyí ní Jerusalẹmu, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká. Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, o kò sì pa ìlànà mi mọ́. “Nítorí náà, báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Nítorí pé ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká lọ, tí ẹ kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ túnṣe dáradára tó àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká. “Nítorí náà báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jerusalẹmu, èmi yóò sì jẹ ọ́ ní yà lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká. Nítorí gbogbo ohun ìríra rẹ, èmi yóò ṣe ohun tí n kò tí ì ṣe rí láàrín rẹ àti èyí tí n kò ní í ṣe irú rẹ̀ mọ́.