Eks 30:11-38
Eks 30:11-38 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Mose pé, “Nígbà tí o bá ka iye àwọn eniyan Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ mú ohun ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ wá fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn, nígbà tí o bá kà wọ́n. Ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí o bá kà yóo san ni: ìdajì ṣekeli, tí a fi ìwọ̀n ilé OLUWA wọ̀n, (tí ó jẹ́ ogún ìwọ̀n gera fún ìwọ̀n ṣekeli kan), ìdajì ṣekeli náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí a bá kà ní àkókò ìkànìyàn náà, tí ó bá tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó gbọdọ̀ san owó náà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Bí eniyan ti wù kí ó ní owó tó, kò gbọdọ̀ san ju ìdajì ṣekeli kan lọ; bí ó sì ti wù kí eniyan tòṣì tó, kò gbọdọ̀ san dín ní ìdajì ṣekeli kan, nígbà tí ẹ bá ń san ọrẹ OLUWA fún ìràpadà ẹ̀mí yín. Gba owó ètùtù lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli, kí o sì máa lò ó fún iṣẹ́ ilé ìsìn àgọ́ àjọ, kí ó lè máa mú àwọn ọmọ Israẹli wá sí ìrántí níwájú OLUWA, kí ó sì lè jẹ́ ètùtù fún yín.” OLUWA tún wí fún Mose pé, “Fi idẹ ṣe agbada omi kan, kí ìdí rẹ̀ náà jẹ́ idẹ, gbé e sí ààrin àgọ́ àjọ ati pẹpẹ, kí o sì bu omi sinu rẹ̀. Omi yìí ni Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo fi máa fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn. Nígbà tí wọ́n bá ń wọ àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, láti rú ẹbọ sísun sí OLUWA; omi yìí ni wọ́n gbọdọ̀ fi fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n má baà kú. Dandan ni kí wọ́n fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má baà kú. Èyí yóo di ìlànà fún wọn títí lae: fún òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ ní gbogbo ìran wọn.” Lẹ́yìn náà, OLUWA tún wí fún Mose pé, “Mú ojúlówó àwọn nǹkan olóòórùn dídùn wọnyi kí o kó wọn jọ: ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli òjíá olómi, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli sinamoni, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli igi olóòórùn dídùn kan tí ó dàbí èèsún, ati ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli kasia, ìwọ̀n ṣekeli ilé OLUWA ni kí wọ́n lò láti wọ̀n wọ́n. Lẹ́yìn náà, mú ìwọ̀n hini ojúlówó òróró olifi kan. Pa gbogbo nǹkan wọnyi pọ̀, kí o fi ṣe òróró mímọ́ fún ìyàsímímọ́. Ṣe é bí àwọn ìpara olóòórùn dídùn, yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ fún OLUWA. Ta òróró yìí sí ara àgọ́ àjọ, ati sí ara àpótí ẹ̀rí, ati sí ara tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò orí rẹ̀, ati sí ara ọ̀pá fìtílà ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara pẹpẹ turari, ati sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara agbada omi, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Fi yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́ patapata; ohunkohun tí ó bá kàn wọ́n yóo sì di mímọ́. Ta òróró yìí sí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lórí, kí o fi yà wọ́n sí mímọ́; kí wọ́n lè máa ṣe alufaa fún mi. Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Òróró yìí ni yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ ní ìrandíran yín, ẹ kò gbọdọ̀ dà á sí ara àwọn eniyan lásán, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe òróró mìíràn tí ó dàbí rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀, tabi ẹnikẹ́ni tí ó bá dà á sórí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe alufaa, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.’ ” OLUWA wí fún Mose pé, “Mú àwọn ohun ìkunra olóòórùn dídùn wọnyi: sitakite, ati onika, ati galibanumi ati ojúlówó turari olóòórùn dídùn, gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà. Lọ̀ wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn tí wọn ń ṣe turari, kí o fi iyọ̀ sí i; yóo sì jẹ́ mímọ́. Bù ninu rẹ̀, kí o gún un lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, bù díẹ̀ ninu lúbúlúbú yìí, kí o fi siwaju àpótí ẹ̀rí ninu àgọ́ àjọ, níbi tí n óo ti bá ọ pàdé, yóo jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe irú turari náà fún ara yín, ṣugbọn ẹ mú un gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe irú rẹ̀, láti máa lò ó gẹ́gẹ́ bíi turari, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.”
Eks 30:11-38 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Nigbati iwọ ba kà iye awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi ẹgbẹ wọn, nigbana li olukuluku ọkunrin yio mú irapada ọkàn rẹ̀ fun OLUWA wá, nigbati iwọ ba kà iye wọn; ki ajakalẹ-àrun ki o máṣe si ninu wọn, nigbati iwọ ba nkà iye wọn. Eyi ni nwọn o múwa, olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, àbọ ṣekeli, ani ṣekeli ibi mimọ́: (ogún gera ni ṣekeli kan:) àbọ ṣekeli li ọrẹ fun OLUWA. Olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, ni yio fi ọrẹ fun OLUWA. Olowo ki o san jù bẹ̃ lọ, bẹ̃li awọn talaka kò si gbọdọ di li àbọ ṣekeli, nigbati nwọn ba mú ọrẹ wá fun OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin. Iwọ o si gbà owo ètutu na lọwọ awọn ọmọ Israeli, iwọ o si fi i lelẹ fun ìsin agọ́ ajọ; ki o le ma ṣe iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun ọkàn nyin. OLUWA si sọ fun Mose pe, Iwọ o si ṣe agbada idẹ kan, ati ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fun wiwẹ̀: iwọ o si gbẹ́ e kà agbedemeji agọ́ ajọ, ati pẹpẹ nì, iwọ o si pọn omi sinu rẹ̀. Nitori Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn nibẹ̀: Nigbati nwọn ba nwọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, nwọn o fi omi wẹ̀ ki nwọn ki o má ba kú: tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ nì lati ṣe ìsin, lati ru ẹbọ sisun ti a fi iná ṣe si OLUWA: Nwọn o si wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn, ki nwọn ki o má ba kú: yio si di ìlana fun wọn lailai, fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lati irandiran wọn. OLUWA si sọ fun Mose pe, Iwọ mú ãyo olõrùn si ọdọ rẹ, pẹlu ojia sísan ẹdẹgbẹta ṣekeli, ati kinnamoni didùn idameji bẹ̃, ani ãdọtalerugba ṣekeli, ati kalamu didùn ãdọtalerugba ṣekeli, Ati kassia ẹdẹgbẹta ṣekeli, ṣekeli ibi mimọ́, ati hini oróro olifi kan: Iwọ o si ṣe e li oróro mimọ́ ikunra, ti a fi ọgbọ́n alapòlu pò: yio si jẹ́ oróro mimọ́ itasori. Iwọ o si ta ninu rẹ̀ sara agọ́ ajọ, ati apoti ẹrí nì, Ati tabili ati ohunèlo rẹ̀ gbogbo, ati ọpáfitila ati ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari, Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀. Iwọ o si yà wọn simimọ́, ki nwọn ki o le ṣe mimọ́ julọ: ohunkohun ti o ba fọwọkàn wọn yio di mimọ́. Iwọ o si ta òróró sí Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si yà wọn si mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe alufa fun mi. Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Eyi ni yio ma ṣe oróro mimọ́ itasori fun mi lati irandiran nyin. A ko gbọdọ dà a si ara enia, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe irú rẹ̀, ni ìwọn pipò rẹ̀: mimọ́ ni, yio si ma ṣe mimọ́ fun nyin. Ẹnikẹni ti o ba pò bi irú rẹ̀, tabi ẹnikẹni ti o ba fi sara alejò ninu rẹ̀, on li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. OLUWA si wi fun Mose pe, Mú olõrùn didùn sọdọ rẹ, stakte, ati onika, ati galbanumu; olõrùn didùn wọnyi, pẹlu turari daradara: òṣuwọn kan na li olukuluku; Iwọ o si ṣe e ni turari, apòlu nipa ọgbọ́n-ọnà alapòlu, ti a fi iyọ̀ si, ti o dara ti o si mọ́. Iwọ o si gún diẹ ninu rẹ̀ kunna, iwọ o si fi i siwaju ẹrí ninu rẹ̀ ninu agọ́ ajọ, nibiti emi o gbé ma bá ọ pade: yio ṣe mimọ́ julọ fun nyin. Ati ti turari ti iwọ o ṣe, ẹnyin kò gbọdọ ṣe e fun ara nyin ni ìwọn pipò rẹ̀: yio si ṣe mimọ́ fun ọ si OLUWA. Ẹnikẹni ti o ba ṣe irú rẹ̀, lati ma gbõrùn rẹ̀, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
Eks 30:11-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA wí fún Mose pé, “Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún OLúWA ní ìgbà tí o bá ka iye wọn. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn kì yóò súnmọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn. Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún OLúWA. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún OLúWA. Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì ṣékélì lọ, àwọn tálákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì ṣékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún OLúWA láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín. Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ yóò sì fi lélẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ. Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli níwájú OLúWA, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.” Nígbà náà ni OLúWA wí fún Mose pé, “Ìwọ yóò sì ṣe agbada idẹ kan, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀. Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìsìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún OLúWA, wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Aaroni àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandíran wọn.” OLúWA sọ fún Mose pé, Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kílógírámù mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́tà-lé-nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́tà-lé-nígba (250) ṣékélì, kasia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ṣékélì—gbogbo rẹ̀ ní ìlànà ṣékélì ibi mímọ́ àti hínì òróró olifi kan (lítà mẹ́rin). Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò gẹ́gẹ́ bí olùṣe òórùn dídùn tì í ṣe, Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí. Ìwọ yóò sì lò ó láti ya àgọ́ sí mímọ́ àti àpótí ẹ̀rí náà, tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti ohun èlò rẹ̀, àti pẹpẹ tùràrí, pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀. Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́. “Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà. Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀. Má ṣe dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yin sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára àlejò yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ” OLúWA sọ fún Mose pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, onika, àti galibanumu àti kìkì tùràrí dáradára, òṣùwọ̀n kan fún gbogbo rẹ, ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́. Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e síwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín. Ẹ má ṣe ṣe tùràrí kankan ní irú èyí fúnrayín; ẹ kà á ní mímọ́ sí OLúWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, òun ni a ó gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”