Eks 5:8-9
Eks 5:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati iye briki ti nwọn ti ima ṣe ni ìgba atẹhinwá, on ni ki ẹnyin bù fun wọn; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ nkan kù kuro nibẹ̀: nitoriti nwọn nṣe imẹlẹ; nitorina ni nwọn ṣe nke wipe, Jẹ ki a lọ rubọ si Ọlorun wa. Ẹ jẹ ki iṣẹ ki o wuwo fun awọn ọkunrin na, ki nwọn ki o le ma ṣe lãlã ninu rẹ̀; ẹ má si ṣe jẹ ki nwọn ki o fiyesi ọ̀rọ eke.
Eks 5:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Iye bíríkì tí wọn ń ṣe tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín; nítorí pé nígbà tí iṣẹ́ kò ká wọn lára ni wọ́n ṣe ń rí ààyè pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ rúbọ sí Ọlọrun wa.’ Ẹ fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn. Nígbà tí iṣẹ́ bá wọ̀ wọ́n lọ́rùn gan-an, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ń parọ́ fún wọn, wọn kò ní fetí sí i.”
Eks 5:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú. Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run wa.’ Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn.”