Eks 4:1-5
Eks 4:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
MOSE si dahùn o si wipe, Ṣugbọn kiyesi i, nwọn ki yio gbà mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn ki yio fetisi ohùn mi: nitoriti nwọn o wipe, OLUWA kò farahàn ọ. OLUWA si wi fun u pe, Kini wà li ọwọ́ rẹ nì? On si wipe, Ọpá ni. O si wi fun u pe, Sọ ọ si ilẹ. On si sọ ọ si ilẹ, o si di ejò; Mose si sá kuro niwaju rẹ̀. OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ ki o si mú u ni ìru: (On si nà ọwọ́ rẹ̀, o si mú u, o si di ọpá si i li ọwọ́:) Ki nwọn ki o le gbàgbọ́ pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o farahàn ọ.
Eks 4:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Mose dáhùn pé, “Wọn kò ní gbà mí gbọ́, wọn kò tilẹ̀ ní fetí sí ọ̀rọ̀ mi, wọn yóo wí pé, OLUWA kò farahàn mí.” OLUWA bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló wà ní ọwọ́ rẹ yìí?” Ó dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.” OLUWA ní, “Sọ ọ́ sílẹ̀.” Mose bá sọ ọ́ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò, Mose bá sá sẹ́yìn. Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ, kí o mú un ní ìrù.” Mose nawọ́ mú un, ejò náà sì pada di ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀. OLUWA wí pé, “Èyí yóo mú kí wọ́n gbàgbọ́ pé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu ni ó farahàn ọ́.”
Eks 4:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mose dáhùn ó sì wí pé; “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ńkọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, tí wọn sì wí pé, ‘OLúWA kò farahàn ọ́’?” Ní ìgbà náà ni OLúWA sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ n nì?” Ó sì dáhùn pé, “ọ̀pá ni.” OLúWA sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.” Mose sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un. Nígbà náà ni Ọlọ́run wá sọ fún un pé, “na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù.” Mose sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀. OLúWA sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, OLúWA Ọlọ́run àwọn baba wọn: Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu; tí farahàn ọ́.”