Esek 34:1-31

Esek 34:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oluṣọ́ agutan Israeli, sọtẹlẹ, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oluṣọ́ agutan; pe, Egbé ni fun awọn oluṣọ́ agutan Israeli, ti mbọ́ ara wọn, awọn oluṣọ́ agutan kì ba bọ́ ọwọ́-ẹran? Ẹnyin jẹ ọrá, ẹ si fi irun agutan bora, ẹ pa awọn ti o sanra: ẹ kò bọ́ agbo-ẹran. Ẹnyin kò mu alailera lara le, bẹ̃ni ẹ kò mu eyiti kò sàn li ara da, bẹ̃ni ẹ kò dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, bẹ̃ni ẹ kò tun mu eyi ti a ti lé lọ padà bọ̀, bẹ̃ni ẹ kò wá eyiti o sọnu, ṣugbọn ipá ati ìka li ẹ ti fi nṣe akoso wọn. A si tú wọn ka, nitori ti oluṣọ́ agutan kò si: nwọn si di onjẹ fun gbogbo ẹranko igbẹ́, nigbati a tú wọn ka. Awọn agutàn mi ṣako ni gbogbo òke, ati lori gbogbo òke kékèké, nitõtọ, a tú ọwọ́-ẹran mi ká ilẹ gbogbo, ẹnikẹni kò bere wọn ki o si wá wọn lọ. Nitorina ẹnyin oluṣọ́ agutan, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa. Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitõtọ, nitori ti ọwọ́-ẹran mi di ijẹ, ti ọwọ́-ẹran mi di onjẹ fun olukuluku ẹranko igbẹ́, nitoriti kò si oluṣọ́ agutan, bẹ̃ni awọn oluṣọ́ agutan kò wá ọwọ́-ẹran mi ri, ṣugbọn awọn oluṣọ́ agutan bọ́ ara wọn, nwọn kò si bọ́ ọwọ́-ẹran mi. Nitorina, ẹnyin oluṣọ́ agutan, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa; Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi dojukọ awọn oluṣọ́ agutan; emi o si bere ọwọ́-ẹ̀ran mi lọwọ wọn, emi o si mu wọn dẹ́kun ati ma bọ́ awọn ọwọ́-ẹran: bẹ̃ni awọn ọluṣọ́ agutan kì yio bọ́ ara wọn mọ, nitori ti emi o gbà ọwọ́-ẹran mi kuro li ẹnu wọn ki nwọn ki o má ba jẹ onjẹ fun wọn. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi, ani emi, o bere awọn agutan mi, emi o si wá wọn ri. Gẹgẹ bi oluṣọ́ agutan iti iwá ọwọ́-ẹran rẹ̀ ri, li ọjọ ti o wà lãrin awọn agutan rẹ̀ ti o fọnka, bẹ̃li emi o wá agutan mi ri, emi o si gbà wọn nibi gbogbo ti wọn ti fọnka si, li ọjọ kũkũ ati okùnkun biribiri. Emi o si mu wọn jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, emi o si kó wọn jọ lati ilẹ gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ara wọn, emi o si bọ́ wọn lori oke Israeli, lẹba odò, ati ni ibi gbigbé ni ilẹ na. Emi o bọ́ wọn ni pápa oko daradara ati lori okè giga Israeli ni agbo wọn o wà: nibẹ ni nwọn o dubulẹ ni agbo daradara, pápa oko ọlọ́ra ni nwọn o si ma jẹ lori oke Israeli. Emi o bọ́ ọwọ́-ẹran mi, emi o si mu ki nwọn dubulẹ, li Oluwa Ọlọrun wi. Emi o wá eyiti o sọnu lọ, emi o si mu eyiti a lé lọ pada bọ̀, emi o si dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, emi o mu eyiti o ṣaisan li ara le; ṣugbọn emi o run eyiti o sanra ati eyiti o lagbara; emi o fi idajọ bọ́ wọn. Bi o ṣe ti nyin, Ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i emi o ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran, lãrin àgbo ati obukọ. Ohun kekere ni li oju nyin ti ẹ ti jẹ oko daradara, ṣugbọn ẹnyin si fi ẹsẹ tẹ̀ oko iyokù mọlẹ, ati ti ẹ ti mu ninu omi jijìn, ṣugbọn ẹ si fi ẹsẹ ba eyi ti o kù jẹ? Bi o ṣe ti ọwọ́-ẹran mi ni, nwọn jẹ eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin tẹ̀ mọlẹ; nwọn si mu eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin bajẹ. Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun wọn, Kiyesi, emi, ani emi, o ṣe idajọ lãrin ọwọ́-ẹran ti o sanra, ati eyiti o rù. Nitoriti ẹnyin ti fi ẹgbẹ́ ati ejiká gbún, ti ẹ si ti fi iwo nyin kàn gbogbo awọn ti o li àrun titi ẹ fi tú wọn kakiri. Nitorina ni emi o ṣe gbà ọwọ́-ẹran mi là, nwọn kì yio si jẹ ijẹ́ mọ, emi o si ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran. Emi o si gbe oluṣọ́ agutan kan soke lori wọn, on o si bọ́ wọn, ani Dafidi iranṣẹ mi; on o bọ́ wọn, on o si jẹ oluṣọ́ agutan wọn. Emi Oluwa yio si jẹ Ọlọrun wọn, ati Dafidi iranṣẹ mi o jẹ ọmọ-alade li ãrin wọn, emi Oluwa li o ti sọ ọ. Emi o si ba wọn da majẹmu alafia, emi o si jẹ ki awọn ẹranko buburu dasẹ ni ilẹ na: nwọn o si ma gbe aginju li ailewu, nwọn o si sùn ninu igbó. Emi o si ṣe awọn ati ibi ti o yi oke mi ká ni ibukún; emi o si jẹ ki ojò ki o rọ̀ li akoko rẹ̀, òjo ibukún yio wà. Igi igbẹ́ yio si so eso rẹ̀, ilẹ yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá, nwọn o si wà li alafia ni ilẹ wọn, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ti ṣẹ́ èdídi àjaga wọn, ti emi o si ti gbà wọn lọwọ awọn ti nwọn nsìn bi ẹrú. Nwọn kì yio si ṣe ijẹ fun awọn keferi mọ, bẹ̃ni ẹranko ilẹ na kì yio pa wọn jẹ, ṣugbọn nwọn o wà li alafia ẹnikẹni kì yio si dẹrùba wọn, Emi o si gbe igi okiki kan soke fun wọn, ebi kì yio si run wọn ni ilẹ na mọ, bẹ̃ni nwọn kì yio rù itiju awọn keferi mọ. Bayi ni nwọn o mọ̀ pe emi Oluwa Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn, ati awọn, ile Israeli, jẹ enia mi, li Oluwa Ọlọrun wi. Ati ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, ọwọ́-ẹran pápa oko mi ni enia, emi si li Ọlọrun nyin, li Oluwa Ọlọrun wi.

Esek 34:1-31 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o fi bá àwọn olùṣọ́-aguntan Israẹli wí, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn olórí Israẹli wí pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Háà, ẹ̀yin olórí Israẹli tí ẹ̀ ń wá oúnjẹ fún ara yín, ṣé kò yẹ kí olùṣọ́-aguntan máa pèsè oúnjẹ fún àwọn aguntan rẹ̀? Ẹ̀yin ń jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ̀ ń fi irun aguntan bo ara yín, ẹ̀ ń pa aguntan tí ó sanra jẹ; ṣugbọn ẹ kò fún àwọn aguntan ní oúnjẹ. Ẹ kò tọ́jú àwọn tí wọn kò lágbára, ẹ kò tọ́jú àwọn tí ń ṣàìsàn, ẹ kò tọ́jú ẹsẹ̀ àwọn tí wọn dá lẹ́sẹ̀, ẹ kò mú àwọn tí wọn ń ṣáko lọ pada wálé; ẹ kò sì wá àwọn tí wọ́n sọnù. Pẹlu ipá ati ọwọ́-líle ni ẹ fi ń ṣe àkóso wọn. Nítorí náà, wọ́n túká nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́, wọ́n sì di ìjẹ fún àwọn ẹranko burúkú. Àwọn aguntan mi túká, wọ́n ń káàkiri lórí gbogbo òkè ńlá ati gbogbo òkè kéékèèké. Àwọn aguntan mi fọ́n káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹni tí ó bèèrè wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó wá wọn.’ “Nítorí náà, ẹ̀yin, olùṣọ́-aguntan, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí. OLUWA Ọlọrun fi ara rẹ̀ búra ó ní, ‘Àwọn aguntan mi di ìjẹ, fún gbogbo ẹranko nítorí pé wọn kò ní olùṣọ́; nítorí pé àwọn tí ń ṣọ́ wọn kò wá wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ oúnjẹ ni wọ́n ń wá sẹ́nu ara wọn, wọn kò bọ́ àwọn aguntan mi.’ Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan: ‘Mo lòdì sí ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, n óo sì bèèrè àwọn aguntan mi lọ́wọ́ yín. N óo da yín dúró lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́-aguntan, ẹ kò sì ní rí ààyè bọ́ ara yín mọ́. N óo gba àwọn aguntan mi lẹ́nu yín, ẹ kò sì ní rí wọn pa jẹ mọ́.’ ” OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Èmi fúnra mi ni n óo wá àwọn aguntan mi, àwárí ni n óo sì wá wọn. Bí olùṣọ́-aguntan tií wá àwọn aguntan rẹ̀ tí ó bá jẹ lọ, bẹ́ẹ̀ ni n óo wá àwọn aguntan mi, n óo sì yọ wọ́n kúrò ninu gbogbo ibi tí wọ́n fọ́nká sí ní ọjọ́ tí ìkùukùu bo ilẹ̀, tí òkùnkùn sì ṣú. N óo mú wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ tiwọn. N óo máa bọ́ wọn lórí àwọn òkè Israẹli, lẹ́bàá orísun omi ati gbogbo ibi tí àwọn eniyan ń gbé ní Israẹli. N óo fún wọn ní koríko tí ó dára jẹ, orí òkè Israẹli sì ni wọn óo ti máa jẹ koríko. Níbẹ̀, ninu pápá oko tí ó dára ni wọn óo dùbúlẹ̀ sí; ninu pápá oko tútù, wọn yóo sì máa jẹ lórí àwọn òkè Israẹli. Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ olùṣọ́ àwọn aguntan mi, n óo sì mú wọn dùbúlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ. “N óo wá àwọn tí ó sọnù, n óo sì mú àwọn tí wọ́n ṣáko lọ pada, n óo tọ́jú ọgbẹ́ àwọn tí wọ́n farapa, n óo fún àwọn tí kò lókun lágbára, ṣugbọn àwọn tí wọ́n sanra ati àwọn tí wọ́n lágbára ni n óo parun, nítorí òtítọ́ inú ni n óo fi ṣọ́ àwọn aguntan mi. “Ní tiyín, ẹ̀yin agbo ẹran mi, èmi OLUWA Ọlọrun ni n óo ṣe ìdájọ́ láàrin aguntan kan ati aguntan keji, ati láàrin àgbò ati òbúkọ. Ṣé kí ẹ máa jẹ oko ninu pápá dáradára kò to yín ni ẹ ṣe ń fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù yín mọ́lẹ̀? Ṣé kí ẹ mu ninu omi tí ó tòrò kò to yín ni ẹ ṣe fẹsẹ̀ da omi yòókù rú? Ṣé àjẹkù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn aguntan tèmi máa jẹ; omi àmukù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ dàrú sì ni ó yẹ kí wọn máa mu? “Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun, ń sọ fun yín ni pé: mo ṣetán tí n óo ṣe ìdájọ́ fún àwọn aguntan tí ó sanra ati àwọn aguntan tí kò lókun ninu. Nítorí pé ẹ̀ ń fi ẹ̀gbẹ́ ti àwọn tí wọn kò lágbára sọnù, ẹ sì ń kàn wọ́n níwo títí tí ẹ fi tú wọn ká. N óo gba àwọn aguntan mi sílẹ̀, wọn kò ní jẹ́ ìjẹ mọ́, n óo sì ṣe ìdájọ́ láàrin aguntan kan ati aguntan keji. Olùṣọ́ kanṣoṣo ni n óo yàn fún wọn, òun náà sì ni Dafidi, iranṣẹ mi. Yóo máa bọ́ wọn, yóo sì máa ṣe olùṣọ́ wọn. Èmi OLUWA ni n óo jẹ́ Ọlọrun wọn; Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba láàrin wọn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo bá wọn dá majẹmu alaafia; n óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, wọn yóo máa gbé inú aṣálẹ̀ ati inú igbó láìléwu. “N óo bukun àwọn, ati gbogbo agbègbè òkè mi. N óo máa jẹ́ kí òjò máa rọ̀ lásìkò wọn, òjò ibukun ni yóo sì máa jẹ́. Igi inú oko yóo máa so; ilẹ̀ yóo sì máa mú ọpọlọpọ irúgbìn jáde. Àwọn eniyan óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà wọn, tí mo bá sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú. Wọn kò ní jẹ́ ìjẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko ilẹ̀ yìí kò ní pa wọ́n jẹ mọ́. Wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, ẹnìkan kan kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́. N óo fún wọn ní ọpọlọpọ nǹkan kórè ninu ohun tí wọ́n bá gbìn, ìyàn kò ní run wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ náà, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò sì ní fi wọ́n ṣẹ̀sín mọ́. Wọn óo mọ̀ pé èmi, OLUWA Ọlọrun wọn, wà pẹlu wọn, ati pé àwọn ọmọ Israẹli sì ni eniyan mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Ẹ̀yin aguntan mi, aguntan pápá mi, ẹ̀yin ni eniyan mi; èmi sì ni Ọlọrun yín.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.

Esek 34:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀rọ̀ OLúWA tọ́ mi wá: “Ọmọ ènìyàn, fi àsọtẹ́lẹ̀ tako olùṣọ́-àgùntàn Israẹli; sọtẹ́lẹ̀ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn Israẹli tí ó ń tọ́jú ara wọn nìkan! Ṣé ó dára kí olùṣọ́-àgùntàn ṣaláì tọ́jú agbo ẹran? Ìwọ jẹ wàrà. O sì wọ aṣọ olówùú sí ara rẹ, o sì ń pa ẹran tí ó wù ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò tọ́jú agbo ẹran. Ìwọ kò ì tí ì mú aláìlágbára lára le tàbí wo aláìsàn sàn tàbí di ọgbẹ́ fún ẹni tí o fi ara pa. Ìwọ kò í tí ì mú aṣáko padà tàbí wá ẹni tí ó nù. Ìwọ ṣe àkóso wọn ní ọ̀nà lílé pẹ̀lú ìwà òǹrorò. Nítorí náà wọn fọ́n káàkiri nítorí àìsí olùṣọ́-àgùntàn, nígbà tí wọ́n fọ́nká tán wọn di ìjẹ fún gbogbo ẹranko búburú. Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn. “ ‘Nítorí náà, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA: Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè ní OLúWA Olódùmarè wí, nítorí pé agbo ẹran mi kò ní olùṣọ́-àgùntàn nítorí tí a kọ̀ wọ́n, tì wọ́n sì di ìjẹ fún ẹranko búburú gbogbo àti pé, nítorí tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn mi kò ṣe àwárí agbo ẹran mi, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe ìtọ́jú ara wọn dípò ìtọ́jú agbo ẹran mi, nítorí náà, ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA: Èyí yìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìlòdì sí àwọn olùṣọ́-àgùntàn, èmi yóò sì béèrè agbo ẹran mi lọ́wọ́ wọn. Èmi yóò sì mú wọn dẹ́kun àti máa darí agbo ẹran mi, tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà kò sì ní lè bọ́ ara wọn mọ́. Èmi yóò gba agbo ẹran mi kúrò ni ẹnu wọn, kì yóò sì jẹ́ oúnjẹ fún wọn mọ́. “ ‘Nítorí èyí ni OLúWA Olódùmarè wí: Èmi fúnra mi yóò wá àgùntàn mi kiri, èmi yóò sì ṣe àwárí wọn. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe fojú tó agbo ẹran rẹ̀ tí ó fọ́nká nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe fojú tó àgùntàn mi. Èmi yóò gbá wọn kúrò ni gbogbo ibi tí wọ́n fọ́nká sí ni ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn. Èmi yóò mú wọn jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì kó wọn jọ láti inú àwọn ìlú, èmi yóò sì mú wọn wá sí ilẹ̀ ara wọn. Èmi yóò mú wọn jẹ ni orí àwọn òkè gíga Israẹli, ni àárín àwọn òkè àti ní gbogbo ibùdó ilẹ̀ náà. Èmi yóò ṣe ìtọ́jú wọn ní pápá oko tútù dáradára, àní orí àwọn òkè gíga ti Israẹli ni yóò jẹ́ ilẹ̀ ìjẹ koríko wọ́n. Níbẹ̀ wọn yóò dùbúlẹ̀ ní ilẹ̀ ìjẹ koríko dídára, níbẹ̀ wọn yóò jẹun ní pápá oko tútù tí ó dara ní orí òkè ti Israẹli. Èmi fúnra mi yóò darí àgùntàn mi, èmi yóò mú wọn dùbúlẹ̀, ni OLúWA Olódùmarè wí. Èmi yóò ṣe àwárí àwọn tí ó nú, èmi yóò mú àwọn tí ó ń rin ìrìn àrè kiri padà. Èmi yóò di ọgbẹ́ àwọn tí ó fi ara pa, èmi yóò sì fún àwọn aláìlágbára ni okun, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra tí ó sì ni agbára ní èmi yóò parun. Èmi yóò ṣe olùṣọ́ àwọn agbo ẹran náà pẹ̀lú òdodo. “ ‘Ní tìrẹ, agbo ẹran mi, èyí yìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn kan àti òmíràn, àti láàrín àgbò àti ewúrẹ́. Ṣé oúnjẹ jíjẹ ní pápá oko tútù dídára kò tó yín! Ṣé ó jẹ́ dandan fún ọ láti fi ẹsẹ̀ tẹ pápá oko tútù rẹ tí ó kù? Ṣé omi tí ó tòrò kò tó fún yín ní mímu? Ṣe dandan ni kí ó fi ẹrẹ̀ yí ẹsẹ̀ yín? Ṣé dandan ni kí agbo ẹran mi jẹ́ koríko tí ẹ ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọn sì mú omi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn sọ di ẹrẹ̀? “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ni OLúWA Olódùmarè wí fún wọn: Wò ó, èmi fúnra mi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn tí ó sanra àti èyí tí ó rù. Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ, Èmi yóò gba agbo ẹran mi là, a kì yóò sì kò wọ́n tì mọ́. Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrín àgùntàn kan àti òmíràn. Èmi yóò fi olùṣọ́-àgùntàn kan ṣe olórí wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi, òun yóò sì tọ́jú wọn; Òun yóò bọ́ wọn yóò sì jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn wọn. Èmi OLúWA yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ìránṣẹ́ mi Dafidi yóò jẹ́ ọmọ-aládé láàrín wọn. Èmi OLúWA ní o sọ̀rọ̀. “ ‘Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, èmi yóò sì gba ilẹ̀ náà kúrò lọ́wọ́ ẹranko búburú, kí wọn kí o lè gbé ní aṣálẹ̀, kí àgùntàn sì gbé ní inú igbó ní àìléwu. Èmi yóò bùkún wọn àti ibi agbègbè ti ó yí òkè mi ká. Èmi yóò rán ọ̀wààrà òjò ni àkókò; òjò ìbùkún yóò sì wà. Àwọn igi igbó yóò mú èso wọn jáde, ilẹ̀ yóò sì mu irúgbìn jáde; A yóò sì dá ààbò bo àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ náà. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLúWA, nígbà tí mo bá já àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà àjàgà, tí mo sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó fi wọ́n ṣe ẹrú. Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò lè kó wọn ní ẹrú mọ́, àwọn ẹranko búburú kì yóò lè pa wọn mọ́. Wọn yóò gbé ni àìléwu, kò sì ṣí ẹni kankan tí yóò le dẹ́rùbà wọ́n. Èmi yóò pèsè ilẹ̀ ti o ní oríyìn fún èso rẹ̀ fún wọn, wọn kì yóò sì jìyà nípasẹ̀ ìyàn mọ́ ni ilẹ̀ náà tàbí ru ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni OLúWA Ọlọ́run wọn, èmi wà pẹ̀lú wọn àti pé, àwọn ilé Israẹli jẹ́ ènìyàn mi, ni OLúWA Olódùmarè wí. Ìwọ àgùntàn mi, àgùntàn pápá mi; ni ènìyàn, èmi sì ni Ọlọ́run rẹ; ni OLúWA Olódùmarè wí.’ ”