Eks 33:18-19
Eks 33:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ogo rẹ̀ hàn mi. On si wi fun u pe, Emi o mu gbogbo ore mi kọja niwaju rẹ, emi o si pè orukọ OLUWA niwaju rẹ; emi o si ṣe ore-ọfẹ fun ẹniti emi nfẹ ṣe ore-ọfẹ fun, emi o si ṣe ãnu fun ẹniti emi o ṣe ãnu fun.
Pín
Kà Eks 33Eks 33:18-19 Yoruba Bible (YCE)
Mose dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, fi ògo rẹ hàn mí.” OLUWA sì dá Mose lóhùn pé, “N óo mú kí ẹwà mi kọjá níwájú rẹ; n óo sì pe orúkọ mímọ́ mi lójú rẹ, èmi ni OLUWA, èmi a máa yọ́nú sí àwọn tí ó bá wù mí, èmi a sì máa ṣàánú fún àwọn tí mo bá fẹ́.”
Pín
Kà Eks 33Eks 33:18-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mose sì wí pé “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.” OLúWA sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ OLúWA níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún.
Pín
Kà Eks 33