Esek 3:18-19
Esek 3:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati emi wi fun enia buburu pe, Iwọ o kú nitõtọ; ti iwọ kò si kilọ̀ fun u, ti iwọ kò sọ̀rọ lati kilọ fun enia buburu, lati kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, lati gba ẹmi rẹ̀ là; enia buburu na yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ. Ṣugbọn bi iwọ ba kilọ̀ fun enia buburu, ti kò si kuro ninu buburu rẹ̀, ti ko yipada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ṣugbọn ọrun rẹ mọ́.
Esek 3:18-19 Yoruba Bible (YCE)
Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúdájú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú, tí kò bá yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú tí ó ń ṣe, tabi ọ̀nà ibi tí ó ń tọ̀; yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ óo gba ara rẹ là.
Esek 3:18-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, dájúdájú, ‘Ìwọ yóò kú,’ tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ènìyàn búburú yìí láti dáwọ́ ìwà ibi rẹ̀ dúró, kí o sì gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún ènìyàn búburú, tí ó kọ̀ tí kò fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n ọrùn tìrẹ ti mọ́.