Esek 37:15-28

Esek 37:15-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọrọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, Ati iwọ, ọmọ enia, mu igi kan, si kọwe si i lara, Fun Juda, ati fun awọn ọmọ Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀: si mu igi miran, si kọwe si i lara, Fun Josefu, igi Efraimu, ati fun gbogbo ile Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀. Si dà wọn pọ̀ ṣọkan si igi kan; nwọn o si di ọkan li ọwọ́ rẹ. Nigbati awọn enia rẹ ba ba ọ sọ̀rọ, wipe, Iwọ kì yio fi idi nkan wọnyi hàn wa? Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu igi Josefu, ti o wà li ọwọ́ Efraimu, ati awọn ẹya Israeli ẹgbẹ́ rẹ̀, emi o si mu wọn pẹlu rẹ̀, pẹlu igi Juda, emi o si sọ wọn di igi kan, nwọn o si di ọkan li ọwọ́ mi. Igi ti iwọ kọwe si lara yio wà li ọwọ́ rẹ, niwaju wọn. Si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu awọn ọmọ Israeli kuro lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ, emi o si ṣà wọn jọ niha gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ti wọn. Emi o si sọ wọn di orilẹ-ède kan ni ilẹ lori oke-nla Israeli; ọba kan ni yio si jẹ lori gbogbo wọn: nwọn kì yio si jẹ orilẹ-ède meji mọ, bẹ̃ni a kì yio sọ wọn di ijọba meji mọ rara. Bẹ̃ni nwọn kì yio fi oriṣa wọn bà ara wọn jẹ mọ, tabi ohun-irira wọn, tabi ohun irekọja wọn: ṣugbọn emi o gbà wọn là kuro ninu gbogbo ibugbe wọn, nibiti nwọn ti dẹṣẹ, emi o si wẹ̀ wọn mọ́: bẹ̃ni nwọn o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn. Dafidi iranṣẹ mi yio si jẹ ọba lori wọn; gbogbo wọn ni yio si ni oluṣọ-agutan kan: nwọn o rìn ninu idajọ mi pẹlu, nwọn o si kiyesi aṣẹ mi, nwọn o si ṣe wọn. Nwọn o si ma gbe ilẹ ti emi ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi, nibiti awọn baba nyin ti gbe; nwọn o si ma gbe inu rẹ̀, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ ọmọ wọn lailai: Dafidi iranṣẹ mi yio si ma jẹ ọmọ-alade wọn lailai. Pẹlupẹlu emi o ba wọn dá majẹmu alafia; yio si jẹ majẹmu aiyeraiye pẹlu wọn: emi o si gbe wọn kalẹ, emi o si mu wọn rẹ̀, emi o si gbe ibi mimọ́ mi si ãrin wọn titi aiye. Agọ mi yio wà pẹlu wọn: nitõtọ, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi. Awọn keferi yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti sọ Israeli di mimọ́, nigbati ibi mimọ́ mi yio wà li ãrin wọn titi aiye.

Esek 37:15-28 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, mú igi kan kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Igi Juda ati àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ Mú igi mìíràn kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Ti Josẹfu, (igi Efuraimu) ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ Fi ẹnu wọn ko ara wọn, kí wọ́n di igi kan lọ́wọ́ rẹ. Bí àwọn eniyan rẹ bá bi ọ́ pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí ò ń ṣe yìí? Wí fún wọn pé èmi OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo mú igi Josẹfu ati àwọn ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, n óo fi ẹnu rẹ̀ ko ẹnu igi Juda; n óo sọ wọ́n di igi kan, wọn yóo sì di ọ̀kan lọ́wọ́ mi.’ “Mú àwọn igi tí o kọ nǹkan sí lára lọ́wọ́, lójú wọn, kí o sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ wò ó! N óo kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà, n óo kó wọn jọ láti ibi gbogbo wá sí ilẹ̀ wọn. N óo sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní orí òkè Israẹli, ọba kanṣoṣo ni yóo sì jẹ lé gbogbo wọn lórí. Wọn kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè meji mọ́; wọn kò ní pín ara wọn sí ìjọba meji mọ́. Wọn kò ní fi ìbọ̀rìṣà kankan, tabi ìwà ìríra kankan tabi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, sọ ara wọn di aláìmọ́ mọ́. N óo gbà wọ́n ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìfàsẹ́yìn tí wọ́n ti dá. N óo wẹ̀ wọ́n mọ́, wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn. Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo jọba lórí wọn; gbogbo wọn óo ní olùṣọ́ kan. Wọn óo máa pa òfin mi mọ́, wọn óo sì máa fi tọkàntọkàn rìn ní ìlànà mi. Wọn óo máa gbé ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín gbé. Àwọn ati àwọn ọmọ wọn ati àwọn ọmọ ọmọ wọn yóo máa gbé ibẹ̀ títí lae. Dafidi iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba wọn títí lae. N óo bá wọn dá majẹmu alaafia, tí yóo jẹ́ majẹmu ayérayé. N óo bukun wọn, n óo jẹ́ kí wọn pọ̀ sí i, n óo sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ sí ààrin wọn títí lae. N óo kọ́ ibùgbé mi sí ààrin wọn, n óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi. Àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ya Israẹli sọ́tọ̀, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà láàrin wọn títí lae.’ ”

Esek 37:15-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mi wá: “Ọmọ ènìyàn, mú igi pátákó kan kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti Juda àti ti Israẹli tí ó ní àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, kí ó mú igi pátákò mìíràn kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Igi tí Efraimu jẹ́ ti Josẹfu àti gbogbo ilé Israẹli tí ó ni àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ So wọ́n papọ̀ sí ara igi kan nítorí náà wọn yóò di ọ̀kan ní ọwọ́ rẹ. “Nígbà tí àwọn ara ìlú rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé ìwọ kò ní sọ ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa?’ Sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Èmi yóò gba igi Josẹfu—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Efraimu—àti ti ẹ̀yà Israẹli tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Juda, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.’ Gbé igi pátákó tí ó kọ nǹkan sí i sókè ní iwájú wọn, kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Israẹli jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ. Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn. Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Israẹli, ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì. Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. “ ‘Dafidi ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ ọba lórí wọn, gbogbo wọn yóò sì ní olùṣọ àgùntàn kan. Wọn yóò sì tẹ̀lé òfin mi, wọn yóò sì ṣe àníyàn láti pa àṣẹ mi mọ́. Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, ìránṣẹ́ mi Dafidi ni yóò jẹ́ Ọmọ-aládé wọn láéláé. Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, yóò sì jẹ́ májẹ̀mú títí ayérayé. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sì sọ wọ́n di púpọ̀ ní iye, èmi yóò sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ ní àárín wọn títí láé. Ibùgbé mí yóò wà pẹ̀lú wọn, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé, èmi OLúWA sọ Israẹli di mímọ́, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà ní àárín wọn títí ayérayé.’ ”