Esek 17:11-21

Esek 17:11-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Sọ nisisiyi fun ọlọ̀tẹ ile na pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohun ti nkan wọnyi jasi? Sọ fun wọn, kiyesi i, ọba Babiloni de Jerusalemu, o si ti mu ọba ibẹ ati awọn ọmọ-alade ibẹ, o si mu wọn pẹlu rẹ̀ lọ si Babiloni: O si ti mu ninu iru-ọmọ ọba, o si bá a dá majẹmu, o si ti mu u bura: o si mu awọn alagbara ilẹ na pẹlu: Ki ijọba na le jẹ alailọla, ki o má le gbe ara rẹ̀ soke, ki o le duro nipa pipa majẹmu rẹ̀ mọ. Ṣugbọn on ṣọ̀tẹ si i ni rirán awọn ikọ̀ rẹ̀ lọ si Egipti, ki nwọn ki o le fi ẹṣin fun u ati enia pupọ. Yio ha sàn a? ẹniti nṣe iru nkan wọnyi yio ha bọ́? tabi yio dalẹ tan ki o si bọ́? Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nitotọ ibi ti ọba ngbe ti o fi i jọba, ibura ẹniti o gàn, majẹmu ẹniti o si bajẹ, ani lọdọ rẹ̀ lãrin Babiloni ni yio kú. Bẹ̃ni Farao ti on ti ogun rẹ̀ ti o li agbara ati ẹgbẹ́ nla kì yio ṣe fun u ninu ogun, nipa mimọ odi, ati kikọle iṣọ́ ti o li agbara, lati ke enia pupọ̀ kuro: Nitoriti o gàn ibura nipa didalẹ, kiye si i, o ti fi ọwọ́ rẹ̀ fun ni, o si ti ṣe gbogbo nkan wọnyi, kì yio bọ́. Nitorina bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi mo ti wà, dajudaju ibura mi ti o ti gàn, ati majẹmu mi ti o ti dà, ani on li emi o san si ori on tikalarẹ̀. Emi o si nà àwọn mi si i lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi; emi o si mu u de Babiloni, emi o si ba a rojọ nibẹ, nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti da si mi. Ati gbogbo awọn isánsa rẹ̀ pẹlu gbogbo awọn ẹgbẹ́-ogun rẹ̀, ni yio ti oju idà ṣubu; awọn ti o si kù ni a o tuka si gbogbo ẹfũfu: ẹnyin o si mọ̀ pe emi Oluwa li o ti sọ ọ.

Esek 17:11-21 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Bi àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi pé, ṣé wọn kò mọ ìtumọ̀ òwe wọnyi ni? Sọ pé ọba Babiloni wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Babiloni. Ó mú ọ̀kan ninu àwọn ìdílé ọba, ó bá a dá majẹmu, ó sì mú kí ó búra. Ó ti kọ́ kó gbogbo àwọn eniyan pataki pataki ilẹ̀ náà lọ, kí ilẹ̀ náà lè di ìrẹ̀sílẹ̀, kí wọ́n má sì lè gbérí mọ́, ṣugbọn kí ilẹ̀ náà lè máa ní ìtẹ̀síwájú, níwọ̀n ìgbà tí ó bá pa majẹmu ọba Babiloni mọ́. Ṣugbọn ọba Juda ṣọ̀tẹ̀ sí ti Babiloni, ó rán ikọ̀ lọ sí Ijipti pé kí wọ́n fún òun ní ẹṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun. Ǹjẹ́ yóo ní àṣeyọrí? Ṣé ẹni tí ń ṣé irú èyí lè bọ́? Ṣé ó lè yẹ majẹmu náà kí ó sì bọ́ ninu rẹ̀? “Èmi OLUWA fi ara mi búra pé, ní ilẹ̀ Babiloni, ní ilẹ̀ ọba tí ó fi í sórí oyè ọba tí kò náání, tí ó sì da majẹmu rẹ̀, níbẹ̀ ni yóo kú sí. Farao, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati ọpọlọpọ eniyan rẹ̀, kò ní lè ràn án lọ́wọ́ nígbà ogun; nígbà tí ogun bá dótì í, tí wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ láti pa ọpọlọpọ eniyan. Kò ní sá àsálà, nítorí pé kò náání ìbúra ó sì da majẹmu, ati pé ó ti tọwọ́ bọ ìwé, sibẹsibẹ, ó tún ṣe gbogbo nǹkan tí ó ṣe.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo fi ara mi búra, n óo gbẹ̀san ìbúra mi tí kò náání lára rẹ̀, ati majẹmu mi tí ó dà. N óo da àwọ̀n mi bò ó mọ́lẹ̀, pańpẹ́ mi yóo mú un, n óo sì mú un lọ sí Babiloni. Níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù sí mi. Idà ni wọn óo fi pa àwọn tí wọ́n bá sá lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, a óo sì fọ́n àwọn tí wọ́n bá kù ká sí gbogbo ayé, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀.”

Esek 17:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mi wá pé: “Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ-aládé ibẹ̀ lọ sí Babeli lọ́dọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ó bá ọ̀kan nínú ọmọ ọba dá májẹ̀mú, ó mú un ìbúra, ó tún kó àwọn alágbára ilẹ̀ náà lọ. Kí ìjọba ilẹ̀ náà le rẹ ilẹ̀, kí ó má lè gbé ara rẹ̀ sókè, kí ó lè dúró nípa pípa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran àwọn ikọ̀ rẹ̀ lọ sí Ejibiti, kí wọn bá à lè fún un ni ẹṣin àti àwọn ọmọ-ogun púpọ̀. Yóò ha ṣe àṣeyọrí? Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀? Yóò ha dalẹ̀ tán kí ó sì bọ́ níbẹ̀ bí? “ ‘Bí mo ti wà láààyè ni OLúWA Olódùmarè wí, òun yóò kú ní Babeli, ní ilẹ̀ ọba tó fi sórí oyè, ìbúra ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà. Farao pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun àti àjọ ńlá rẹ̀ kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún un lójú ogun. Nígbà tí wọ́n bá pa bùdó ogun tì í, tí wọ́n sì mọ odi láti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, Nítorí pé ó kẹ́gàn ìbúra nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kì yóò bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí ó ṣe yìí. “ ‘Nítorí náà OLúWA Olódùmarè wí pé: Bí mo ti wà láààyè, Èmi yóò mú ẹ̀san ẹ̀jẹ́ mi tó kẹ́gàn àti májẹ̀mú mi tó dà wa sórí rẹ̀. Èmi yóò ta àwọ̀n mi sórí rẹ̀, yóò sì bọ sínú okùn mi, Èmi yóò mú ọ lọ Babeli láti ṣe ìdájọ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó hù sí mi. Gbogbo ìgbèkùn àti ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri. Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, “Èmi OLúWA ni ó ti sọ̀rọ̀.”