Esek 17:22-23
Esek 17:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ninu ẹka ti o ga jùlọ, ninu igi Kedari giga; emi o si lọ́ ọ, emi o ke ọ̀munú ẹka kan kuro ninu ọ̀munú ẹka rẹ̀; emi o si gbìn i sori oke giga kan ti o si hàn: Lori oke giga ti Israeli ni emi o gbìn i si, yio si yọ ẹka; yio si so eso, yio si jẹ igi Kedari daradara; labẹ rẹ̀ ni gbogbo ẹiyẹ oniruru iyẹ́ o si gbe; ninu ojiji ẹka rẹ̀ ni nwọn o gbe.
Esek 17:22-23 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA Ọlọrun ní: “Èmi fúnra mi ni n óo mú ọ̀kan ninu ẹ̀ka kan ní ṣóńṣó igi Kedari gíga, n óo ṣẹ́ ẹ̀ka kan láti orí rẹ̀, n óo gbìn ín sí orí òkè gíga fíofío. Lórí òkè gíga Israẹli ni n óo gbìn ín sí, kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so, kí ó sì di igi Kedari ńlá. Oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́ ni yóo máa gbé abẹ́ rẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóo pa ìtẹ́ sí abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀.
Esek 17:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Báyìí ní OLúWA Olódùmarè wí: Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lórí igi Kedari gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí. Ní ibi gíga òkè Israẹli ni èmi yóò gbìn ín sí; yóò pẹ̀ka, yóò sì so èso, yóò wa di igi Kedari tí ó lọ́lá. Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóò sì fi òjìji abẹ ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé; wọn yóò ṣe ibùgbé si abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀