Esek 1:4-9
Esek 1:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo si wò, si kiye si i, ãja jade wá lati ariwa, awọsanma nla, ati iná ti o yi ara rẹ̀ ka, didán si wà yika, ani lati ãrin rẹ̀ wá, bi àwọ amberi, lati ãrin iná na wá. Pẹlupẹlu lati ãrin rẹ̀ wá, aworan ẹda alãye mẹrin, eyi si ni irí wọn, nwọn ni aworan enia. Olukuluku si ni oju mẹrin, olukuluku si ni iyẹ mẹrin. Ẹsẹ wọn si tọ́, atẹlẹsẹ wọn si dabi atẹlẹsẹ ọmọ malũ: nwọn si tàn bi awọ̀ idẹ didan. Nwọn si ni ọwọ́ enia labẹ iyẹ́ wọn, li ẹgbẹ wọn mẹrẹrin, awọn mẹrẹrin si ni oju wọn ati iyẹ́ wọn. Iyẹ́ wọn si kàn ara wọn; nwọn kò yipada nigbati nwọn lọ, olukuluku wọn lọ li ọkankan ganran.
Esek 1:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Ninu ìran náà, mo rí i tí ìjì kan ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá, pẹlu ìkùukùu ńlá tí ìmọ́lẹ̀ ńlá ati iná tí ń kọ mànàmànà yí ìjì náà ká, ààrin iná náà sì dàbí idẹ dídán tí ń kọ mànà. Láàrin iná yìí, mo rí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan, wọ́n dàbí eniyan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ojú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin. Ẹsẹ̀ wọn tọ́, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì dàbí pátákò mààlúù, ó ń kọ mànà bíi idẹ. Wọ́n ní ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn mẹrẹẹrin, wọ́n ní ojú mẹ́rin ati ìyẹ́ mẹ́rin. Báyìí ni ojú àwọn mẹrẹẹrin ati ìyẹ́ wọn rí: Ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn; bí wọ́n bá ń rìn, olukuluku wọn á máa lọ siwaju tààrà, láìyà sí ibikíbi, bí wọn tí ń lọ.
Esek 1:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùùkuu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná ti n bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárín iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná, àti láàrín iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin. Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán. Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́, ìyẹ́ wọn kan ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni.