Esek 3:7-9
Esek 3:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ile Israeli kò ni gbọ́ tirẹ; nitori ti nwọn kò fẹ gbọ́ ti emi: nitori alafojudi ati ọlọkàn lile ni gbogbo ile Israeli. Kiyesi i, mo ti sọ oju rẹ di lile si oju wọn, ati iwaju rẹ di lile si iwaju wọn. Bi okuta diamondi ti o le ju okuta ibọn ni mo ṣe iwaju rẹ: máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe fòya oju wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọ̀tẹ ile.
Esek 3:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò ní gbọ́ tìrẹ, nítorí pé wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Olóríkunkun ati ọlọ́kàn líle ni gbogbo wọn. Mo ti mú kí ojú rẹ le sí tiwọn. Bí òkúta adamanti ṣe le ju òkúta akọ lọ ni mo ṣe mú kí orí rẹ le ju orí wọn lọ. Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí ojú wọn já ọ láyà, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”
Esek 3:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ilé Israẹli kò fẹ́ gbọ́ tìrẹ nítorí pé wọn kò fẹ́ láti gbọ́ tèmi, torí pé aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Israẹli. Ṣùgbọ́n bí i tiwọn lèmi náà yóò ṣe jẹ́ kí ojú àti ọkàn rẹ le. Èmi yóò ṣe iwájú orí rẹ bí òkúta tó le jùlọ, ànító le ju òkúta-ìbọn lọ. Má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí jẹ́ kí wọn ó dáyà já ọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”