Eks 32:1-8

Eks 32:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI awọn enia ri pe, Mose pẹ lati sọkalẹ ti ori òke wá, awọn enia kó ara wọn jọ sọdọ Aaroni, nwọn si wi fun u pe, Dide, dá oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa lọ; bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. Aaroni si wi fun wọn pe, Ẹ kán oruka wurà ti o wà li eti awọn aya nyin, ati ti awọn ọmọkunrin nyin, ati ti awọn ọmọbinrin nyin, ki ẹ si mú wọn tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn enia si kán oruka wurà ti o wà li eti wọn, nwọn si mú wọn tọ̀ Aaroni wá. O si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si fi ohun-ọnà fifin ṣe e, nigbati o si dà a li aworan ẹgbọrọmalu tán: nwọn si wipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ Egipti wá. Nigbati Aaroni si ri i, o tẹ́ pẹpẹ kan niwaju rẹ̀; Aaroni si kede, o si wipe, Ọla li ajọ fun OLUWA. Nwọn si dide ni kùtukutu ijọ́ keji nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si mú ẹbọ alafia wá; awọn enia si joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. OLUWA si sọ fun Mose pe, Lọ, sọkalẹ lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, nwọn ti ṣẹ̀. Nwọn ti yipada kánkan kuro ni ipa-ọ̀na ti mo làsilẹ fun wọn: nwọn ti dá ere ẹgbọrọmalu fun ara wọn, nwọn si ti mbọ ọ, nwọn si ti rubọ si i, nwọn nwipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ̀ Egipti wá.

Eks 32:1-8 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i pé Mose ń pẹ́ jù lórí òkè, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n tọ Aaroni lọ; wọ́n sọ fún un pé, “Ṣe oriṣa kan fún wa, tí yóo máa ṣáájú wa lọ; nítorí pé, a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.” Aaroni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gba gbogbo yẹtí wúrà etí àwọn aya yín jọ, ati ti àwọn ọmọkunrin yín, ati ti àwọn ọmọbinrin yín, kí ẹ sì kó wọn wá.” Gbogbo àwọn eniyan náà bá bọ́ yẹtí wúrà etí wọn jọ, wọ́n kó wọn tọ Aaroni lọ. Aaroni gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó lo irinṣẹ́ àwọn alágbẹ̀dẹ, ó fi wúrà náà da ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan. Àwọn eniyan náà bá dáhùn pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ọlọrun yín tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.” Nígbà tí Aaroni rí i bẹ́ẹ̀, ó tẹ́ pẹpẹ kan siwaju ère náà, ó sì kéde pé, “Ọ̀la yóo jẹ́ ọjọ́ àjọ fún OLUWA.” Wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ alaafia wá, wọ́n bá jókòó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn lòpọ̀. OLUWA wí fún Mose pé, “Tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá ti ba ara wọn jẹ́. Wọ́n ti yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère mààlúù kan, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí bọ ọ́, wọ́n sì ti ń rúbọ sí i. Wọ́n ń wí pé, ‘ọlọ́run yín nìyí Israẹli, ẹni tí ó mú yín gòkè wá láti ilẹ̀ Ijipti.’ ”

Eks 32:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mose pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Aaroni ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mose tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.” Aaroni dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bọ́ òrùka wúrà tí ó wà ní etí àwọn ìyàwó yín, tí àwọn ọmọkùnrin yín, àti tí àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn bọ́ òrùka etí wọn, wọn sì kó wọn wá fún Aaroni. Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfín, ó sì dà á ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Israẹli, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Ejibiti.” Nígbà ti Aaroni rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, “Lọ́la ni àjọyọ̀ sí OLúWA.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré. OLúWA sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Ejibiti, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀. Wọ́n ti yí kánkán kúrò nípa ọ̀nà tí mo ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹgbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rú ẹbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Israẹli wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá.’ ”