Esek 20:21-23
Esek 20:21-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awọn ọmọ na ṣọ̀tẹ si mi: nwọn kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni nwọn kò pa idajọ mi mọ lati ṣe wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn; nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: mo si wipe, Emi o da irúnu mi sori wọn, lati pari ibinu mi sori wọn li aginju. Ṣugbọn mo fà ọwọ́ mi sẹhìn, mo si ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má bà di ibajẹ li oju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade. Mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn pẹlu li aginju, lati tú wọn ka lãrin awọn keferi, ati lati fọ́n wọn ká ilẹ gbogbo
Esek 20:21-23 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀. Ṣugbọn mo rowọ́, mo sì ro ti orúkọ mi, tí n kò fẹ́ kí wọ́n bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde. Nítorí náà, mo ṣe ìlérí fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n óo fọ́n wọn káàkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù
Esek 20:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mi mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú mi lórí wọn, Èmi yóò sì mú kí ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni aginjù. Síbẹ̀síbẹ̀ mo dáwọ́ dúró, nítorí orúkọ mi, mo sì ṣe ohun tí kò ní ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè ti mo kó wọn jáde lójú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú ọwọ́ ti mo gbé sókè sí wọn, mo búra fún wọn nínú aginjù pé èmi yóò tú wọn ka sì àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ gbogbo