Eks 33:14-16
Eks 33:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
On si wipe, Oju mi yio ma bá ọ lọ, emi o si fun ọ ni isimi. On si wi fun u pe, Bi oju rẹ kò ba bá wa lọ, máṣe mú wa gòke lati ihin lọ. Nipa ewo li a o fi mọ̀ nihinyi pe, emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ani emi ati awọn enia rẹ? ki iha iṣe ni ti pe iwọ mbá wa lọ ni, bẹ̃ni a o si yà wa sọ̀tọ, emi ati awọn enia rẹ, kuro lara gbogbo enia ti o wà lori ilẹ?
Eks 33:14-16 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Ojú mi yóo máa bá ọ lọ, n óo sì fún ọ ní ìsinmi.” Mose wí fún OLUWA pé, “Bí o kò bá ní bá wa lọ, má wulẹ̀ kó wa kúrò níhìn-ín. Nítorí pé, báwo ni àwọn eniyan yóo ṣe mọ̀ pé, inú rẹ dùn sí èmi ati àwọn eniyan rẹ? Ṣebí bí o bá wà pẹlu wa bí a ti ń lọ ni a óo fi lè dá èmi ati àwọn eniyan rẹ mọ̀ yàtọ̀ sí gbogbo aráyé yòókù.”
Eks 33:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.” Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ. Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”