Esek 3:12-27

Esek 3:12-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹmi si gbe mi soke, mo si gbọ́ ohùn iró nla lẹhin mi, nwipe, Ibukun ni fun ogo Oluwa lati ipò rẹ̀ wá. Mo si gbọ́ ariwo iyẹ́ awọn ẹ̀da alãye, ti o kàn ara wọn, ati ariwo awọn kẹkẹ́ ti o wà pẹlu wọn, ati ariwo iró nla. Bẹ̃ni ẹmi na gbe mi soke, o si mu mi kuro, mo si lọ ni ibinujẹ, ati ninu gbigbona ọkàn mi; ṣugbọn ọwọ́ Oluwa le lara mi. Nigbana ni mo tọ̀ awọn ti igbekùn ti Telabibi lọ, ti nwọn ngbe ẹba odò Kebari, mo si joko nibiti nwọn joko, ẹnu si yà mi bi mo ti wà lãrin wọn ni ijọ meje. O si di igbati o ṣe li opin ijọ meje, ọ̀rọ Oluwa wá sọdọ mi, wipe: Ọmọ enia, mo ti fi iwọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli, nitorina gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, si kilọ fun wọn lati ọdọ mi wá. Nigbati emi wi fun enia buburu pe, Iwọ o kú nitõtọ; ti iwọ kò si kilọ̀ fun u, ti iwọ kò sọ̀rọ lati kilọ fun enia buburu, lati kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, lati gba ẹmi rẹ̀ là; enia buburu na yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ. Ṣugbọn bi iwọ ba kilọ̀ fun enia buburu, ti kò si kuro ninu buburu rẹ̀, ti ko yipada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ṣugbọn ọrun rẹ mọ́. Ẹ̀wẹ, nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si da ẹ̀ṣẹ, ti mo si fi ohun idigbolu siwaju rẹ, yio kú; nitoriti iwọ kò kilọ fun u, yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, a ki yio ranti ododo rẹ̀ ti o ti ṣe; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ. Ṣugbọn bi iwọ ba kilọ fun olododo, ki olododo ki o má dẹ̀ṣẹ, ti on kò si ṣẹ̀, yio yè nitotọ, nitori ti a kilọ fun u, ọrùn rẹ si mọ́. Ọwọ́ Oluwa si wà lara mi nibẹ; o si wi fun mi pe, Dide, lọ si pẹtẹlẹ, emi o si ba ọ sọ̀rọ nibẹ. Mo si dide, mo si lọ si pẹtẹlẹ, si kiyesi i ogo Oluwa duro nibẹ, bi ogo ti mo ri lẹba odò Kebari: mo si doju mi bolẹ. Ẹmi si wọ̀ inu mi lọ, o si gbe mi duro li ẹsẹ mi, o si ba mi sọ̀rọ, o si sọ fun mi pe, Lọ, há ara rẹ mọ ile rẹ. Ṣugbọn iwọ, ọmọ enia, kiyesi i, nwọn o si fi idè le ọ, nwọn o si fi dè ọ, iwọ ki yio si jade larin wọn. Emi o si mu ahọn rẹ lẹ mọ oke ẹnu rẹ, iwọ o si yadi, iwọ ki yio jẹ abaniwi si wọn; nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn. Ṣugbọn nigbati mo ba bá ọ sọ̀rọ, emi o ya ẹnu rẹ, iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹniti o gbọ́, jẹ ki o gbọ́; ẹniti o kọ̀, jẹ ki o kọ̀ nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.

Esek 3:12-27 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, mo sì gbọ́ ìró kan lẹ́yìn mi tí ó dàbí ariwo ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá, ó ní, “Ẹ fi ìyìn fún ìfarahàn ògo OLUWA ní ibùgbé rẹ̀.” Ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà ni mò ń gbọ́ tí wọn ń kan ara wọn, ati ìró àgbá wọn; ó dàbí ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá. Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, ó sì gbé mi lọ. Tìbínú-tìbínú ni mo sì fi ń lọ. Ẹ̀mí OLUWA ni ó gbé mi lọ pẹlu agbára. Mo bá dé Teli Abibu lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn tí wọn ń gbé ẹ̀bá odò Kebari. Ọjọ́ meje ni mo fi wà pẹlu wọn, tí mo jókòó tì wọ́n, tí mò ń wò wọ́n tìyanu-tìyanu. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọmọ eniyan, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli. Nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ohunkohun lẹ́nu mi, o gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn. Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúdájú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú, tí kò bá yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú tí ó ń ṣe, tabi ọ̀nà ibi tí ó ń tọ̀; yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ óo gba ara rẹ là. “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni bí olódodo bá yipada kúrò ninu òdodo rẹ̀, tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, tí mo sì gbé ohun ìkọsẹ̀ kan siwaju rẹ̀, yóo kú, nítorí pé o kò kìlọ̀ fún un, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a kò sì ní ranti iṣẹ́ òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe; ṣugbọn n óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún olódodo náà pé kí ó má dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè, nítorí pé ó gbọ́ ìkìlọ̀; ìwọ náà yóo sì gba ẹ̀mí ara rẹ là.” Ẹ̀mí OLUWA sì wà lára mi, ó sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí àfonífojì, níbẹ̀ ni n óo ti bá ọ sọ̀rọ̀.” Mo bá dìde, mo jáde lọ sí àfonífojì. Mo rí ìfarahàn ògo OLUWA níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí i lẹ́bàá odò Kebari, mo bá dojúbolẹ̀. Ṣugbọn ẹ̀mí Ọlọrun kó sí mi ninu, ó sì gbé mi nàró; ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé, “Lọ ti ara rẹ mọ́ ilé rẹ. Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! A óo na okùn lé ọ lórí, a óo sì fi okùn náà dè ọ́, kí o má baà lè jáde sí ààrin àwọn eniyan. N óo mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ ọ lẹ́nu kí o sì ya odi, kí o má baà lè kìlọ̀ fún wọn, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn. Ṣugbọn bí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ tán, n óo là ọ́ lóhùn, o óo sì sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun bá sọ fún wọn. Ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó gbọ́, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó má gbọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.”

Esek 3:12-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Ẹ̀mí gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ohùn ìró ńlá lẹ́yìn mi tó sọ pé, kí a gbé ògo OLúWA ga láti ibùgbé rẹ̀ wá! Bẹ́ẹ̀ ni mo tún gbọ́ ariwo ìyẹ́ apá àti kẹ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà pẹ̀lú ariwo tó dàbí àrá ńlá. Ẹ̀mí náà sì gbé mi sókè, ó sì mú mi lọ, mo lọ pẹ̀lú ọkàn kíkorò àti ìbínú nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ọwọ́ líle OLúWA ni ara mi. Nígbà náà ni mo lọ sí etí odò Kebari níbi tí àwọn ìgbèkùn ń gbé ni Teli-Abibu. Níbẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé, mo jókòó láàrín wọn pẹ̀lú ìyanu, fún ọjọ́ méje. Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, fún wọn ní ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi. Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, dájúdájú, ‘Ìwọ yóò kú,’ tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ènìyàn búburú yìí láti dáwọ́ ìwà ibi rẹ̀ dúró, kí o sì gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún ènìyàn búburú, tí ó kọ̀ tí kò fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n ọrùn tìrẹ ti mọ́. “Bákan náà, bí olódodo kan bá yípadà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àìṣòdodo, tí mo sì fi ohun ìkọ̀sẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Nítorí pé ìwọ kọ̀ láti kìlọ̀ fún un, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a ó gbàgbé gbogbo ìwà rere tó ti hù tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún olódodo tó sì dáwọ́ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ dúró, dájúdájú òun yóò yè nítorí pé ó ti gba ìkìlọ̀, ọrùn tìrẹ sì mọ́.” Ọwọ́ OLúWA wà lára mi níbẹ̀, ó sì wí fún mi pé, “Dìde, lọ sí ibi tí ó tẹ́jú, èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀.” Mo sì dìde, mo lọ sí ibi tí ó tẹ́jú. Ògo OLúWA dúró níbẹ̀, ó dàbí irú ògo tí mo rí létí odò Kebari, mo sì dojúbolẹ̀. Nígbà náà ni Ẹ̀mí wọ inú mi, tí ó sì tún gbé mi dúró. Ó sì wí fún mi pé: “Lọ, ti ara rẹ mọ́ inú ilé rẹ ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, wọn yóò fi okùn dè ọ́ mọ́lẹ̀; dé ibi pé ìwọ kò ní í le rìn káàkiri láàrín àwọn ènìyàn. Èmi yóò mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ àjà ẹnu rẹ, tó bẹ́ẹ̀ ti ìwọ yóò wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Ìwọ kò sì ní lè bá wọn wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ní wọn Ṣùgbọ́n nígbà tí èmi bá bá ọ sọ̀rọ̀, Èmi yóò ṣí ọ lẹ́nu, ìwọ yóò sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí.’ Ẹni tó bá fẹ́ kí ó gbọ́, ẹni tó bá fẹ́ kọ̀, kó kọ̀ nítorí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.