Eks 33:9-11
Eks 33:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, bi Mose ti dé ibi agọ́ na, ọwọ̀n awọsanma sọkalẹ, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: OLUWA si bá Mose sọ̀rọ. Gbogbo enia si ri ọwọ̀n awọsanma na o duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: gbogbo enia si dide duro, nwọn si wolẹ sìn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀. OLUWA si bá Mose sọ̀rọ li ojukoju, bi enia ti ibá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ. O si tun pada lọ si ibudó: ṣugbọn Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, ọdọmọkunrin kan, kò lọ kuro ninu agọ́ na.
Eks 33:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Bí Mose bá ti wọ inú àgọ́ àjọ náà lọ, ìkùukùu náà á sọ̀kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpó, a sì dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ náà. OLUWA yóo sì bá Mose sọ̀rọ̀. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan bá sì rí ìkùukùu tí ó dàbí òpó yìí, lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, gbogbo àwọn eniyan á dìde, olukuluku wọn á sì sin OLUWA ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ ní ojúkoojú, bí eniyan ṣe ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tí Mose bá pada sí ibùdó, Joṣua, iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, tí òun jẹ́ ọdọmọkunrin, kìí kúrò ninu àgọ́ àjọ.
Eks 33:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí Mose ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí OLúWA ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mose. Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. OLúWA máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ lójúkojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni Mose yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Joṣua ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Nuni kò fi àgọ́ sílẹ̀.