Eks 3:4-6
Eks 3:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati OLUWA ri pe, o yipada si apakan lati wò o, Ọlọrun kọ si i lati inu ãrin igbẹ́ na wá, o si wipe, Mose, Mose. On si dahun pe, Emi niyi. O si wipe, Máṣe sunmọ ihin: bọ́ salubata rẹ kuro li ẹsẹ̀ rẹ, nitori ibiti iwọ gbé duro si nì, ilẹ mimọ́ ni. O si wipe, Emi li Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu. Mose si pa oju rẹ̀ mọ́; nitoriti o bẹ̀ru lati bojuwò Ọlọrun.
Eks 3:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Ọlọrun rí i pé ó súnmọ́ ọn láti wo ohun ìyanu náà, Ọlọrun pè é láti inú igbó náà, ó ní, “Mose! Mose!” Mose dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọrun ní, “Má ṣe súnmọ́ tòsí ibí, bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé, ilẹ̀ tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Ọlọrun tún fi kún un pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu.” Mose bá bo ojú rẹ̀ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọrun.

Eks 3:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí OLúWA rí i pe Mose ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárín igbó náà, “Mose! Mose!” Mose sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nìyìí.” Olúwa sì wí fún Mose pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.” Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.” Nítorí ìdí èyí, Mose sì pa ojú rẹ̀ mọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti bojú wo Ọlọ́run.