Eks 32:1-35

Eks 32:1-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI awọn enia ri pe, Mose pẹ lati sọkalẹ ti ori òke wá, awọn enia kó ara wọn jọ sọdọ Aaroni, nwọn si wi fun u pe, Dide, dá oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa lọ; bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. Aaroni si wi fun wọn pe, Ẹ kán oruka wurà ti o wà li eti awọn aya nyin, ati ti awọn ọmọkunrin nyin, ati ti awọn ọmọbinrin nyin, ki ẹ si mú wọn tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn enia si kán oruka wurà ti o wà li eti wọn, nwọn si mú wọn tọ̀ Aaroni wá. O si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si fi ohun-ọnà fifin ṣe e, nigbati o si dà a li aworan ẹgbọrọmalu tán: nwọn si wipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ Egipti wá. Nigbati Aaroni si ri i, o tẹ́ pẹpẹ kan niwaju rẹ̀; Aaroni si kede, o si wipe, Ọla li ajọ fun OLUWA. Nwọn si dide ni kùtukutu ijọ́ keji nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si mú ẹbọ alafia wá; awọn enia si joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. OLUWA si sọ fun Mose pe, Lọ, sọkalẹ lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, nwọn ti ṣẹ̀. Nwọn ti yipada kánkan kuro ni ipa-ọ̀na ti mo làsilẹ fun wọn: nwọn ti dá ere ẹgbọrọmalu fun ara wọn, nwọn si ti mbọ ọ, nwọn si ti rubọ si i, nwọn nwipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ̀ Egipti wá. OLUWA si wi fun Mose pe, Emi ti ri awọn enia yi, si kiyesi i, ọlọrùn lile enia ni: Njẹ nisisiyi jọwọ mi jẹ, ki ibinu mi ki o gbona si wọn, ki emi ki o le pa wọn run: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla. Mose si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, OLUWA, ẽtiṣe ti ibinu rẹ fi gbona si awọn enia rẹ, ti iwọ fi ipá nla ati ọwọ́ agbara rẹ mú lati ilẹ Egipti jade wá? Nitori kini awọn ara Egipti yio ṣe sọ wipe, Nitori ibi li o ṣe mú wọn jade, lati pa wọn lori oke, ati lati run wọn kuro lori ilẹ? Yipada kuro ninu ibinu rẹ ti o muna, ki o si yi ọkàn pada niti ibi yi si awọn enia rẹ. Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Israeli awọn iranṣẹ rẹ, ẹniti iwọ fi ara rẹ bura fun, ti iwọ si wi fun wọn pe, Emi o mu irú-ọmọ nyin bisi i bi irawọ ọrun, ati gbogbo ilẹ na ti mo ti sọ nì, irú-ọmọ nyin li emi o fi fun, nwọn o si jogún rẹ̀ lailai. OLUWA si yi ọkàn pada niti ibi na ti o ti sọ pe on o ṣe si awọn enia rẹ̀. Mose si yipada, o si sọkalẹ lati ori òke na wá, walã ẹrí meji nì si wà li ọwọ́ rẹ̀; walã ti a kọwe si ni ìha mejeji; lara ekini ati ekeji li a kọwe si. Iṣẹ́ Ọlọrun si ni walã wọnni, ikọwe na ni ikọwe Ọlọrun, a fin i sara walã na. Nigbati Joṣua si gbọ́ ariwo awọn enia na, bi nwọn ti nhó, o wi fun Mose pe, Ariwo ogun mbẹ ni ibudó. Mose si wi pe, Ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nhó nitori iṣẹgun, bẹ̃ni ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nkigbe pe a ṣẹgun wọn: ohùn awọn ti nkọrin ni mo gbọ́ yi. O si ṣe, bi o ti sunmọ ibudó, o si ri ẹgbọrọmalu na, ati agbo ijó: ibinu Mose si ru gidigidi, o si sọ walã wọnni silẹ kuro li ọwọ́ rẹ̀, o si fọ́ wọn nisalẹ òke na. O si mú ẹgbọrọ-malu na ti nwọn ṣe, o si sun u ni iná, o si lọ̀ ọ di ẹ̀tu, o si kù u soju omi, o si mu awọn ọmọ Israeli mu u. Mose si wi fun Aaroni pe, Kili awọn enia wọnyi fi ṣe ọ, ti iwọ fi mú ẹ̀ṣẹ̀ nla wá sori wọn? Aaroni si wipe, Máṣe jẹ ki ibinu oluwa mi ki o gbona: iwọ mọ̀ awọn enia yi pe, nwọn buru. Awọn li o sa wi fun mi pe, Ṣe oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa: bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. Emi si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba ni wurà, ki nwọn ki o kán a kuro; bẹ̃ni nwọn fi fun mi: nigbana li emi fi i sinu iná, ẹgbọrọmalu yi si ti jade wá. Nigbati Mose ri i pe awọn enia na kò ṣe ikoso; nitoriti Aaroni sọ wọn di alailakoso lãrin awọn ti o dide si wọn. Nigbana ni Mose duro li ẹnubode ibudó, o si wipe, Ẹnikẹni ti o wà ni ìha ti OLUWA, ki o tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn ọmọ Lefi si kó ara wọn jọ sọdọ rẹ̀. O si wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli, wipe, Ki olukuluku ọkunrin ki o kọ idà rẹ̀ si ẹgbẹ́ rẹ̀, ki ẹ si ma wọle, ki ẹ si ma jade lati ẹnubode dé ẹnubode já gbogbo ibudó, olukuluku ki o si pa arakunrin rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa ẹgbẹ rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa aladugbo rẹ̀. Awọn ọmọ Lefi si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose: awọn ti o ṣubu ninu awọn enia li ọjọ́ na to ìwọn ẹgbẹdogun enia. Mose sa ti wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ li oni fun OLUWA, ani olukuluku ọkunrin lara ọmọ rẹ̀, ati lara arakunrin rẹ̀; ki o le fi ibukún si nyin lori li oni. O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Mose wi fun awọn enia pe, Ẹnyin dá ẹ̀ṣẹ nla: njẹ nisisiyi, emi o gòke tọ̀ OLUWA, bọya emi o ṣètutu fun ẹ̀ṣẹ nyin. Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wipe, Yẽ, awọn enia wọnyi ti dá ẹ̀ṣẹ nla, nwọn si dá oriṣa wurà fun ara wọn. Nisisiyi, bi iwọ o ba dari ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn; bi bẹ̃ si kọ, emi bẹ̀ ọ, pa mi rẹ́ kuro ninu iwé rẹ ti iwọ ti kọ. OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹnikẹni ti o ṣẹ̀ mi, on li emi o parẹ́ kuro ninu iwé mi. Njẹ nisisiyi lọ, ma mú awọn enia na lọ si ibiti mo ti sọ fun ọ: kiyesi i, angeli mi yio ṣaju rẹ: ṣugbọn li ọjọ́ ti emi o ṣe ìbẹwo, emi o bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò lara wọn. OLUWA si yọ awọn enia na lẹnu, nitoriti nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu, ti Aaroni ṣe.

Eks 32:1-35 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i pé Mose ń pẹ́ jù lórí òkè, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n tọ Aaroni lọ; wọ́n sọ fún un pé, “Ṣe oriṣa kan fún wa, tí yóo máa ṣáájú wa lọ; nítorí pé, a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.” Aaroni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gba gbogbo yẹtí wúrà etí àwọn aya yín jọ, ati ti àwọn ọmọkunrin yín, ati ti àwọn ọmọbinrin yín, kí ẹ sì kó wọn wá.” Gbogbo àwọn eniyan náà bá bọ́ yẹtí wúrà etí wọn jọ, wọ́n kó wọn tọ Aaroni lọ. Aaroni gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó lo irinṣẹ́ àwọn alágbẹ̀dẹ, ó fi wúrà náà da ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan. Àwọn eniyan náà bá dáhùn pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ọlọrun yín tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.” Nígbà tí Aaroni rí i bẹ́ẹ̀, ó tẹ́ pẹpẹ kan siwaju ère náà, ó sì kéde pé, “Ọ̀la yóo jẹ́ ọjọ́ àjọ fún OLUWA.” Wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ alaafia wá, wọ́n bá jókòó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn lòpọ̀. OLUWA wí fún Mose pé, “Tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá ti ba ara wọn jẹ́. Wọ́n ti yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère mààlúù kan, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí bọ ọ́, wọ́n sì ti ń rúbọ sí i. Wọ́n ń wí pé, ‘ọlọ́run yín nìyí Israẹli, ẹni tí ó mú yín gòkè wá láti ilẹ̀ Ijipti.’ ” OLUWA bá wí fún Mose pé, “Mo ti rí àwọn eniyan wọnyi, wò ó, alágídí ni wọ́n. Dá mi dá wọn, inú ń bí mi sí wọn gidigidi, píparẹ́ ni n óo sì pa wọ́n rẹ́, ṣugbọn n óo sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá.” Ṣugbọn Mose bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí inú fi bí ọ tóbẹ́ẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ, àwọn tí o fi agbára ati tipátipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti? Kí ló dé tí o óo fi jẹ́ kí àwọn ará Ijipti wí pé, o mọ̀ọ́nmọ̀ fẹ́ ṣe wọ́n níbi ni o fi kó wọn jáde láti pa wọ́n lórí òkè yìí, ati láti pa wọ́n rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé? Jọ̀wọ́, má bínú mọ, yí ọkàn rẹ pada, má sì ṣe ibi tí o ti pinnu láti ṣe sí àwọn eniyan rẹ. Wo ti Abrahamu, ati Isaaki, ati Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn tí o ti fi ara rẹ búra fún pé o ó sọ arọmọdọmọ wọn di pupọ gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run; o ní gbogbo ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí ni o óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn; ati pé àwọn ni wọn yóo sì jogún rẹ̀ títí lae.” Ọlọrun bá yí ọkàn rẹ̀ pada, kò sì ṣe ibi tí ó gbèrò láti ṣe sí àwọn eniyan náà mọ́. Mose bá yipada, ó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, tòun ti wàláà òkúta ẹ̀rí mejeeji lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn wàláà òkúta tí Ọlọrun ti kọ nǹkan sí lójú mejeeji. Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn wàláà òkúta náà, Ọlọrun tìkararẹ̀ ni ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára wọn. Bí Joṣua ti gbọ́ ariwo àwọn eniyan náà tí wọn ń ké, ó wí fún Mose pé, “Ariwo ogun wà ninu àgọ́.” Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “Èyí kì í ṣe ìhó ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe igbe ẹni tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, ìró orin ni èyí tí mò ń gbọ́ yìí.” Bí ó ti súnmọ́ tòsí àgọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó rí ère ọmọ mààlúù, ó sì rí àwọn eniyan tí wọn ń jó. Inú bí Mose gidigidi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ju àwọn wàláà òkúta náà mọ́lẹ̀, ó sì fọ́ wọn ní ẹsẹ̀ òkè náà. Ó mú ère ọmọ mààlúù náà, tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó sun ún níná, ó lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, ó kù ú sójú omi, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Israẹli mu. Mose bi Aaroni pé, “Kí ni àwọn eniyan wọnyi fi ṣe ọ́, tí o fi mú ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá yìí wá sórí wọn?” Aaroni bá dáhùn, ó ní, “Má bínú, oluwa mi, ṣebí ìwọ náà mọ àwọn eniyan wọnyi pé eeyankeeyan ni wọ́n, àwọn ni wọ́n wá bá mi tí wọ́n ní, ‘Ṣe oriṣa fún wa tí yóo máa ṣáájú wa lọ, nítorí pé a kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Mose, tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.’ Ni mo bá wí fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Wọ́n kó wọn fún mi, ni mo bá dà wọ́n sinu iná, òun ni mo sì fi yá ère mààlúù yìí.” Nígbà tí Mose rí i pé Aaroni ti dá rúdurùdu sílẹ̀, láàrin àwọn eniyan náà, ati pé apá kò ká wọn mọ́, ọ̀rọ̀ náà sì sọ wọ́n di ẹni ìtìjú níwájú àwọn ọ̀tá wọn, Mose bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ní, “Ẹ̀yin wo ni ẹ̀ ń ṣe ti OLUWA, ẹ máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ọmọ Lefi bá kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Mose wí fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ti wí, ó ní, ‘Gbogbo ẹ̀yin ọkunrin, ẹ sán idà yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín kí ẹ sì máa lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, jákèjádò ibùdó, kí olukuluku máa pa arakunrin rẹ̀ ati ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ati aládùúgbò rẹ̀.’ ” Àwọn ọmọ Lefi sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, àwọn tí wọ́n kú láàrin àwọn eniyan náà tó ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin. Mose bá wí fún wọn pé, “Lónìí ni ẹ yan ara yín fún iṣẹ́ OLUWA, olukuluku yín sì ti fi ẹ̀mí ọmọ rẹ̀, ati ti arakunrin rẹ̀ yan ara rẹ̀, kí ó lè tú ibukun rẹ̀ sí orí yín lónìí yìí.” Ní ọjọ́ keji, Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, n óo tún gòkè tọ OLUWA lọ, bóyá n óo lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Mose bá pada tọ OLUWA lọ, ó ní, “Yéè! Àwọn eniyan wọnyi ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá; wọ́n ti fi wúrà yá ère fún ara wọn; ṣugbọn OLUWA, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pa orúkọ mi rẹ́ patapata kúrò ninu ìwé tí o kọ orúkọ àwọn eniyan rẹ sí.” OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi ni n óo pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé mi. Pada lọ nisinsinyii, kí o sì kó àwọn eniyan náà lọ sí ibi tí mo sọ fún ọ. Ranti pé angẹli mi yóo máa ṣáájú yín lọ, ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo jẹ àwọn eniyan náà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Nítorí náà, nígbà tó yá, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn burúkú kan sáàrin àwọn eniyan náà, nítorí pé wọ́n mú kí Aaroni fi wúrà yá ère mààlúù fún wọn.

Eks 32:1-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mose pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Aaroni ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mose tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.” Aaroni dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bọ́ òrùka wúrà tí ó wà ní etí àwọn ìyàwó yín, tí àwọn ọmọkùnrin yín, àti tí àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn bọ́ òrùka etí wọn, wọn sì kó wọn wá fún Aaroni. Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfín, ó sì dà á ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Israẹli, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Ejibiti.” Nígbà ti Aaroni rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, “Lọ́la ni àjọyọ̀ sí OLúWA.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré. OLúWA sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Ejibiti, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀. Wọ́n ti yí kánkán kúrò nípa ọ̀nà tí mo ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹgbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rú ẹbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Israẹli wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá.’ ” OLúWA wí fún Mose pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn. Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbóná sí wọn, kí èmi sì lè pa wọ́n run. Nígbà náà ni èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.” Ṣùgbọ́n Mose kígbe fún ojúrere OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “OLúWA, èéṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Ejibiti wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára? Èéṣe tí àwọn ará Ejibiti yóò ṣe wí pé, ‘Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́n mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé’? Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ. Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnrarẹ̀: ‘tí o wí fún wọn pé, èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ” Nígbà náà ni OLúWA dáwọ́ ìbínú rẹ̀ dúró, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́. Mose sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú òkúta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin. Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín in sára àwọn òkúta wàláà náà. Nígbà tí Joṣua gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mose pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.” Mose dáhùn pé: “Kì í ṣe ariwo fún ìṣẹ́gun, kì í ṣe ariwo fún aṣẹ́gun; ohùn àwọn tí ń kọrin ni mo gbọ́.” Nígbà tí Mose dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì sọ wàláà ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ ní ìsàlẹ̀ òkè náà. Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli mu ún. Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?” Aaroni dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó. Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mose ẹni tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá àwa kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.’ Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!” Mose rí pé àwọn ènìyàn náà kò ṣe ṣàkóso àti pé Aaroni ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrín àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn. Bẹ́ẹ̀ ni Mose dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún OLúWA, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Lefi sì péjọ yí i ká. Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, “Èyí ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, wí pé: ‘Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládùúgbò rẹ.’ ” Àwọn ará Lefi ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kú tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ènìyàn. Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún OLúWA lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.” Ní ọjọ́ kejì Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá OLúWA; bóyá èmi lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ OLúWA lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.” OLúWA dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi. Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹli mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín. Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” OLúWA sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú ààrùn nítorí ohun tí wọ́n ṣe ní ti ẹgbọrọ màlúù tí Aaroni ṣe.