Eks 31:1-11
Eks 31:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Wò ó, emi ti pè Besaleli li orukọ, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah: Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà. Lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, Ati li okuta gbigbẹ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà. Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ: Agọ́ ajọ na, ati apoti ẹrí nì, ati itẹ́-ãnu ti o wà lori rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo Agọ́ na. Ati tabili na ati ohun-èlo rẹ̀, ati ọpá-fitila mimọ́ pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari; Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada nì ti on ti ẹsẹ̀ rẹ̀; Ati aṣọ ìsin, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa; Ati oróro itasori, ati turari olõrùn didùn fun ibi mimọ́ nì: gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ ni nwọn o ṣe.
Eks 31:1-11 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Mose pé, “Wò ó, mo ti pe Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. Mo sì ti fi ẹ̀mí Ọlọrun kún inú rẹ̀, mo ti fún un ní òye ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ iṣẹ́ ọnà, láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, láti dá oríṣìíríṣìí àrà sí ara òkúta ati láti tò ó, láti gbẹ́ igi ati láti fi oríṣìíríṣìí ohun èlò ṣe iṣẹ́ ọnà. Mo ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani pẹlu rẹ̀. Mo sì ti fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà ní ọgbọ́n, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí àgọ́ àjọ, ati àpótí ẹ̀rí ati ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò àgọ́, ati tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, pẹpẹ turari, pẹpẹ ẹbọ sísun ati gbogbo ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀ ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; ati àwọn ẹ̀wù tí a dárà sí, ẹ̀wù mímọ́ Aaroni alufaa ati ẹ̀wù àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ patapata ni wọn yóo ṣe bí mo ti pa á láṣẹ.”
Eks 31:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA wí fún Mose pé, “Wò ó, èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, Èmi sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́. “Bákan náà, èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ: “àgọ́ àjọ náà, àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà, tábìlì àti ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ tùràrí, pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, àti aṣọ híhun pẹ̀lú, papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà, òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́.