Esek 3:18
Esek 3:18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati emi wi fun enia buburu pe, Iwọ o kú nitõtọ; ti iwọ kò si kilọ̀ fun u, ti iwọ kò sọ̀rọ lati kilọ fun enia buburu, lati kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, lati gba ẹmi rẹ̀ là; enia buburu na yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.
Esek 3:18 Yoruba Bible (YCE)
Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúdájú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
Esek 3:18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, dájúdájú, ‘Ìwọ yóò kú,’ tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ènìyàn búburú yìí láti dáwọ́ ìwà ibi rẹ̀ dúró, kí o sì gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.