Eks 34:1-28

Eks 34:1-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju: emi o si kọ ọ̀rọ walã ti iṣaju, ti iwọ ti fọ́, sara walã wọnyi. Si mura li owurọ̀, ki iwọ ki o si gún òke Sinai wá li owurọ̀, ki o si wá duro niwaju mi nibẹ̀ lori òke na. Ẹnikẹni ki yio si bá ọ gòke wá, ki a má si ṣe ri ẹnikẹni pẹlu li òke na gbogbo; bẹ̃ni ki a máṣe jẹ ki agbo-agutan tabi ọwọ́-ẹran ki o jẹ niwaju òke na. On si gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju; Mose si dide ni kutukutu owurọ̀, o si gún òke Sinai, bi OLUWA ti paṣẹ fun u, o si mú walã okuta mejeji li ọwọ́ rẹ̀. OLUWA si sọkalẹ ninu awọsanma, o si bá a duro nibẹ̀, o si pè orukọ OLUWA. OLUWA si rekọja niwaju rẹ̀, o si nkepè, OLUWA, OLUWA, Olọrun alãnu ati olore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹniti o pọ̀ li ore ati otitọ; Ẹniti o npa ãnu mọ́ fun ẹgbẹgbẹrun, ti o ndari aiṣedede, ati irekọja, ati ẹ̀ṣẹ jì, ati nitõtọ ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijiyà; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn omọ, ati lara awọn ọmọ ọmọ, lati irandiran ẹkẹta ati ẹkẹrin. Mose si yara, o si foribalẹ, o si sìn. On si wipe, Njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi Oluwa, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki Oluwa ki o ma bá wa lọ; nitori enia ọlọrùn lile ni; ki o si dari aiṣẹdede wa ati ẹ̀ṣẹ wa jì, ki o si fi wa ṣe iní rẹ. On si wipe, Kiyesi i, emi dá majẹmu kan: emi o ṣe ohun iyanu, niwaju gbogbo awọn enia rẹ irú eyiti a kò ti iṣe lori ilẹ gbogbo rí, ati ninu gbogbo orilẹ-ède: ati gbogbo enia ninu awọn ti iwọ wà, nwọn o ri iṣẹ OLUWA, nitori ohun ẹ̀ru li emi o fi ọ ṣe. Iwọ kiyesi eyiti emi palaṣẹ fun ọ li oni yi: kiyesi i, emi lé awọn Amori jade niwaju rẹ, ati awọn ara Kenaani, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi. Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nibikibi ti iwọ nlọ, ki o má ba di idẹwò fun ọ lãrin rẹ: Bikoṣepe ki ẹnyin ki o wó pẹpẹ wọn, ki ẹnyin ki o fọ́ ọwọ̀n wọn, ki ẹnyin si wó ere oriṣa wọn lulẹ. Nitoriti ẹnyin kò gbọdọ bọ oriṣa: nitori OLUWA, orukọ ẹniti ijẹ Ojowu, Ọlọrun ojowú li on: Ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nigbati nwọn ba nṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ti nwọn si nrubọ si oriṣa wọn, ti nwọn si pè ọ ti iwọ si lọ jẹ ninu ẹbọ wọn; Ki iwọ ki o má si ṣe fẹ́ ninu awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmokọnrin rẹ, ki awọn ọmọbinrin wọn ki o má ba ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ki nwọn ki o má ba mu ki awọn ọmọkunrin rẹ ki o ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn. Iwọ kò gbọdọ dà ere oriṣakoriṣa kan fun ara rẹ. Ajọ aiwukàra ni ki iwọ ki o ma pamọ́. Ijọ́ meje ni iwọ o jẹ àkara alaiwu, bi mo ti paṣẹ fun ọ, ni ìgba oṣù Abibu: nitoripe li oṣù Abibu ni iwọ jade kuro ni Egipti. Gbogbo akọ́bi ni ti emi; ati akọ ninu gbogbo ohunọ̀sin rẹ; akọ́bi ti malu, ati ti agutan. Ṣugbọn akọ́bi kẹtẹkẹtẹ ni ki iwọ ki o fi ọdọ-agutan rapada: bi iwọ kò ba si rà a pada, njẹ ki iwọ ki o ṣẹ́ ẹ li ọrùn. Gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọkunrin rẹ ni ki iwọ ki o rapada. Kò si sí ẹnikan ti yio farahàn niwaju mi lọwọ ofo. Ijọ́ mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ni ijọ́ keje ni ki iwọ ki o simi: ni ìgba ifunrugbìn, ati ni ìgba ikore ni ki iwọ ki o simi. Iwọ o si ma kiyesi ajọ ọ̀sẹ, akọ́so eso alikama, ati ajọ ikore li opin ọdún. Li ẹrinmẹta li ọdún kan ni gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ yio farahàn niwaju Oluwa, ỌLỌRUN, Ọlọrun Israeli. Nitoriti emi o lé awọn orilẹ-ède nì jade niwaju rẹ, emi o si fẹ̀ ipinlẹ rẹ: bẹ̃li ẹnikẹni ki yio fẹ́ ilẹ̀-iní rẹ, nigbati iwọ o gòke lọ lati pejọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ẹrinmẹta li ọdún kan. Iwọ kò gbọdọ ta ẹ̀jẹ ẹbọ mi silẹ nibiti iwukàra wà, bẹ̃li ẹbọ ajọ irekọja kò gbọdọ kù titi di owurọ̀. Akọ́so eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o mú wa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀. OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ kọwe ọ̀rọ wọnyi: nitori nipa ìmọ ọ̀rọ wọnyi li emi bá iwọ ati Israeli dá majẹmu. On si wà nibẹ̀, lọdọ OLUWA li ogoji ọsán ati ogoji oru: on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi. On si kọwe ọ̀rọ majẹmu na, ofin mẹwa nì, sara walã wọnni.

Eks 34:1-28 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Gbẹ́ wàláà òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, n óo sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kọ sára wàláà ti àkọ́kọ́ tí ó fọ́ sára wọn. Múra ní àárọ̀ ọ̀la, kí o gun òkè Sinai wá, kí o wá farahàn mí lórí òkè náà. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá ọ wá, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ sí níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, àwọn mààlúù, tabi àwọn aguntan kò gbọdọ̀ jẹ káàkiri níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà.” Mose bá gbẹ́ wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gun òkè Sinai lọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un; ó kó àwọn wàláà òkúta mejeeji náà lọ́wọ́. OLUWA tún sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu ó dúró níbẹ̀ pẹlu rẹ̀, ó sì pe orúkọ mímọ́ ara rẹ̀. OLUWA kọjá níwájú rẹ̀, ó sì kéde orúkọ ara rẹ̀ báyìí pé, “OLUWA Ọlọrun aláàánú ati olóore, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ ní àánú ati òtítọ́. Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.” Mose yára tẹ orí ba, ó dojú bolẹ̀, ó sì sin OLUWA. Ó ní, “Bí inú rẹ bá dùn sí mi nítòótọ́, OLUWA, jọ̀wọ́, máa wà láàrin wa, nígbà tí a bá ń lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóríkunkun ni àwọn eniyan náà; dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé wa jì wá, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí eniyan rẹ.” OLUWA wí fún Mose pé, “Mo dá majẹmu kan, n óo ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú àwọn eniyan náà, irú èyí tí ẹnikẹ́ni kò rí rí ní gbogbo ayé tabi láàrin orílẹ̀-èdè kankan. Gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń gbé ààrin wọn yóo sì rí iṣẹ́ OLUWA, nítorí ohun tí n óo ṣe fún wọn yóo bani lẹ́rù jọjọ. “Máa pa àwọn òfin tí mo fún ọ lónìí yìí mọ́. N óo lé àwọn ará Hamori ati àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, jáde kúrò níwájú rẹ. Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ rí i pé ẹ kò bá àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá majẹmu kankan, kí wọn má baà dàbí tàkúté tí a dẹ sí ààrin yín. Ṣugbọn, ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ gbogbo àwọn ère wọn, kí ẹ sì gé gbogbo igbó oriṣa wọn lulẹ̀. “Ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, nítorí èmi OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ owú, Ọlọrun tíí máa jowú ni mí. Ẹ kò gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni dá majẹmu ninu gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà, kí ẹ má baà bá wọn dá majẹmu tán, kí ó wá di pé, nígbà tí wọn bá ń rúbọ sí oriṣa wọn, tí wọn sì ń ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn, wọn óo máa pè yín, pé kí ẹ máa lọ bá wọn jẹ ninu ẹbọ wọn. Kó má baà wá di pé ẹ̀ ń fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín, kí àwọn ọmọbinrin yín má baà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa, kí wọ́n sì mú kí àwọn ọmọkunrin yín náà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn. “Ẹ kò gbọdọ̀ yá ère fún ara yín. “Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ àìwúkàrà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ fún ọjọ́ meje ní àkókò àjọ náà, ninu oṣù Abibu, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún yín, nítorí pé ninu oṣù Abibu ni ẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti. “Tèmi ni gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ àkọ́bí, gbogbo àkọ́bí ẹran: kì báà jẹ́ ti mààlúù, tabi ti aguntan. Ṣugbọn ọ̀dọ́ aguntan ni kí ẹ máa fi ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí ó bá jẹ́ akọ pada, tí ẹ kò bá fẹ́ rà á pada, ẹ gbọdọ̀ lọ́ ọ lọ́rùn pa. Gbogbo àkọ́bí yín lọkunrin, ni ẹ gbọdọ̀ rà pada. “Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá siwaju mi ní ọwọ́ òfo láti sìn mí. “Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣe iṣẹ́ yín, ní ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ sinmi; kì báà ṣe àkókò oko ríro, tabi àkókò ìkórè, dandan ni kí ẹ sinmi. “Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ̀dún ọ̀sẹ̀ ìkórè àkọ́so alikama ọkà yín, ati àjọ̀dún ìkójọ nígbà tí ẹ bá ń kórè nǹkan oko sinu abà ní òpin ọdún. “Ẹẹmẹta lọdọọdun, ni gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun Israẹli, kí wọ́n wá sìn mí. Nítorí pé n óo lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún yín, n óo sì fẹ ààlà yín sẹ́yìn. Kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo fẹ́ gba ilẹ̀ yín nígbà tí ẹ bá lọ sin OLUWA Ọlọrun yín, lẹẹmẹtẹẹta lọdọọdun. “Ẹ kò gbọdọ̀ fi ẹran rúbọ sí mi pẹlu ìwúkàrà, bẹ́ẹ̀ ni ohunkohun tí ẹ bá sì fi rú ẹbọ àjọ̀dún ìrékọjá kò gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji. “Ẹ gbọdọ̀ mú àkọ́so oko yín wá sí ilé OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi ọmú ìyá rẹ̀.” OLUWA wí fún Mose pé, “Kọ ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀, nítorí pé òun ni majẹmu mi dúró lé lórí pẹlu ìwọ ati Israẹli.” Mose sì wà pẹlu OLUWA fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ó sì kọ ọ̀rọ̀ majẹmu náà, tíí ṣe òfin mẹ́wàá, sára àwọn wàláà òkúta náà.

Eks 34:1-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé, “E gé òkúta wàláà méjì jáde bí i ti àkọ́kọ́, èmi yóò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé tó wà lára tí àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fọ́ sára wọn. Múra ní òwúrọ̀, kí o sì wá sórí òkè Sinai. Kí o fi ara rẹ hàn mí lórí òkè náà. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá pẹ̀lú rẹ tàbí kí a rí wọn lórí òkè náà; bẹ́ẹ̀ ni agbo àgùntàn tàbí ọwọ́ ẹran kó má ṣe jẹ níwájú òkè náà.” Bẹ́ẹ̀ Mose sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sinai lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pa á láṣẹ fún un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀. Nígbà náà ni OLúWA sọ̀kalẹ̀ nínú àwọsánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ OLúWA. Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “OLúWA, OLúWA, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́, Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.” Mose foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn. Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojúrere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.” Nígbà náà ni OLúWA wí pé: “Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín. Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ èmi yóò ṣe ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀-èdè ní gbogbo ayé rí. Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrín wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí èmi OLúWA yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó Ṣe ohun tí èmi pàṣẹ fún ọ lónìí. Èmi lé àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde níwájú rẹ. Máa ṣọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ̀ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdẹwò láàrín rẹ. Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Aṣerah wọn. (Ère òrìṣà wọn). Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn, nítorí OLúWA, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Òjòwú, Ọlọ́run owú ni. “Máa ṣọ́ra kí ẹ má ṣe bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, tí wọ́n sì rú ẹbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn. Nígbà tí ìwọ bá yàn nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí yóò ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. “Ìwọ kò gbọdọ̀ dá ère òrìṣàkórìṣà fún ara rẹ. “Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú oṣù Abibu, nítorí ní oṣù náà ni ẹ jáde láti Ejibiti wá. “Gbogbo àkọ́bí inú kọ̀ọ̀kan tèmi ní i ṣe, pẹ̀lú àkọ́bí gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ, bóyá ti màlúù tàbí ti àgùntàn. Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́-àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá síwájú mi ní ọwọ́ òfo. “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje ìwọ yóò sinmi; kódà ní àkókò ìfúnrúgbìn àti ní àkókò ìkórè ìwọ gbọdọ̀ sinmi. “Ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àkọ́so èso alikama àti àjọ ìkórè ní òpin ọdún. Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún, gbogbo àwọn ọkùnrin ni kí ó farahàn níwájú OLúWA Olódùmarè, Ọlọ́run Israẹli. Èmi yóò lé orílẹ̀-èdè jáde níwájú rẹ, èmi yóò sì mú kí ìpín rẹ fẹ̀, ẹnikẹ́ni kì yóò gba ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá gòkè lọ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún kọ̀ọ̀kan láti farahàn níwájú OLúWA Ọlọ́run rẹ. “Má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sí mi pẹ̀lú ohunkóhun tí ó bá ní ìwúkàrà, kí o má sì ṣe jẹ́ kí ẹbọ ìrékọjá kù títí di òwúrọ̀. “Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé OLúWA Ọlọ́run rẹ. “Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀.” OLúWA sì wí fún Mose pé, “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi bá ìwọ àti Israẹli dá májẹ̀mú.” Mose wà níbẹ̀ pẹ̀lú OLúWA fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru (40) láìjẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.