Esek 22:30-31
Esek 22:30-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi si wá ẹnikan lãrin wọn, ti ibá tun odi na mọ, ti ibá duro ni ibiti o ya na niwaju mi fun ilẹ na, ki emi má bà parun: ṣugbọn emi kò ri ẹnikan. Nitorina ni mo ṣe dà ibinu mi si wọn lori; mo ti fi iná ibinu mi run wọn: mo si ti fi ọ̀na wọn gbẹsan lori ara wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.
Esek 22:30-31 Yoruba Bible (YCE)
Mo wá ẹnìkan láàrin wọn tí ìbá tún odi náà mọ, kí ó sì dúró níbi tí odi ti ya níwájú mi láti bẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, kí n má baà pa á run, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan. Nítorí náà, n óo bínú sí wọn; n óo fi ìrúnú pa wọ́n rẹ́, n óo sì gbẹ̀san ìwà wọn lára wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Esek 22:30-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi si wá ẹnìkan láàrín wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má bá à parun: ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan. Nítorí náà ni mo ṣe da ìbínú mi sí wọn lórí, mo ti fi iná ìbínú mi run wọn, mo si ti fi ọ̀nà wọn gbẹ̀san lórí ara wọn, ní OLúWA Olódùmarè wí.”