Eks 31:1-18

Eks 31:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose pe, Wò ó, emi ti pè Besaleli li orukọ, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah: Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà. Lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, Ati li okuta gbigbẹ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà. Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ: Agọ́ ajọ na, ati apoti ẹrí nì, ati itẹ́-ãnu ti o wà lori rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo Agọ́ na. Ati tabili na ati ohun-èlo rẹ̀, ati ọpá-fitila mimọ́ pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari; Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada nì ti on ti ẹsẹ̀ rẹ̀; Ati aṣọ ìsin, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa; Ati oróro itasori, ati turari olõrùn didùn fun ibi mimọ́ nì: gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ ni nwọn o ṣe. OLUWA si sọ fun Mose pe, Ki iwọ ki o sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ isimi mi li ẹnyin o pamọ́ nitõtọ: nitori àmi ni lãrin emi ati lãrin nyin lati irandiran nyin; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA ti o yà nyin simimọ́. Nitorina ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́ isimi mọ́; nitoripe mimọ́ ni fun nyin: ẹniti o ba bà a jẹ́ on li a o pa nitõtọ: nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ kan ninu rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ; ṣugbọn ni ọjọ́ keje ni ọjọ́ isimi, mimọ́ ni si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ li ọjọ́ isimi, on li a o si pa nitõtọ. Nitorina li awọn ọmọ Israeli yio ṣe ma pa ọjọ́ isimi mọ́, lati ma kiyesi ọjọ́ isimi lati irandiran wọn, fun majẹmu titilai. Àmi ni iṣe lãrin emi ati lãrin awọn ọmọ Israeli titilai: nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, ni ijọ́ keje o si simi, o si ṣe ìtura. O si fi walã ẹrí meji, walã okuta, ti a fi ika Ọlọrun kọ, fun Mose, nigbati o pari ọ̀rọ bibá a sọ tán lori oke Sinai.

Eks 31:1-18 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose pé, “Wò ó, mo ti pe Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. Mo sì ti fi ẹ̀mí Ọlọrun kún inú rẹ̀, mo ti fún un ní òye ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ iṣẹ́ ọnà, láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, láti dá oríṣìíríṣìí àrà sí ara òkúta ati láti tò ó, láti gbẹ́ igi ati láti fi oríṣìíríṣìí ohun èlò ṣe iṣẹ́ ọnà. Mo ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani pẹlu rẹ̀. Mo sì ti fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà ní ọgbọ́n, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí àgọ́ àjọ, ati àpótí ẹ̀rí ati ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò àgọ́, ati tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, pẹpẹ turari, pẹpẹ ẹbọ sísun ati gbogbo ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀ ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; ati àwọn ẹ̀wù tí a dárà sí, ẹ̀wù mímọ́ Aaroni alufaa ati ẹ̀wù àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ patapata ni wọn yóo ṣe bí mo ti pa á láṣẹ.” OLUWA rán Mose, ó ní, “Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, nítorí pé òun ni àmì tí ó wà láàrin èmi pẹlu yín ní ìrandíran yín; kí ẹ lè mọ̀ pé, èmi OLUWA yà yín sọ́tọ̀ fún ara mi. Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ di aláìmọ́, pípa ni kí wọ́n pa á; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀. Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, èyí tí ó jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ ìsinmi, pípa ni kí wọ́n pa á. Nítorí náà, àwọn eniyan Israẹli yóo máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, wọn yóo máa ranti rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì majẹmu ní ìrandíran wọn. Ọjọ́ náà jẹ́ àmì ayérayé tí ó wà láàrin èmi ati àwọn eniyan Israẹli, pé ọjọ́ mẹfa ni èmi Ọlọrun fi dá ọ̀run ati ayé, ati pé ní ọjọ́ keje, mo dáwọ́ iṣẹ́ ṣíṣe dúró, mo sì sinmi.’ ” Nígbà tí Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀ tán lórí òkè Sinai, ó fún un ní wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ọlọrun fúnra rẹ̀ ni ó fi ìka ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára àwọn wàláà náà.

Eks 31:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA wí fún Mose pé, “Wò ó, èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, Èmi sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́. “Bákan náà, èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ: “àgọ́ àjọ náà, àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà, tábìlì àti ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ tùràrí, pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, àti aṣọ híhun pẹ̀lú, papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà, òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. “Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.” OLúWA wí fún Mose pé, “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì láàrín èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni OLúWA, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́. “ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún OLúWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé. Yóò jẹ́ ààmì láàrín èmi àti àwọn ọmọ Israẹli títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni OLúWA dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ” Nígbà tí OLúWA parí ọ̀rọ̀ sísọ fún Mose lórí òkè Sinai, ó fún un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, òkúta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.