Eks 36:1-7
Eks 36:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
BESALELI ati Oholiabu yio si ṣiṣẹ, ati olukuluku ọlọgbọ́n inu, ninu ẹniti OLUWA fi ọgbọn ati oyé si, lati mọ̀ bi a ti ṣiṣẹ onirũru iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA ti palaṣẹ. Mose si pè Besaleli ati Oholiabu, ati gbogbo ọkunrin ọlọgbọ́n inu, ninu ọkàn ẹniti OLUWA fi ọgbọ́n si, ani gbogbo ẹniti inu wọn ru soke lati wá si ibi iṣẹ na lati ṣe e: Nwọn si gbà gbogbo ọrẹ na lọwọ Mose, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, lati fi ṣe e. Sibẹ̀ nwọn si nmú ọrẹ ọfẹ fun u wá li orowurọ̀. Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọgbọ́n, ti o ṣe gbogbo isẹ ibi mimọ́ na, lọ olukuluku kuro ni ibi iṣẹ rẹ̀ ti nwọn ṣe; Nwọn si sọ fun Mose pe, Awọn enia múwa pupọ̀ju fun iṣẹ ìsin na, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe. Mose si paṣẹ, nwọn si ṣe ki nwọn ki o kede yi gbogbo ibudó na ká, wipe, Máṣe jẹ ki ọkunrin tabi obinrin ki o tun ṣe iṣẹkiṣẹ fun ọrẹ ibi mimọ́ na mọ́. Bẹ̃li a da awọn enia lẹkun ati ma múwa. Nitoriti ohun-èlo ti nwọn ni o to fun gbogbo iṣẹ na, lati fi ṣe e, o si pọ̀ju.
Eks 36:1-7 Yoruba Bible (YCE)
“Kí Besaleli, ati Oholiabu ati olukuluku àwọn tí OLUWA fún ní ìmọ̀ ati òye, láti ṣe èyíkéyìí ninu iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ kíkọ́ ilé mímọ́ náà, ṣe é bí OLUWA ti pa á láṣẹ gan-an.” Mose bá pe Besaleli ati Oholiabu, ati olukuluku àwọn tí OLUWA ti fún ní ìmọ̀ ati òye ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ náà láti wá bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ náà gba gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá láti fi ṣe iṣẹ́ àgọ́ mímọ́ náà lọ́wọ́ Mose. Àwọn eniyan ṣá tún ń mú ọrẹ àtinúwá yìí tọ Mose lọ ní àràárọ̀. Wọ́n mú ọrẹ wá tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ náà tọ Mose lọ; wọ́n sọ fún un pé, “Ohun tí àwọn eniyan náà mú wá ti pọ̀ ju ohun tí a nílò láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wa.” Mose bá pàṣẹ, wọ́n sì kéde yí gbogbo àgọ́ ká, pé kí ẹnikẹ́ni, kì báà ṣe ọkunrin, tabi obinrin, má wulẹ̀ ṣòpò láti mú ọrẹ wá fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà mọ́. Wọ́n sì dá àwọn eniyan náà lẹ́kun pé kí wọ́n má mú ọrẹ wá mọ́; nítorí pé ohun tí wọ́n ti mú wá ti tó, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù fún ohun tí wọ́n nílò láti fi ṣe iṣẹ́ náà.
Eks 36:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Besaleli, Oholiabu àti olúkúlùkù ọlọ́gbọ́n ẹni tí OLúWA tí fún ní ọgbọ́n àti òye láti mọ bí a ti í ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ ni kí wọn ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pa á láṣẹ.” Mose sì pe Besaleli àti Oholiabu àti gbogbo ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹni tí OLúWA ti fún ni agbára àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ láti wá sé iṣẹ́ náà. Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Israẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mose fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà. Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́-ọnà tí wọn ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀. Mose sì wí pé, “Àwọn ènìyàn mú púpọ̀ wá fún ṣíṣe iṣẹ́ náà ju bi OLúWA ti pa á láṣẹ láti ṣe lọ.” Mose sì pàṣẹ, wọ́n sì rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo ibùdó: “Kí ọkùnrin tàbí obìnrin má ṣe ṣe ohun kankan bí ọrẹ fún ibi mímọ́ náà mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni a dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti mú un wá sí i, nítorí ohun tí wọ́n ti ní ti ju ohun tí wọn fẹ́ fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà lọ.